Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí
Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí bọ́ sí ọjọ́ Sunday, April 8. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn ọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí:
◼ Ní ṣíṣètò àkókò fún ìpàdé náà, ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri títí di ẹ̀yìn tí oòrùn bá wọ̀.
◼ Kí á fi àkókò tí a óò ṣe ayẹyẹ náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é tó gbogbo èèyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀ létí.
◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tí ó yẹ, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.
◼ Kí á gbé àwo, ago, tábìlì àti aṣọ tábìlì tí ó yẹ wá sí gbọ̀ngàn, kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.
◼ Kí á tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a ó ti pàdé ṣe, kó wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.
◼ Kí á yan àwọn olùtọ́jú èrò àti àwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ojúṣe wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é.
◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò lera, tí kò sì lè wá.
◼ Tí a bá ṣètò kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí ẹnu ọ̀nà, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tí gbogbo èèyàn ń gbà, àti ibi ìgbọ́kọ̀sí máa bàa kún jù.