Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí Jẹ́ Aláyọ̀
“A mọ̀ pé àpéjọpọ̀ yìí tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè láti múra wa sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò Ìjọba púpọ̀ sí i.” Ohun tí ọ̀kan lára àwọn tó sọ̀rọ̀ lápá ìbẹ̀rẹ̀ Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ nìyẹn. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A ti múra sílẹ̀ láti gba ìtọ́ni nípa ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀, kí a gba ìṣírí láti dúró ti ètò àjọ Jèhófà, kí a sún wa láti máa bá ìtara wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà nìṣó, kí a sì rán wa létí nípa ìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́nà.”
LÁTI apá ìparí oṣù May 2000 ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ti ń péjú pésẹ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibi àpéjọpọ̀ kárí ayé láti lọ gba ìmọ̀ Bíbélì tó ṣe kókó. Ẹ̀kọ́ wo ni wọ́n kọ́ ní àpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà?
Ọjọ́ Kìíní—Ṣíṣàì Gbàgbé Gbogbo Ìgbòkègbodò Iṣẹ́ Jèhófà
Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, alága ké sí àwùjọ láti gbádùn àwọn ìbùkún tí ń wá látinú ìjọsìn Jèhófà tí ó wà níṣọ̀kan nígbà àwọn àpéjọpọ̀ wa. Ó mú un dá gbogbo àwọn tó wá lójú pé ìgbàgbọ́ wọn yóò túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀, àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà yóò sì lágbára sí i.
“Ọlọ́run aláyọ̀” mọ ohun tó lè mú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láyọ̀. (1 Tímótì 1:11) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àsọyé náà “Ṣíṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run Ń Máyọ̀ Wá” tẹnu mọ́ ọn pé Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Jèhófà ló lànà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. (Jòhánù 13:17) Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mélòó kan táa ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́ fi hàn pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lábẹ́ onírúurú ipò ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e, “Máa Tàn Yinrin Nítorí Oore Jèhófà,” tẹnu mọ́ ọn pé, gẹ́gẹ́ bí “aláfarawé Ọlọ́run,” ó yẹ káwọn Kristẹni máa mú “onírúurú ohun rere” jáde nínú ìgbésí ayé wọn. (Éfésù 5:1, 9) Ọ̀kan lára ọ̀nà títayọ táa lè gbà ṣe èyí ni wíwàásù ìhìn rere náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Sáàmù 145:7.
Ìjíròrò náà “Máa Bá A Lọ Ní Fífẹsẹ̀múlẹ̀ Ṣinṣin Bí Ẹni Tí Ń Rí Ẹni Tí A Kò Lè Rí” ṣàlàyé bí ìgbàgbọ́ tó lágbára ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti “rí” Ọlọ́run àìrí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé bí àwọn ẹni tẹ̀mí ṣe ń mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, títí kan bí ó ṣe ń mọ ohun tí à ń rò pàápàá. (Òwe 5:21) Àwọn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò mẹ́nu kan àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n ti gbé láti lè mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i, kí wọ́n sì fi ire tẹ̀mí sípò iwájú nínú ìgbésí ayé wọn.
Lájorí àsọyé, “Ẹ Yin Jèhófà—Olùṣe Àwọn Ohun Àgbàyanu,” la fi kásẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ nílẹ̀. Ó ran àwùjọ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé báa bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa rí ìdí tó fi yẹ láti máa yìn ín gẹ́gẹ́ bí Olùṣe àwọn ohun àgbàyanu. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Bí a ṣe ń ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu ti ìṣẹ̀dá Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ohun àgbàyanu tó ń ṣe fún wa nísinsìnyí, ìmọrírì àtọkànwá ń sún wa láti máa yìn ín. Bí a ṣe ń ṣàṣàrò nípa àwọn nǹkan ìyanu tó ti ṣe nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ láwọn ìgbà tó ti kọjá, a ń fẹ́ láti yìn ín. Bí a sì ṣe ń ronú nípa àwọn ìlérí ohun àgbàyanu tí Jèhófà ṣì máa ṣe, àwa pẹ̀lú máa ń wá ọ̀nà láti fi ìmọrírì hàn.”
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àsọyé náà, “Má Ṣe Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára,” èyí tó rán gbogbo àwùjọ létí pé pákáǹleke inú ayé yìí mú un dá wa lójú pé òpin ti sún mọ́lé lóòótọ́. (2 Tímótì 3:1) Àmọ́ tí a ò bá juwọ́ sílẹ̀, a lè fi hàn pé àwa jẹ́ “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Hébérù 10:39.
Ìmọ̀ràn wo la fúnni látinú Bíbélì nípa ìgbésí ayé ìdílé? Àpínsọ àsọyé àkọ́kọ́ ní àpéjọpọ̀ náà—“Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú apá náà “Nínú Yíyan Ẹni Tí A Óò Fẹ́.” Yíyan ẹni tí a óò fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára ìpinnu tó wúwo jù lọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni máa ń fẹ́ dúró dìgbà tí wọ́n bá ti dàgbà dénú kí wọ́n tó ṣe ìgbéyàwó, wọ́n sì ń ṣe é “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Apá kejì àpínsọ àsọyé náà jíròrò fífẹ́ tí Jèhófà fẹ́ kí gbogbo ìdílé Kristẹni ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó wà ní ìrẹ́pọ̀ nípa tẹ̀mí, ó sì pèsè àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí wọ́n fi lè ṣe èyí ní àṣeyọrí. Apá tó gbẹ̀yìn rán àwọn òbí létí pé kíkọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ táwọn òbí náà ní fún Ọlọ́run.
Àwọn kókó tó jẹ yọ látinú àsọyé náà “Ṣọ́ra fún Àhesọ àti Òfófó” ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́ láti rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kàyéfì máa ń ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ fọgbọ́n hùwà, ká má ṣe bí òpè, nígbà táa bá gbọ́ àwọn ìròyìn kàyéfì. Ó sàn kí àwọn Kristẹni máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ òótọ́—ìyẹn ìhìn rere Ìjọba náà. Ọ̀pọ̀ ni àsọyé tó tẹ̀ lé e, “Kíkojú ‘Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara,’” tù nínú gan-an, ó sì fún wọn ní ìṣírí. Ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé bí àdánwò táa ń fojú winá rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀, síbẹ̀ Jèhófà lè fún wa lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni wa. A rí ọ̀pọ̀ ìṣírí lórí ọ̀rọ̀ yìí látinú ìrírí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—2 Kọ́ríńtì 12:7-10; Fílípì 4:11, 13.
Àsọyé náà, “Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn,” ni ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn lọ́jọ́ àkọ́kọ́. A ṣàgbéyẹ̀wò ìhà mẹ́ta tí ètò àjọ Ọlọ́run ti tẹ̀ síwájú ní pàtàkì: (1) òye tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i nípa ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí látọ̀dọ̀ Jèhófà, (2) iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi síkàáwọ́ wa, àti (3) àwọn àtúnṣe yíyẹ táa ti ṣe sí àwọn ìlànà ètò àjọ yìí. Nígbà náà ni olùbánisọ̀rọ̀ náà wá sọ pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ pé: “Àwọn ìfojúsọ́nà tó . . . ń bẹ níwájú ń mú ọkàn-àyà wa yọ̀.” Ó wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ ó yẹ kí a ṣiyèméjì rárá pé ó ṣe pàtàkì pé kí ìgbọ́kànlé táa ní lákọ̀ọ́kọ́ máa bá a lọ títí dé òpin?” (Hébérù 3:14) Ìdáhùn náà ṣe kedere. Lẹ́yìn èyí la wá kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ tuntun kan táa pe àkọlé rẹ̀ ní Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò ran àwọn tí kò kàwé púpọ̀ tàbí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wéé kà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.
Ọjọ́ Kejì—Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Sísọ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà ń bá a nìṣó pẹ̀lú àpínsọ àsọyé náà “Àwọn Òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Apá àkọ́kọ́ pe àfiyèsí sí bí iṣẹ́ ìwàásù wa kárí ayé ṣe ń yọrí sí rere. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò fẹ́ gbọ́ ìhìn Ìjọba náà mú ká túbọ̀ nílò ìfaradà nínú iṣẹ́ yìí. Àwọn akéde ọlọ́jọ́ pípẹ́ mélòó kan ṣàlàyé pé ìdí tí ẹ̀mí ìdágunlá àti àtakò àwọn èèyàn kò fi kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni pé àwọn máa ń ṣara gírí, àwọn sì máa ń mọ́kàn le láti kojú wọn. Apá kejì rán àwọn alápèéjọpọ̀ létí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń làkàkà láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbi gbogbo, lọ́nà tó jẹ́ bí àṣà àti lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà. Apá tó kẹ́yìn sì ṣàlàyé onírúurú ọ̀nà tí gbogbo Kristẹni lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Olùbánisọ̀rọ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé láti lè ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ fi Ìjọba Ọlọ́run sípò kìíní, kódà bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ fa ìnira àti ìfi-nǹkan-du-ara-ẹni.—Mátíù 6:19-21.
Níwọ̀n bí a ti ń gbé nínú ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó kún fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, àsọyé náà “Ní Ẹ̀mí Ìfọkànsin Ọlọ́run Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ohun-Moní-Tómi” bọ́ sákòókò gẹ́ẹ́. Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbé díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ karí 1 Tímótì 6:6-10, 18, 19, ó sì fi hàn bí ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti yẹra fún ìfẹ́ owó, èyí tó lè mú wọn ṣáko lọ, kí ó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora. Ó tẹnu mọ́ ọn pé bó ti wù kí ipò ìṣúnná owó wa rí, ayọ̀ wa sinmi lórí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà àti ipò tẹ̀mí wa. Àwọn kókó táa ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ náà “Ṣíṣàìdójú Ti Ọlọ́run” wú àwọn èèyàn lórí lọ́pọ̀lọpọ̀. A tẹnu mọ́ kókó náà pé Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ olóòótọ́ láé. Àpẹẹrẹ aláìlẹ́gbẹ́ ti Jésù Kristi—ẹni tó “jẹ́ ọ̀kan náà lánàá àti lónìí, àti títí láé”—yóò ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti máa fi ìfaradà sá eré ìje ìyè nìṣó.—Hébérù 13:8.
Ọ̀rọ̀ ìbatisí ló kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀—ó sábà máa ń jẹ́ apá pàtàkì níbi àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wa mà dùn o, láti rí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́, tí wọ́n tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù nípa ṣíṣe batisí nínú omi! (Mátíù 3:13-17) Gbogbo àwọn tó gbé ìgbésẹ̀ yìí ti ṣe gudugudu méje gẹ́gẹ́ bí olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, lẹ́yìn ìbatisí wọn, wọn di òjíṣẹ́ ìhìn rere, wọn yóò sì máa rí ayọ̀ púpọ̀ nínú mímọ̀ pé àwọn ń kópa nínú yíya orúkọ Jèhófà sí mímọ́.—Òwe 27:11.
A fún wa ní ìmọ̀ràn tó sọjú abẹ níkòó nínú ọ̀rọ̀ náà “A Nílò Ìdàgbàdénú ‘Láti Fi Ìyàtọ̀ Sáàárín Ohun Tí Ó Tọ́ àti Ohun Tí Kò Tọ́.’” Ìlànà tí ayé yìí fi ń pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ kò kúnjú òṣùwọ̀n rárá. Ìdí nìyẹn táa fi gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ìlànà Jèhófà. (Róòmù 12:2) A rọ kálukú láti sapá kárakára láti jèrè òye pípé nípa àwọn ọ̀nà Ọlọ́run, kí a sì dàgbà dénú. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a óò kọ́ agbára ìwòye wa “láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:11-14.
Èyí tó wá kàn lẹ́yìn ìyẹn ni àpínsọ àsọyé náà “Ẹ Ṣiṣẹ́ Kára Láti Jẹ́ Ènìyàn Tẹ̀mí.” Àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ ìjẹ́pàtàkì dídi ẹni tẹ̀mí àti bíbá a nìṣó láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Èyí gba aápọn—kíkàwé, kíkẹ́kọ̀ọ́, àti ṣíṣe àṣàrò. (Mátíù 7:13, 14; Lúùkù 13:24) Àwọn ẹni tẹ̀mí tún máa ń gba “gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” (Éfésù 6:18) A mọ̀ pé àdúrà wa máa ń fi bí ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn wa, àti ipò tẹ̀mí wa ti jinlẹ̀ tó hàn, ó tún máa ń fi àwọn ohun táa kà sí “ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” hàn. (Fílípì 1:10) A tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní àjọṣe dídánmọ́rán àti onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jèhófà, irú èyí tí ọmọ onígbọràn ní pẹ̀lú bàbá rẹ̀ onínúure. A ò ní fi gbogbo rẹ̀ mọ sórí pé a ní ẹ̀sìn kan—bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni—ṣùgbọ́n a tún gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ‘bíi pé à ń rí Ọlọ́run.’—Hébérù 11:6, 27.
A tún sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí nínú àsọyé náà “Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere.” A gbé apá mẹ́ta irú ìtẹ̀síwájú bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò: (1) fífikún ìmọ̀, òye, àti ọgbọ́n, (2) síso èso ẹ̀mí Ọlọ́run, àti (3) ṣíṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ìdílé.
Ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn lọ́jọ́ yẹn, “Rírìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ sí I,” fi kún ayọ̀ àwọn alápèéjọpọ̀ nígbà tí wọ́n gba ìwé tuntun náà, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní. Èyí ni apá kìíní ìwé alápá méjì tí yóò ṣàlàyé ìwé Aísáyà inú Bíbélì, láti orí kan sí òmíràn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Aísáyà kàn wá lóde òní o.” Ó tẹ̀ síwájú pé: “Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ ní ìgbà ayé Aísáyà lọ́hùn-ún. . . . Ṣùgbọ́n, púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ló ń ṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ lóde òní, tí àwọn mìíràn yóò sì ṣẹ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.”
Ọjọ́ Kẹta—Ẹ Jẹ́ Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Jèhófà Wí
Ìjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ la fi bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà la wá gbọ́ àpínsọ àsọyé náà, “Àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà Tó Nítumọ̀ fún Àwọn Tí Ń Ṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Àsọyé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ń bẹ nínú àpínsọ àsọyé yìí fi hàn pé, Jèhófà yóò mú ìpọ́njú dé bá àwọn tí kò gba ìkìlọ̀ rẹ̀ nísinsìnyí, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe ní àwọn ọjọ́ Júdà alágídí. Nítorí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ṣe ni wọn yóò máa táràrà kiri bí afọ́jú, wọn ò ní rí ẹni tó máa gbà wọ́n. Àmọ́, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi tọkàntọkàn wá Jèhófà, a ó sì pa wọ́n mọ́ lọ́jọ́ ìbínú Ọlọ́run. Síwájú sí i, wọ́n ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún báyìí pàápàá. Wọ́n ní àǹfààní àtàtà ti sísọ “èdè mímọ́ gaara,” èyíinì ni òtítọ́ Bíbélì. (Sefanáyà 3:9) Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Sísọ èdè mímọ́ gaara kì í ṣe ọ̀ràn wíwulẹ̀ gba òtítọ́ gbọ́, ká sì máa fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn, ṣùgbọ́n ó tún kan mímú ìwà wa bá àwọn òfin Ọlọ́run àti ìlànà rẹ̀ mu.”
Ara àwọn alápèéjọpọ̀ ti wà lọ́nà fún àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Àwọn Ohun Àríkọ́gbọ́n fún Wa Lónìí.” Àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí tó jẹ́ ti ìgbàanì jẹ́ kí a rí bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí nítorí pé wọ́n gbàgbé Jèhófà, àwọn obìnrin kèfèrí sì sún wọn sínú àgbèrè àti ìjọsìn èké. Jámínì, tí í ṣe ẹnì kan pàtàkì nínú ìtàn náà, kò kọ́kọ́ mọ ohun tí òun ì bá ṣe, bóyá kóun bá àwọn ọmọbìnrin Móábù lọ ni o, tàbí kóun rọ̀ mọ́ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ èké àti ìrònú ẹ̀tàn ti Símírì aláìní ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn sójú táyé, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsìn Fíníhásì fara hàn kedere. A fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé ewu ń bẹ nínú bíbá àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe wọlé-wọ̀de.
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ló ṣe atọ́kùn àsọyé tó tẹ̀ lé e, “Ẹ Má Ṣe Di Olùgbọ́ Tí Ń Gbàgbé.” A ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ 1 Kọ́ríńtì 10:1-10, tó fi hàn pé Jèhófà máa ń dán ìgbọràn wa wò láti mọ̀ bóyá a tóótun láti gba ogún kan nínú ayé tuntun. Ní ti àwọn kan, àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara ń mú wọn pa àwọn góńgó tẹ̀mí tì, kódà nísinsìnyí, tó jẹ́ pé díẹ̀ ló kù ká wọnú ètò tuntun. A fún gbogbo wa níṣìírí láti má ṣe pàdánù àǹfààní táa ní láti ‘wọnú ìsinmi Jèhófà.’—Hébérù 4:1.
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn ni “Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run.” “Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” Jèhófà fi ọgbọ́n àti ọlá àṣẹ rẹ̀ hàn lórí gbogbo ẹ̀dá táa lè fojú rí ní àyíká wa. (Jóòbù 37:14) Ọ̀pọ̀ ìbéèrè gbankọgbì látọ̀dọ̀ Jèhófà ti tó láti jẹ́ kí Jóòbù mọ bí Ẹlẹ́dàá ti lágbára tó. Jèhófà yóò tún ṣe “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” lọ́jọ́ iwájú nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Olùbánisọ̀rọ̀ náà kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìdí tó pọ̀ rẹpẹtẹ ń bẹ, tó fi yẹ ká pàfiyèsí sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà, ìyẹn àwọn ohun tó ṣe sẹ́yìn, àwọn ohun tó ń ṣe níṣojú wa lónìí nínú ìṣẹ̀dá, àti èyí tó ṣèlérí láti ṣe láìpẹ́ láìjìnnà.”
Lẹ́yìn àkópọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀sẹ̀ yẹn ni a wá sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn ní àpéjọpọ̀ yìí. Àkòrí rẹ̀ ni “Máa Fojú Ribiribi Wo Àǹfààní Jíjẹ́ Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí.” Àwíyé tí ń tani jí yìí tẹnu mọ́ ọn pé nǹkan iyì ni láti jẹ́ olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí. (Jákọ́bù 1:22) A rán àwùjọ létí pé àǹfààní wa gẹ́gẹ́ bí olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, bí a bá sì ṣe pẹ́ lẹ́nu lílo àǹfààní yìí tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò túbọ̀ máa fojú ribiribi wò ó. A rọ gbogbo àwọn tó wá pé kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìṣírí tí wọ́n ti gbọ́ ní àpéjọpọ̀ àgbègbè yìí sílò bí wọ́n ti ń sapá láti jẹ́ olùṣe ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ni ayọ̀ wa fi lè kún.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
A kéde ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ tuntun tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! ní ọ̀sán Friday. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti mú kí ẹ̀kọ́ Bíbélì rọrùn ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé, ìwé pẹlẹbẹ yìí yóò sì mú kí èyí ṣeé ṣe. Yóò jẹ́ ìbùkún ńláǹlà fáwọn tí kò kàwé púpọ̀ tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wéé kà dáadáa.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé
Inú àwọn tó wá sí àpéjọpọ̀ dùn gan-an láti gba Apá Kìíní ìwé alápá méjì náà, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé. Ìwé yìí ṣe àlàyé púpọ̀ lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti wúlò fún wa tó lónìí.