ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 1/15 ojú ìwé 21-25
  • Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run Ẹ Má Ṣe Fi fún Ènìyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run Ẹ Má Ṣe Fi fún Ènìyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹṣin Ọrọ̀ Ọjọ́ Àkọ́kọ́: “Jèhófà, . . . Ìwọ Ni Ó Yẹ Láti Gba Ògo”
  • Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Kejì: “Ẹ Máa Polongo Ògo Rẹ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
  • Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Kẹta: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Fún Ògo Ọlọ́run”
  • Àwọn Àpéjọpọ̀ Tí Ń Rùmọ̀lárasókè Gbé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ga
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • A Rọ Àwọn Olùkọ́ni ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Ṣe Iṣẹ́ Tá A Gbé Lé Wọn Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” Péjọ Tayọ̀tayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé Ta Wá Jí Láti Fi Ògo fún Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 1/15 ojú ìwé 21-25

Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run Ẹ Má Ṣe Fi fún Ènìyàn

LÁWỌN oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo kárí ayé ló kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa fi ògo fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n kóra jọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run,” èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Ẹ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tá a gbádùn níbẹ̀.

Odindi ọjọ́ mẹ́ta làwọn tó lọ sí àpéjọ àgbègbè náà fi gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó dá lórí Bíbélì nígbà táwọn tó lọ sí àpéjọ àgbáyé tó jẹ́ àkànṣe gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún ọjọ́ mẹ́rin gbáko. Látòkè délẹ̀, ọ̀rọ̀ tó dá lórí Ìwé Mímọ́ tí gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà gbọ́ ju ọgbọ̀n lọ. Lára wọn ni àwọn àsọyé tó túbọ̀ mú ká mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí jinlẹ̀, àwọn ìrírí tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun, àwọn àṣefihàn tó ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti wọṣọ bíi tàwọn àrá ìgbàanì, tó sọ nípa inúnibíni táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dojú kọ. Bó o bá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọ àgbègbè náà, o ò ṣe kúkú ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ rẹ bí o ṣe ń kà àpilẹ̀kọ yìí? Ó dájú pé ìyẹn á jẹ́ kó o rántí àsè tẹ̀mí tó gbádùn mọ́ni tó o ti jẹ tẹ́lẹ̀ yìí, yóò sì tún kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.

Ẹṣin Ọrọ̀ Ọjọ́ Àkọ́kọ́: “Jèhófà, . . . Ìwọ Ni Ó Yẹ Láti Gba Ògo”

Lẹ́yìn orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, àsọyé tá a pe àkòrí rẹ̀ ní: “A Pé Jọ Láti Fi Ògo fún Ọlọ́run,” èyí tó dá lórí ìdí pàtàkì tá a fi pé jọ, ni ẹni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ fi kí gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀ káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Nígbà tó ń fà ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìṣípayá 4:11, olùbánisọ̀rọ̀ náà tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ fún àpéjọ náà. Ó ṣe àlàyé tó kúnná lórí ohun tó túmọ̀ sí láti fi ògo fún Ọlọ́run. O lo ìwé Sáàmù láti tẹnu mọ́ ọn pé fífi ògo fún Ọlọ́run kan ‘ìjọsìn,’ “ìdúpẹ́,” àti “ìyìn.”—Sáàmù 95:6; 100:4, 5; 111:1, 2.

Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀lé èyí ní àkòrí náà, “Ìbùkún Ni fún Àwọn Tó Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà pàfiyèsí sí ohun kan tó múnú ẹni dùn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní igba ilẹ̀ àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] kárí ayé, a lè sọ nígbà náà pé tọ̀sán tòru láwọn èèyàn ń fi ògo fún Jèhófà. (Ìṣípayá 7:15) Àwọn tó wà níbẹ̀ gbádùn bá a ṣe fọ̀rọ̀ wá àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lẹ́nu wò.

“Ìṣẹ̀dá Ń Polongo Ògo Ọlọ́run” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ tá a sọ tẹ̀ lé e. Bí wọn kò tìẹ lè sọ̀rọ̀, àwọn ẹ̀dá ojú ọ̀run ń gbé títóbi Ọlọ́run lárugẹ, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọyì bí Ọlọ́run ṣe ń bìkítà fún wá lọ́nà onífẹ̀ẹ́. A ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí kókó yìí.—Aísáyà 40:26.

Àwọn ohun tó máa ń ṣàkóbá fún ìwà títọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ ni inúnibíni, àtakò, ipa tí ayé ń ní lórí ẹni àti èrò tó máa ń wá sọ́kàn wa láti dẹ́sẹ̀. Abájọ tí ọ̀rọ̀ náà, “Máa Rìn ní Ọ̀nà Ìwà Títọ́” fi gbà àfiyèsí àwọn èèyàn. A jíròrò Sáàmù kẹrìndínlọ́gbọ̀n lẹ́sẹẹsẹ, a sì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ kí ohunkóhun ba ìwà rere òun jẹ́ àti ẹlòmíràn tó ń lo àkókò púpọ̀ nídìí àwọn eré ìdárayá tó ń kọni lóminú ṣùgbọ́n tó ti ṣe àwọn nǹkan kan láti ṣíwọ́ tó sì ti borí ìṣòro náà.

Lájorí àsọyé wa tó ní àkòrí náà, “Àwọn Ìran Ológo Tó Jẹ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Ń fún Wa Níṣìírí!” ló kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà mẹ́nu kan àpẹẹrẹ wòlíì Dáníẹ́lì, àti ti àpọ́sítélì Jòhánù òun Pétérù gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a fún ìgbàgbọ́ wọn lókun nípasẹ̀ ìran ológo tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tó kan bí a ṣe fìdí Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà ń dárí múlẹ̀ àti bí Ìjọba náà yóò ṣe ṣàkóso. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ń sọ nípa àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbàgbé ẹ̀rí kedere tó fi hàn pé a ti ń gbé ní àkókò òpin, ó sọ pé: “A nírètí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò tún padà gbájú mọ́ wíwàníhìn-ín Kristi nínú ògo Ìjọba èyí tó ti dòun báyìí, wọ́n yóò sì di ẹni tí a ràn lọ́wọ́ láti jèrè okun wọn padà.”

Àsọyé tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “A Ṣí Ògo Jèhófà Payá fún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀” la fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọ̀sán. Alásọyé náà fi hàn pé Jèhófà fi àpẹẹrẹ lílo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lélẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni Ẹni tó ga jù lọ láyé àti lọ́run. (Sáàmù 18:35) Jèhófà máa ń fi ojú rere hàn sáwọn tó fi tinútinú jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kì í dùn sáwọn tó máa ń lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kìkì nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn tó jẹ́ ẹgbẹ́ wọn tàbí àwọn tó jù wọ́n lọ ṣe nǹkan, àmọ́ tí wọ́n máa ń hùwà òǹrorò sáwọn tó wà lábẹ́ wọ́n.—Sáàmù 138:6.

Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e ni àpínsọ àsọyé tó ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan lóríṣiríṣi ọ̀nà, àkòrí rẹ̀ ni: “Àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì—Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa Lóde Òní.” Nígbà tí ẹni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí ń tọ́ka sí àpẹẹrẹ Ámósì, ó pàfiyèsí wa sí ojúṣe wa láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ìdájọ́ Jèhófà tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni “Fi Ìgboyà Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ẹni tó sọ̀rọ̀ ṣìkejì béèrè pé: “Jèhófà yóò ha fòpin sí ìwà ibi àti ìnira lórí ilẹ̀ ayé láé bí?” Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Àwọn Ẹni Ibi,” ó sì fi hàn nínú ọ̀rọ̀ yẹn pé ìdájọ́ Ọlọ́run tọ́ sí àwọn tó máa ń dé bá, ó tún fi hàn pé ìdájọ́ Ọlọ́run kò ṣeé sá fún, bákan náà ló fi hàn pé ìka tó bá ṣẹ nìkan ló máa ń gé. Ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ tó gbẹ̀yìn nínú àpínsọ àsọyé náà pàfiyèsí sí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Jèhófà Máa Ń Ṣàyẹ̀wò Ọkàn-Àyà.” Gbogbo ẹni tó bá wù láti mú inú Jèhófà dùn yóò ṣègbọràn sí ohun tó wà nínú Ámósì 5:15, tó sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.”

Àwọn ọtí, irú bíi wáìnì tó máa ń mú ọkàn yọ̀, ni a lè ṣì lò. Nínú ọ̀rọ̀ tá a pe àkọlé rẹ̀ ni: “Yẹra fún Ìdẹkùn Ọtí Àmujù,” ńṣe ni olùbánisọ̀rọ̀ náà to àwọn ewu nípa tara àti nípa tẹ̀mí tó wà nínú ọtí àmujù lẹ́sẹẹsẹ, kódà bí ẹni yẹn kò tiẹ̀ mutí para. Ó fún wa ní ìlànà tó lè ṣamọ̀nà wa pé: Níwọ̀n bí ìwọ̀n ọtí tára olúkúlùkù lè gbà tí yàtọ̀ síra, a jẹ́ pé ìwọ̀n yòówù tó bá ti lè ṣàkóbá fún “ọgbọ́n tó gbẹ́ṣẹ́ àti agbára [rẹ] láti ronú” ti pọ̀ jù fún ọ nìyẹn.—Òwe 3:21, 22.

Níwọ̀n bí a ti ń gbé ní àwọn àkókò tó le koko, ẹṣin ọ̀rọ̀ tó kàn jẹ́ orísun ìtùnú, ó sọ pé: “Jèhófà, ‘Odi Agbára Wa Ní Àkókò Wàhálà.’” Àdúrà, ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú wàhálà.

Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ náà ni, “‘Ilẹ̀ Dáradára’ Náà—Àpẹẹrẹ Bí Párádísè Yóò Ṣe Rí,” ó sì jẹ́ ìdùnnú ńlá fún gbogbo wa láti rí ìwé tuntun kan tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán ilẹ̀ inú Bíbélì nínú! Àkòrí ìwé ọ̀hún ni Wo Ilẹ̀ Dáradára Náà.

Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Kejì: “Ẹ Máa Polongo Ògo Rẹ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”

Lẹ́yìn tá a ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọjọ́ náà tán, ọpọ́n sún kàn àpínsọ àsọyé kejì ti àpéjọ náà, ẹ̀sìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ni “À Ń ‘Ṣe Àgbéyọ Ògo Jèhófà Bíi Dígí.’” Nínú apá àkọ́kọ́, a tú iṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lórí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pe a ń ṣe bẹ́ẹ̀ “Nípa Mímú Ìhìn Rere Náà Dé Ibi Gbogbo,” ó si fi àwọn àṣefihàn àwọn ìrírí tó ṣẹlẹ̀ gan-an lóde ìwàásù kún un. Nínú apá kejì, a ṣe àṣefihàn ìpadàbẹ̀wò kan nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ń ṣàlàyé kókó náà pé a ń ṣe bẹ́ẹ̀ “Nípa Ṣíṣí Ìbòjú Kúrò Lójú Àwọn Tá A Bò Lójú.” Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó gbẹ̀yìn àpínsọ àsọyé ọ̀hún sọ pé a ń ṣe bẹ́ẹ̀ “Nípa Gbígbé E Yọ Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa,” a sì fi àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó lárinrin nípa àwọn ìrírí tó ṣẹlẹ̀ lóde ìwàásù ti ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn.

Apá tó kàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ pé “Wọ́n Ń Kórìíra Wa Láìnídìí.” Ọ̀rọ̀ náà ní àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ń gbéni ró, tá a gbọ́ látẹnu àwọn olóòótọ́ èèyàn tí agbára Ọlọ́run ràn lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ mọ́ nígbà tí wọ́n dojú kọ àtakò.

Àsọyé ìrìbọmi jẹ́ apá tí gbogbo èèyàn máa ń wọ̀nà fún láwọn àpéjọ agbègbè, kété lẹ́yìn tí a sọ àsọyé náà tán ni a ṣèrìbọmi fún gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi tí wọ́n sì tóótun láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìrìbọmi nínú omi jẹ́ àmì pé ẹnì kan ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà. Abájọ tí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà: “Gbígbé Níbàámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ Wa Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run” fi bá a mu gẹ́lẹ́.

Àsọyé kan tó fún wa níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò ara wa la fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán, ó sọ pé: “Bí A Ṣe Lè Ní Èrò Kristi Nípa Ipò Ọlá.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà fa àwọn kókó pàtàkì yìí yọ pé: Fífarawé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Kristi la fi lè di ẹni ńlá. Nítorí náà, Kristẹni kan kò gbọ́dọ̀ máa wọ́nà láti dé ipò ọlá àṣẹ kìkì kó bàa lè tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé mo ṣe tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó lè ṣèrànwọ́ àmọ́ táwọn èèyàn kò ní tètè kíyè sí?’

Ǹjẹ́ ò tiẹ̀ máa ń rẹ̀ ọ́? Ó dájú pé gbogbo wa ló máa ń rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Gbogbo wa ló gbádùn àsọyé náà “Ó Ń Rẹ̀ Wá Àmọ́ A Kì Í Ṣàárẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tí a fi wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti pẹ́ nínú ètò àjọ yìí fi hàn pé Jèhófà lè sọ wá di “alágbára . . . nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.”—Éfésù 3:16.

Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ kì í ṣe ànímọ́ tá a bí mọ́ wá, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ́ béèyàn ṣe máa ń lawọ́. Kókò pàtàkì yìí la tẹnu mọ́ nínú àsọyé náà tó sọ pé “Ẹ jẹ́ Ká Jẹ́ Aláìṣahun, Ká Múra Tán Láti Ṣàjọpín.” A béèrè ìbéèrè tó muni ronú jinlẹ̀ yìí pé: “Ǹjẹ́ a múra tán láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀ lóòjọ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ àgbàlagbà, àwọn tó jẹ́ aláìlera, àwọn tó ní ìdààmú ọkàn tàbí àwọn tó dá nìkan wà?”

Ó dájú pé àsọyé náà “Ẹ Ṣọ́ra fún ‘Ohùn Àwọn Àjèjì’” gba àfiyèsí gbogbo àwọn èèyàn. Àsọyé yìí fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wé àwọn àgùntàn tó fetí sí kìkì ohùn Jésù nítorí pé ó jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” nígbà tí àwọn tí kò fetí sí Jésù ń fetí sí “ohùn àwọn àjèjì” èyí tó ń wá látinú onírúurú ọ̀nà tí Èṣù ń darí.—Jòhánù 10:5, 14, 27.

Ẹgbẹ́ akọrin kan gbọ́dọ̀ kọrin pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan kí orin tí wọ́n ń kọ lè nítumọ̀. Àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn kárí ayé náà gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ̀kan láti lè máa yin Ọlọ́run lógo. Nítorí náà, àsọyé tó sọ pé, “Ẹ Máa ‘Fi Ẹnu Kan’ Yin Ọlọ́run Lógo” fún wa ní ìtọ́ni tó ṣàǹfààní lórí bí a ṣe lè fi “èdè mímọ́ gaara” kan ṣoṣo sọ̀rọ̀ ká sì tún máa sin Jèhófà ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sefanáyà 3:9.

Ó dájú pé inú gbogbo àwọn òbí ló dùn gan-an, àgàgà àwọn tó ní àwọn ọmọ kéékèèké, nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ tó gbẹ̀yìn ọjọ́ kejì àpéjọ náà, ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni, “Àwọn Ọmọ Wa—Ogún Iyebíye Ni Wọ́n.” Inú gbogbo àwùjọ ló dùn láti rí ìwé tuntun olójú ewé ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́rin [256] tá a mú jáde. Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà yóò ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti lo àkókò tó mérè wá nípa tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn tó jẹ́ ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wọn.

Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ Kẹta: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Fún Ògo Ọlọ́run”

Ìránnilétí látinú ẹsẹ ojoojúmọ́ ni ìpèsè tẹ̀mí tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọ àgbègbè náà. Apá àkọ́kọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sórí ìdílé. Àsọyé àkọ́kọ́ tó sọ pé, “Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Gbé Agbo Ilé Yín Ró,” la fí múra ọkàn àwọn olùgbọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàtúnyẹ̀wò ojúṣe àwọn òbí láti pèsè àwọn ohun ti ara fún ìdílé wọn, ó wá fẹ̀rí hàn pé ojúṣe àwọn òbí ní pàtàkì jẹ́ láti pèsè ohun tẹ̀mí fún àwọn ọmọ wọn.

Àwọn ọmọ ni olùbánisọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ní tààràtà, ó sì sọ̀rọ̀ lórí kókó náà tó sọ pé: “Bí Àwọn Èwe Ṣe Ń Yin Jèhófà.” Ó sọ pé àwọn èwe dà bíi “ìrì tí ń sẹ̀” nítorí pípọ̀ tí wọ́n pọ̀ àti pé ìtara ìgbà èwe wọn máa ń tuni lára gan-an. Inú àwọn tó ti dàgbà máa ń dùn láti máa bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sáàmù 110:3) Apá yìí ní fífi ọ̀rọ̀ wá àwọn èwe tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ lẹ́nu wò nínú, ó sì lárinrin.

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ti wọṣọ bíi ti àwọn ará ìgbàanì jẹ́ apá kan tó máa ń mórí wa yá gan-an ní àwọn àpéjọ àgbègbè, èyí sì wáyé ní àpéjọ àgbègbè tó kọjá yìí pẹ̀lú. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà “Fífi Ìgboyà Jẹ́rìí Láìfàtakò Pè” ṣàpèjúwe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní. Kì í ṣe pé ó mórí wa ya nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún kún fún ẹ̀kọ́. “Ẹ Máa Polongo Ìhìn Rere Náà ‘Láìdabọ̀’” ni àkòrí ọ̀rọ̀ tó tẹ̀lé àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì fa àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà yọ.

Ara gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà ló wà lọ́nà láti gbọ́ kókó tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọjọ́ Sunday, ìyẹn ni àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí ó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Wo Ló Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run Lónìí?” Alásọyé náà fún wa ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro nípa bí àwùjọ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ti àwọn onísìn lápapọ̀ kò ṣe fi ògo fún Ọlọ́run. Kìkì àwọn tí à ń pe orúkọ Ọlọ́run mọ́, àwọn tó ń wàásù tó sì ń kọ́ni ní òtítọ́ nípa Jèhófà ni àwọn tó ń yin orúkọ Ọlọ́run lógo ní ti tòótọ́ lónìí.

Àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀sẹ̀ yẹn ló tẹ̀lé àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Lẹ́yìn náà ni a sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn, àkòrí rẹ̀ ni “‘Ẹ Máa So Èso Púpọ̀’ fún Ògo Jèhófà.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbé ìpinnu tó pín sọ́nà mẹ́wàá kan síwájú gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà. Àwọn ìpinnu náà dá lórí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ọ̀nà tá a lè gbà máa fi ògo fún Jèhófà Ẹlẹ́dàá. Ìró “Mo Fara Mọ́ Ọn” ló gbà gbogbo abẹ́ gbọ̀ngàn àpéjọ náà kan.

Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” ń dún gbọnmọgbọnmọ létí gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ náà bí a ṣe mú ìpàdé náà wá sópin. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí Jèhófà àti ti apá tó ṣeé fojú rí nínú ètò àjọ rẹ̀, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa wá ọ̀nà láti máa fi ògo fún Ọlọ́run, kí á má ṣe fi fún ènìyàn.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn Àpéjọ Àgbáyé

A ṣe Àpéjọ Àgbáyé tó jẹ́ ọlọ́jọ́ mẹ́rin ní Áfíríkà, Éṣíà, Ọsirélíà, Yúróòpù àti ní Àríwá òun Gúúsù Amẹ́ríkà. Àwọn Ẹlẹ́rìí káàkiri igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé ló wá sí àwọn ibi ìkórajọ yìí. Èyí wá jẹ́ kí “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” lè wà láàárín àwọn àlejò àtàwọn tó gbà wọ́n sílé. (Róòmù 1:12) Àwọn tó ti mọra tipẹ́ tún ri ara wọn, nígbà tí olúkúlùkù sì tún ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Apá pàtàkì kan nínú àwọn àpéjọ àgbáyé ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a pè ní “Ìròyìn Láti Àwọn Ilẹ̀ Mìíràn.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tuntun Tó Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run

Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun méjì la mú jáde ní Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run.” Ìwé Wo Ilẹ̀ Dáradára Náà ní àwọn àwòrán-ilẹ̀ tá a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì, ó jẹ́ ìwé tó ní ẹ̀yìn tí kò lè tètè fà ya, ó sì ni ojú ìwé mẹ́rìndínlógójì tó kún fún àwọn àwòrán ilẹ̀ àti fọ́tò àwọn ilẹ̀ tá a dárúkọ nínú Bíbélì. Gbogbo ojú ewé tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ aláwọ̀ mèremère, ó sì ní àwòrán ilẹ̀ tó fi ilẹ̀ ọba Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì àti Róòmù hàn. Àwòrán ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fi ìṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe gbilẹ̀ hàn.

Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ní ojú ewé ọ̀tàlénígba ó dín mẹ́rin [256] ó sì ní àwòrán tí kò dín ní ìgbà àti ọgbọ̀n [230]. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò lo lè gbádùn pẹ̀lú àwọn ọmọdé tẹ́ ẹ bá ń wo àwòrán tó wà nínú ìwé náà pà pọ̀ tí ẹ sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó wà nínú ìwé náà. A dìídì ṣe ìwé wa tuntun yìí láti kojú àtakò Sátánì lórí àwọn èwe wa, ìyẹn ìwà rere wọn tó sọ pé òun fẹ́ bà jẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn míṣọ́nnárì sọ àwọn ìrírí tó ń fún ìgbàgbọ́ lókun

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ìbatisí jẹ́ apá pàtàkì àpéjọ agbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àtọmọdé àtàgbà ló gbádùn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́