Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí bọ́ sí ọjọ́ Thursday, March 28. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí:
◼ Tí ẹ bá ń ṣètò àkókò tẹ́ ẹ máa fi ìpàdé yìí sí, kí ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà kiri àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.
◼ Kí a fi àkókò pàtó tí a óò ṣe ayẹyẹ náà àti ibi tí a óò ti ṣe é tó gbogbo èèyàn létí, títí kan olùbánisọ̀rọ̀.
◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ, kí wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.
◼ Kí a gbé àwo, ago, tábìlì àti aṣọ tábìlì tó bójú mu wá sí gbọ̀ngàn ìpàdé náà, kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.
◼ Kí a tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò lò ṣe, kí ó sì wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.
◼ Kí a yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ojúṣe wọn, bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, àti ìjẹ́pàtàkì mímúra lọ́nà tó bójú mu.
◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tó jẹ́ aláìlera, tí kò bá lè wá.
◼ Tí a bá ṣètò pé kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí ẹnu ọ̀nà, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tí gbogbo èèyàn ń gbà àti ibi ìgbọ́kọ̀sí máa bà a kún jù fún èrò.