ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/01 ojú ìwé 7
  • Máa Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí Jẹ́ Aláyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àwọn Onídùnnú-ayọ̀ “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Naa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń Jẹ́ Ká Fara Dà Á Ká Sì Máa Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 3/01 ojú ìwé 7

Máa Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run

1 Fún odindi ọjọ́ mẹ́ta tó ṣàrà ọ̀tọ̀, a pésẹ̀ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí.” A gbọ́kàn wa kúrò lórí ságbà súlà ìgbésí ayé ojoojúmọ́, a sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà. A pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀hún láti mú kí ìgbàgbọ́ táa ní nínú Ọlọ́run àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀ sí i, láti mú kí àjọṣe àwa àti òun lágbára sí i, àti láti mú kí ìtara táa ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i. Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú àwọn nǹkan táa kọ́?—Jòh. 13:17.

2 Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Àpínsọ àsọyé náà, “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ipò tẹ̀mí ìdílé wa. Àwọn ọmọ máa ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Nítorí èyí, a fún àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run níṣìírí láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé jẹ́ ìpìlẹ̀ fún gbígbé agbo ilé tó lágbára nípa tẹ̀mí ró. Ọ̀pọ̀ olórí ìdílé ló ti ń bá àwọn ọmọ wọn kéékèèké jíròrò nínú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe aláyọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wà láàárín àwọn àti Jèhófà. Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè máa fiyè sí ohun tó jẹ́ èrò Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tí ẹ ní fún un àti fún àwọn iṣẹ́ rẹ̀ máa hàn dáadáa nínú ọ̀rọ̀ yín. (Sm. 103:2) Ẹ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti gbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀, láti lé wọn bá, kí ẹ sì máa kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú sísin Jèhófà.

3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Tànmọ́lẹ̀ sí Ọ̀nà Wa: Inú wa dùn láti rí ìwé tuntun náà, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní. Ibo lo ti ka apá kìíní yìí dé? Ìwé Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ ìdájọ́ tí kò báradé fún àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì sọ pé àwọn ìbùkún aláyọ̀ ti Ìjọba náà yóò jẹ́ tàwọn èèyàn Ọlọ́run. (Aísá. 34:2; 35:10) Ó tún ń mú ká ní ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà àti nínú ọ̀nà tó ń gbà ṣe àwọn nǹkan.—Aísá. 12:2-5.

4 Nígbà tóo bá ń ka ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà Apá Kìíní, ní ìbẹ̀rẹ̀, o lè rí bí Aísáyà ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́ nígbà tí ìwà ibi yí i ká. Nígbà tí Ọlọ́run ké sí i pé kó wá jíṣẹ́ fún òun, Aísáyà fèsì pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Ṣíṣàṣàrò lórí irú ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni tó ní yóò fún ọ níṣìírí láti máa bá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere náà, kí o sì máa kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú jíjẹ́ “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mát. 24:14.

5 Fífi tí a bá ń fiyè sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà yóò gbé ìtóbilọ́lá rẹ̀ ga. Nítorí náà, máa mọyì àǹfààní jíjẹ́ olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́