ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 1/15 ojú ìwé 24-30
  • Àwọn Àpéjọpọ̀ Tí Ń Rùmọ̀lárasókè Gbé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ga

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àpéjọpọ̀ Tí Ń Rùmọ̀lárasókè Gbé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ga
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀sán Ọjọ́ Àkọ́kọ́
  • Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kejì
  • Ọ̀sán Ọjọ́ Kejì
  • Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kẹta
  • Ọ̀sán Ọjọ́ Kẹta
  • Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kẹrin
  • Ọ̀sán tí Ó Kẹ́yìn
  • A Rọ Àwọn Olùkọ́ni ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Ṣe Iṣẹ́ Tá A Gbé Lé Wọn Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” Péjọ Tayọ̀tayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run Ẹ Má Ṣe Fi fún Ènìyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí Jẹ́ Aláyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 1/15 ojú ìwé 24-30

Àwọn Àpéjọpọ̀ Tí Ń Rùmọ̀lárasókè Gbé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ga

LÓNÌÍ, ayé ń ní ìrírí ìpọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ àwọn ìsọfúnni. Lórí tẹlifíṣọ̀n àti redio, nínú àwọn ìwé tàbí nípasẹ̀ kọ̀m̀pútà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìpèsè aláìlópin ni ó wà lórí kókó-ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tí ó ṣeéronúkàn níti gidi. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn ń ṣàìsàn wọ́n sì ń kú. Ìwà-ọ̀daràn, ebi, àti òṣì wà níbi gbogbo káàkiri ayé, ìṣiṣẹ́gbòdì èrò-ìmọ̀lára sì ń bá ọ̀pọ̀ ènìyàn jà ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Gbogbo ìmọ̀ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó ti kùnà láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀ràn. Èéṣe? Nítorí pé aráyé ti kẹ̀yìn sí ọgbọ́n Ọlọrun.

Nígbà náà, ó ti báamu tó pé “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí a yàn fún àpéjọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a ṣe láìpẹ́ yìí! Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà rán àwọn wọnnì tí wọ́n wá létí pé ẹ̀kọ́ tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli nìkan, ni ó ní ìníyelórí tòótọ́, tí ń gba ẹ̀mí là.

Àpéjọpọ̀ àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ní Thursday, June 3, ní Uniondale, New York, U.S.A. Láti ìgbà náà lọ, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni a gbékalẹ̀ ní àwọn ìlú-ńlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní orílẹ̀-èdè kan tẹ̀lé òmíràn, tí ó sì parí sí àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì Africa àti South America.

Ọ̀sán Ọjọ́ Àkọ́kọ́

Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí ó tẹnumọ́ apá-ìhà kan nínú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Fún àpẹẹrẹ, ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ọjọ́ àkọ́kọ́ ní a gbékarí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Mímọ Ẹ̀kọ́ tí ó Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọrun Wá.” (Johannu 7:17) Èrò yìí ní a gbékalẹ̀ dáradára bí ọjọ́ náà ti ń tẹ̀síwájú.

Lẹ́yìn orin àti àdúrà, alága àpéjọpọ̀ náà ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-àsọyé tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ń Mú Wa Wà Papọ̀.” Ó fihàn pé àwọn ènìyàn Jehofa ni a sopọ̀ ṣọ̀kan nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀nà Rẹ̀ àti rírìn ní àwọn ipa-ọ̀nà Rẹ̀. (Mika 4:​1-⁠5) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá fún ìṣọ̀kan wọn lókun. Àwọn olùpéjọpọ̀ ni a fún ní ìṣírí láti yọ̀ nínú ìfararora oníṣọ̀kan wọn.​—⁠Orin Dafidi 133:​1-⁠3.

Nígbà tí ó ṣe díẹ̀ síi ní ọ̀sán, a jíròrò àwọn ìpàdé ìjọ tí a ń ṣe déédéé nínú àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé kan tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Ìpàdé tí Ń Kọ́ Wa Nípa Àwọn Ọ̀nà Jehofa.” Olùbánisọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ rán àwọn olùpéjọpọ̀ létí pé nígbà tí a bá pàdé pọ̀, a ń bọlá fún Jehofa a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gba ìbùkún Rẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e tẹnumọ́ àìní náà láti kópa nínú àwọn ìpàdé. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ń yin Jehofa ní gbangba, a ń fi ìgbàgbọ́ wa hàn, a sì ń fún ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn lókun. Olùbánisọ̀rọ̀ kẹta nínú àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé náà fi àìní náà láti fí ohun tí a bá kọ́ ní àwọn ìpàdé sílò. A gbọ́dọ̀ jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kí ó má sì ṣe olùgbọ́ nìkan.”​—⁠Jakọbu 1:⁠22.

Tẹ̀lé e ni ìjíròrò dídára kan lórí kíkọrin ìyìn sí Jehofa. Orin àtọkànwá jẹ́ apá tí ó jámọ́ pàtàkì nínú ìjọsìn wa. Lájorí ọ̀rọ̀-àwíyé náà “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ti Ṣẹ́gun” ni ó tẹ̀lé ọ̀rọ̀-àsọyé yìí. Ẹ wo ẹṣin-ọ̀rọ̀ títayọlọ́lá tí èyí jẹ́! “Jehofa ni Orísun ẹ̀kọ́ dídára jùlọ tí ẹnìkan lè rígbà,” ni olùbánisọ̀rọ̀ náà wí. Lẹ́yìn ìjíròrò kúkúrú nípa iṣẹ́-ìyanu ọpọlọ ènìyàn, nígbà náà ni ó wí pé: “A níláti lo agbára ìrònú wa ní pàtàkì láti gba ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Òun nìkan ni ó máa ń yọrísí ojúlówó ọgbọ́n.” Ẹ wo bí ìyẹn ti jẹ́ òtítọ́ tó!

Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kejì

“Ẹ Máa Báa Lọ Ní Ṣíṣe Ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà Wa Ní Ọ̀ṣọ́” ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọjọ́ kejì apéjọpọ̀ náà. (Titu 2:10) Ìlànà yìí wá sí ojútáyé nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Àwọn Ẹ̀kọ́ Ẹ̀mí Èṣù.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ẹ̀mí-èṣù ní àwọn ẹ̀kọ́ tiwọn. (1 Timoteu 4:1) Gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ náà ti ṣàlàyé, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun “ọgbọ́n” Satani nípa títúdìí àwọn ẹ̀kọ́ èké àti àwọn ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí Eṣu. Nítorí èyí, nǹkan bíi 4,500,000 àwọn Kristian ọlọ́kàn-títọ́ ni wọn kìí ṣe ẹrú mọ́ nínú òkùnkùn Satani.​—⁠Johannu 8:32.

Síbẹ̀, a níláti máa báa lọ láti gbéjàko Satani. Èyí ni ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Iwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?” tẹnumọ́. Ẹ̀mí ayé yìí ń ṣekúpani. Ó ń fún ọ̀nà-ìwàhíhù arẹninípòsílẹ̀ níṣìírí, ojú-ìwòye ọlọ̀tẹ̀ nípa ọlá-àṣẹ, àti ìfẹ́-ọkàn fún kíkó àwọn ohun ti ara jọ. Kristian kan níláti máa yẹ araarẹ̀ wo nígbà gbogbo. Òun ha ṣì ní àwọn ìlànà gíga nígbà tí ó bá kan àwọn ohun tí òun ń wò, ń tẹ́tísí, tàbí ń kà? Lọ́nà tí ń fúnni níṣìírí, olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “A gbóríyìn fún yín, ẹ̀yin arákùnrin, arábìnrin, àti ẹ̀yin ọ̀dọ́, fún ìsapá onífọkànsí tí ẹ ń sà lórí ọ̀ràn yìí ní báyìí.”​—⁠1 Johannu 2:​15-⁠17.

Kókó-abájọ kan wà tí ó mú kí ó ṣòro láti yẹra fún ẹ̀mí ayé. Kí nìyẹn? Gbogbo wa jẹ́ aláìpé. Nítòótọ́, Jesu kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, ṣùgbọ́n a ṣì níláti bá ìtẹ̀sí náà láti dẹ́ṣẹ̀ jìjàkadì. Èyí ni a gbéyẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Gbígbógunti Ìwàmú Ẹ̀ṣẹ̀ Lórí Ẹran-Ara Ẹlẹ́ṣẹ̀.” Yàtọ̀ sí àwọn ohun mìíràn, olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé a lè ṣẹ́gun nínú ìjàkadì wa pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ bí a bá gbé ìwà-ànímọ́ titun náà wọ̀ tí a sì yẹra fún ohunkóhun tí ń tẹ́ àwọn ìtẹ̀sí wa fún ẹ̀ṣẹ̀ lọ́rùn.

“Sọ Ẹ̀kọ́ tí ó Yèkooro Di Ọ̀nà Ìgbésí-Ayé Rẹ” ni àkòrí ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e. Àwọn kan ní àníyàn tí ó pọ̀jù nípa ìlera ti ara. Ṣùgbọ́n, níti tòótọ́, ìlera ti ẹ̀mí ṣe pàtàkì jù fíìfíì. Olùbánisọ̀rọ̀ náà tẹ̀numọ́ àìní náà láti fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú àwọn ẹrù-iṣẹ́ wa lórí ọ̀ràn yìí, ó sì ní ọ̀rọ̀ afúnni-níṣìírí fún àwọn Kristian obìnrin ní pàtàkì. Ó wí pé: “Àwa ní ìmọrírì gidigidi fún àwọn arábìnrin àgbàlagbà àti àwọn arábìnrin ọ̀dọ́ tí wọ́n wà déédéé dáradára nínú ìtara wọn fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà àti nínú ọ̀nà tí wọn gbà ń bójútó àwọn ẹrù-iṣẹ́ ti ara-ẹni.” Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo wa sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ẹ̀kọ́ afúnninílera tí ó yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé.

Ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ṣí Ète Ìgbésí-Ayé Payá” ni ó mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti òwúrọ̀ wá sí ìparí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Bópẹ́-bóyá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ènìyàn ní yóò máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni ète ìgbésí-ayé?’” Pẹ̀lú àwọn gbólóhùn àlàyé tí ó lágbára, ó fi ẹ̀rí hàn pé Bibeli nìkanṣoṣo ni ó fúnni ní ìdáhùn tòótọ́ sí ìbéèrè yẹn. Lẹ́yìn náà, olùbánisọ̀rọ̀ náà fihàn pé àwọn ìlérí àgbàyanu Ọlọrun fún wa ní ète kan nínú ìgbésí-ayé lọ́nà gbígbéṣẹ́. Ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí ń bẹ láwùjọ máa ronú pé, ‘Èyí ni ohun náà gan-⁠an tí àwọn tí ń bẹ ní àgbègbè ìpínlẹ̀ mi níláti gbọ́.’ Èrò kan-náà ní Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ní. Ìwé-pẹlẹbẹ titun kan, tí a pé àkọlé rẹ̀ ní What Is the Purpose of Life? ni a mújadé ní ìparí ọ̀rọ̀-àsọyé yìí. Ẹ wo bí inú olúkúlùkù ti dùn tó! Àkókó ìṣíwọ́ ráńpẹ́ ní ọ̀sán pèsè àǹfààní fún yíyẹ ìtẹ̀jáde titun náà wò.

Ọ̀sán Ọjọ́ Kejì

Ọ̀rọ̀-àsọyé àkọ́kọ́ ní ọ̀sán ní ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí ń tuninínú náà “Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa.” Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni ó ń fa àníyàn; síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé a níláti kó gbogbo àníyàn wa lé e. (1 Peteru 5:​6, 7) Lóòótọ́, àwọn ìṣòro kan ń báa lọ, nípa èyí sì ni olùbánisọ̀rọ̀ náà rọni pé: ‘Ní sùúrù. Dúró de Jehofa. Ní ìgbàgbọ́ fífẹsẹ̀múlẹ̀ gbọnyin pé títẹ̀lé Bibeli ni ó máa ń fìgbà gbogbo dára jùlọ. Bí a bá pa ọkàn-àyà wa pọ̀ sọ́dọ̀ Jehofa, àwa yóò wá gbádùn “àlàáfíà Ọlọrun” tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ.’​—⁠Filippi 4:​6, 7.

Àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé mẹ́rin tí ó tẹ̀lé e fihàn pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kan ìgbésí-ayé ìdílé. Èyí àkọ́kọ́, “Mímú Kí Ìgbéyàwó Jẹ́ Ìsopọ̀ tí ó Wà Títí Lọ Gbére,” rán àwọn olùpéjọpọ̀ létí pé ní ojú Jehofa ìgbéyàwó kìí ṣe ètò tí a lè fọwọ́ rọ́ dànù, bí ọ̀pọ̀ nínú ayé ti ń wò ó. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ṣe àṣeyọrísírere nínú ìgbéyàwó, a níláti tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jehofa. Òun ni ó dá wa. Nítorí náà, Ọ̀rọ̀ onímìísí rẹ̀ ní ìmọ̀ràn dídára jùlọ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lórí ìgbéyàwó nínú.

Ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ṣiṣẹ́ Kára fún Ìgbàlà Agbo-Ilé Rẹ” jíròrò àwọn ìpèníjà ti bíbójútó ìdílé kan ní àwọn àkókò lílekoko yìí. (2 Timoteu 3:1) Àwọn òbí ń kọ́ awọn ọmọ wọn ní àṣà ìmọ́tótó ti ara, ìwà-ọmọlúwàbí, bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́, àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́ àti ẹni tí ó lè bójútó àwọn ẹlòmíràn. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ìránṣẹ́ olùfọkànsìn fún Jehofa.​—⁠Owe 22:⁠6.

Nínú ìjíròrò tí ó tẹ̀lé e, “Ẹ̀yin Òbí, Àwọn Ọmọ Yín Nílò Àfiyèsí Àrà-Ọ̀tọ̀,” olùbánisọ̀rọ̀ náà rán àwọn olùpéjọpọ̀ létí àìní náà láti máa gbóríyìn fún àwọn ọmọ, láìdijú apákan sí àwọn àìlera wọn. Àwọn òbí ní pàtàkì gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àwọn ìtẹ̀sí síhà àìṣòótọ́, ìfẹ́-ọrọ̀-àlùmọ́ọ́nì, tàbí ìmọtara-ẹni-nìkan.

Àwọn ọ̀dọ́ olùpéjọpọ̀ fetísílẹ̀ ní pàtàkì sí ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Ẹ̀yin Èwe​—⁠Àwọn Ẹ̀kọ́ Ta Ni Ẹ̀yin Ń Kọbiara Sí?” Àwọn nǹkan nira fún àwọn ọ̀dọ́ Kristian lónìí. Ó rọrùn láti máa tọ ayé lẹ́yìn, ṣùgbọ́n èyí ń ṣamọ̀nà sí ikú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yíyàn láti faramọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá gba ìgboyà fún ọ̀dọ́ kan, ó ń mú ìbùkún ńlá wá nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun ní ọjọ́ iwájú.​—⁠1 Timoteu 4:⁠8.

Ọjọ́ kejì parí pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí ń mú ọkàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ náà Àwọn Èwe Tí Wọn Rántí Ẹlẹ́dàá Wọn Nísinsìnyí. Nínú ìnasẹ̀-ọ̀rọ̀ náà, olùdarí pe àwọn ọ̀dọ́ nínú ètò-àjọ Ọlọrun ní “ẹgbẹ́-ọmọ-ogun ìṣàkóso Ọlọrun tí wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin lọ́wọ́ nínú iṣẹ́-ìsìn àfitọkàntọkàn ṣe sí Jehofa Ọlọrun àti Ọba ọ̀run tí òun yàn, Kristi Jesu.” Ó fikún un pé: “Àwọn ọ̀dọ́ wa ń ṣe àṣeparí ohun dáradára kan níti tòótọ́!” Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà gbé àwòrán náà yọ ní kedere pé bí òbí kan bá kọ́ ọmọ kan dáradára, ìyẹn yóò ṣàǹfààní fún ọmọ náà nígbà tí ó bá dàgbà tí ó sì ń sin Jehofa ní àyè ara tirẹ̀.

Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kẹta

Ẹṣin-ọ̀rọ̀ fún ọjọ́ kẹta ni “Ẹ Máa Báa Lọ Ní Kíkọ́ Àwọn Ènìyàn Orílẹ̀-Èdè Gbogbo.” (Matteu 28:​19, 20) Kò sí iyèméjì pé àwọn olùpéjọpọ̀ náà retí ìmọ̀ràn tí ó bọ́sákòókò lórí iṣẹ́ ìwàásù, a kò sì já wọn kulẹ̀. Àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Fífi Tayọ̀tayọ̀ Mú Iṣẹ́ Wíwàásù àti Kíkọ́ni tí a Yàn fún Wa Ṣẹ” fún ìpinnu wọn láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà nìṣó lókun. Ọ̀rọ̀-àsọyé àkọ́kọ́ jíròrò ìkésíni àkọ́kọ́; ìkejì, ìpadàbẹ̀wò; àti ẹ̀kẹta, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Àwọn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run káàkiri ayé ni a ti késí láti padà wálé kí wọ́n sì lọ sí àpéjọpọ̀ kan pẹ̀lú àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ wọn. Ní àwọn ibi kan, àwọn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run kópa nínú apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí. Ó gbádùnmọ́ni láti gba ìjìnlẹ̀-òye díẹ̀ nípa àṣeyọrísírere tí wọn ń ní ìrírí rẹ̀ nínú àwọn iṣẹ́-àyànfúnni wọn. Ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, “Mímú Ìhìnrere Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Ènìyàn” ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà ń kó.

A mú òwúrọ̀ náà wá sí ìparí pẹ̀lú ọ̀rọ̀-àsọyé lórí ìrìbọmi, tí ó sábà máa ń jẹ́ kókó-ẹ̀kọ́ kan ní àwọn ìkórajọpọ̀ ńlá ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Láti àpéjọpọ̀ kan sí òmíràn, àwùjọ ńlá àwọn olùṣèyàsímímọ́ titun dúró níwájú ogunlọ́gọ̀ tí ó péjọ náà wọ́n sì fi ìdánilójú dáhùn bẹ́ẹ̀ni sí àwọn ìbéèrè méjì náà tí a darí rẹ̀ sí wọn. Lẹ́yìn náà ni wọ́n ṣe ìrìbọmi níwájú gbogbo ènìyàn. Ẹ wo ẹ̀rí alágbára tí èyí jẹ́ nípa ìyọrísí títóbilọ́lá ti ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá náà!

Ọ̀sán Ọjọ́ Kẹta

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sán bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjíròrò jíjinlẹ̀ lórí Ìwé Mímọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ àwọn ọ̀rọ̀ Matteu orí 24 àti Luku orí 21 ní àmọ̀dunjú. Àwọn kan ha ronú pé kò sí ohun titun kan tí a lè sọ nípa àwọn orí Bibeli yìí mọ́ bí? Ẹ wo bí ìyẹn ti ṣàìtọ̀nà tó! Àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Kí Ni Yoo Sì Jẹ́ Àmì Wíwàníhìn-⁠ín Rẹ?” àti “Sọ Fún Wa, Nígbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yoo Ṣẹ?” darí àwọn olùpéjọpọ̀ náà wọnú ìjíròrò fífanimọ́ra nínú àwọn ẹ̀ka-ìpín àwọn orí méjì wọ̀nyí ó sì pèsè àwọn ìsọfúnni tí ó bá àkókó mu lórí àwọn ẹsẹ díẹ̀. Àwọn ìjíròrò tí ń dánilárayá wà lẹ́yìn àkókò-ìjókòó náà bí àwọn olùpéjọpọ̀ ti ń fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ láti ríi bí wọ́n bá lóye àwọn kókó náà. Láìsí iyèméjì, ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè ni a óò dáhùn nígbà tí a bá tẹ ìsọfúnni yìí jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà.

Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ń báa lọ nínú ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Àwọn Ìdáhùn Tí Wọ́n Kún fún Ẹ̀kọ́ sí Àwọn Ìbéèrè Rẹ Lórí Bibeli.” Nígbà náà ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yí sí orí kókó mìíràn. Ọdún 1993 ní ó sàmìsí àyájọ́ àádọ́ta ọdún ti Watchtower Bible School of Gilead. Ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Àádọ́ta Ọdún Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti Ìgbòkègbodò Ìjíhìn-Iṣẹ́ Ọlọrun ti Gileadi” fi ohun tí a ti ṣe ní àṣeyege ní sáà-àkókò yẹn han àwọn olùpéjọpọ̀. Bí òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run kan bá wà ní ìjókòó nígbà tí a ń sọ ọ̀rọ̀-àsọyé náà “Àwọn Àṣeyọrí Iṣẹ́ Ìjíhìnrere Nínú Pápá Kárí-Ayé,” a késí wọn láti ṣàjọpín díẹ̀ lára àwọn ìrírí wọn pẹ̀lú àwùjọ. Gbígbọ́ ìròyìn àwọn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run náà múnilóríyá!

Ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, “Ìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Fi Ń Báa Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà,” jẹ́ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀-ìtàn mìíràn. Ó fihàn pé àwọn Kristian ti wà lẹ́nu ṣíṣọ́nà láti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní C.E. títí di ìsinsìnyí. Ìyẹn jálẹ̀ sí ìyàlẹ́nu mìíràn. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó tẹ̀lé e, ti a pe àkọlé rẹ̀ ní “Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Jẹ́ Aláápọn Ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé,” olùbánisọ̀rọ̀ náà gbé ìdìpọ̀ ńlá kan (nígbà tí ó ti wà ní èdè àdúgbò) ó sí wí pé: ‘Ó jẹ́ ayọ̀ mi láti ṣèfilọ̀ níhìn-⁠ín lónìí ìmújáde ìwé titún yìí, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Jehovah’s Witnesses​—⁠Proclaimers of God’s Kingdom.’ Ìwé náà ní ìròyìn kíkúnrẹ́rẹ́ nípa ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa òde-òní nínú. Ó sọ ìtàn tí ń rùmọ̀lárasókè nípa ìfaradà, ìgbèròpinnu, àti àṣeyọrísírere, tí ń fúnni ní ẹ̀rí lílágbára nípa ìgbékánkánṣiṣẹ́ ẹ̀mí Jehofa lórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Òwúrọ̀ Ọjọ́ Kẹrin

Ọjọ́ tí ó kẹ́yìn nínú àpéjọpọ̀ náà ti wá dé báyìí. Ẹṣin-ọ̀rọ̀ ti ọjọ́ náà, “Fífi Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ṣe Araawa Láǹfààní,” pèsè ìfojúsọ́nà fún òtéńté dídára kan fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. (Isaiah 48:17) Ní òwúrọ̀ àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó ní ọ̀rọ̀-àsọyé lílágbára mẹ́ta nínú gba gbogbo àfiyèsí àwọn olùpéjọpọ̀ náà pátápátá. A pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìhìn-Iṣẹ́ Ìkìlọ̀ Onímìísí ti Jeremiah​—⁠Fún Ìgbà tí ó ti Kọjá àti ti Ìsinsìnyí,” àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé náà ní ìjíròrò ẹlẹ́sẹẹsẹ ti Jeremiah orí 23, 24, àti 25 nínú. Ẹ sì wo àwọn ìhìn-iṣẹ́ lílágbára tí àwọn orí wọ̀nyí ní nínú! Àwọn ọmọ Israeli aláìṣòtítọ́ ti ọjọ́ Jeremiah ti gbọ́dọ̀ wárìrì sí àwọn ìkìlọ̀ olóòótọ́-ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a mísí látọ̀runwá. Gbogbo ayé tilẹ̀ wárìrì jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí a mú àwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn ṣẹ. Àwọn nǹkan ha yàtọ̀ lónìí bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fìgboyà wàásù àwọn ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí pátá yóò níláti dojúkọ àwọn ìṣe ìdájọ́ Ọlọrun. Ìyẹn yóò túmọ̀sí ìparun yán-⁠án yán-⁠án fún ayé Satani.

Òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday wá sí ìparí pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ kejì, Máṣe Jẹ́ Kí A Tàn Ọ́ Jẹ Má Sì Ṣe Gan Ọlọrun. Ní ọ̀nà tí ó ṣe kedere, ó fihàn bí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe lè dábòbòbò wá kúrò lọ́wọ́ dídi ẹni tí àwọn àwòrán fídíò àti orin arẹninípòwálẹ̀ nípa lélórí àti kúrò nínú ìtẹ̀sí kan láti fúnrúgbìn àìsí ìrẹ́pọ̀ láàárín àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ní ìparí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, alága fa àwọn ọ̀rọ̀ amúnironújinlẹ̀ ti ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn inú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà yọ pé: “A kò ní àjẹsára lòdìsí agbára ìdarí ayé. Bí a kò bá dè é lọ́nà, ayé lè fi ọgbọ́n wẹ́wẹ́ sọ ìrònú wa dìbàjẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rè é bóyá a jẹ́ olùṣòtítọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ yóò sinmi lórí ohun tí a ń fúnrúgbìn.” Ẹ wo bí ìyẹn ti jẹ́ òtítọ́ tó!

Ọ̀sán tí Ó Kẹ́yìn

Àpéjọpọ̀ náà ń yárakánkán súnmọ́ ìparí rẹ̀ bí olùbánisọ̀rọ̀ ti lọ sí ibi ìdúró sọ̀rọ̀ láti sọ ọ̀rọ̀-àwíyé fún gbogbo ènìyàn, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ̀kọ́ Arannilọ́wọ́ fún Àwọn Àkókò Lílekoko Wa.” Ní ọ̀nà ṣíṣe kedere tí ó sì bá ọgbọ́n ìrònú mu, ó fi àwọn ìṣòro pàtàkì tí ń nípa lórí wa lónìí hàn ó sì ṣàlàyé àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lè gbà ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí-ayé tí ó sàn jù. Ó sọ pé bí a bá ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá nísinsìnyí, yóò lè ṣeéṣe fún wa láti máa tẹ̀lé e títíláé nínú ayé titun ti Jehofa.

Lẹ́yìn àkópọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, àkókò tó fún ọ̀rọ̀-àsọyé tí ó gbẹ̀yìn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà yára sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́rin náà ó sì rán àwọn olùpéjọpọ̀ náà létí àwọn ìtẹ̀jáde titun náà. Ó tún ṣèfilọ̀ pé kásẹ́ẹ̀tì fídíò kejì nínú ọ̀wọ́ náà The Bible​—⁠A Book of Fact and Prophecy ni a máa tó mújáde. Níti tòótọ́, kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí a fún ní àkọlé náà The Bible​—⁠Mankind’s Oldest Modern Book, ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní Gẹ̀ẹ́sì nísinsìnyí. Àwọn ìròyìn tí ń ru ìmọ̀lára sókè láti àwọn ibi tí yánpọnyánrin lílekoko wà, bíi Bosnia àti Herzegovina ní a kà. Ní ìparí, olùbánisọ̀rọ̀ náà ka àwọn ọ̀rọ̀ Oniwasu 12:13: “Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọrun kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.”

Ẹ wo ìránnilétí rere tí èyí jẹ́! Ẹ jẹ́ kí a máa gbé ní ìrètí ọjọ́ náà nígbà tí gbogbo aráyé yóò yin Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa, Jehofa, kí a sì kọbiara sí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá rẹ̀.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Àwọn àpéjọpọ̀ “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní Moscow ati Kiev yọrísí ayọ̀ ńlá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]

1. Nípa ìrìbọmi, ọ̀pọ̀ fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọrun hàn

2. Ó dùnmọ́ olùpéjọpọ̀ ẹní 100 ọdún kan nínú láti gbà ìtẹ̀jáde titun kan

3, 4. Àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ amúnironújinlẹ̀ ni a mọrírì lọ́pọ̀lọpọ̀

5. Àwọn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò tẹnumọ́ àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́