Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé Ta Wá Jí Láti Fi Ògo fún Ọlọ́run!
Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” ti jẹ́rìí ńláǹlà fáwọn èèyàn. Àwọn ìpàdé pàtàkì wọ̀nyí tí ètò àjọ Ọlọ́run ṣètò ti mú kí orúkọ Jèhófà di èyí tá a gbé ga, wọ́n sì ti túbọ̀ mú kó ṣeé ṣe fún wa láti “gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un.” (Sm. 96:8) Ká sòótọ́, ògo yẹ Ọlọ́run nítorí àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu, èyí tó ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ dáradára hàn.—Jóòbù 37:14; Ìṣí. 4:11.
Lo àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí pa pọ̀ pẹ̀lú àkọsílẹ̀ tìrẹ láti fi múra sílẹ̀ kí o sì kópa nínú àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè tó kọjá, èyí tí a ó ṣe ní ọ̀sẹ̀ February 16.
1. Báwo làwọn ìṣẹ̀dá aláìlẹ́mìí ṣe ń polongo ògo Ọlọ́run, báwo ni ìyẹn sì ṣe yàtọ̀ sí ọ̀nà táwa ẹ̀dá èèyàn ń gbà yìn ín? (Sm. 19:1-3; “Ìṣẹ̀dá Ń Polongo Ògo Ọlọ́run”)
2. Ohun tó ti fara hàn kedere báyìí wo ni ìyípadà ológo náà ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni ohun yìí ṣe ń fún àwa Kristẹni níṣìírí nínú iṣẹ́ ìsìn wa? (Lájorí àsọyé, “Àwọn Ìran Ológo Tó Jẹ́ Asọtẹ́lẹ̀ Ń Fún Wa Níṣìírí!”)
3. Báwo la ṣe lè ní irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí wòlíì Dáníẹ́lì ní, báwo la ó sì ṣe jàǹfààní tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀? (Dán. 9:2, 5; 10:11, 12; “A Ṣí Ògo Jèhófà Payá fún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀”)
4. (a) Àwọn ohun mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo nípa ìdájọ́ Ọlọ́run la lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì? (Ámósì 1:3, 11, 13; 9:2-4, 8, 14) (b) Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ tó jẹ́ ìkìlọ̀ tó wà nínú Ámósì 2:12? (“Àsọtẹ́lẹ̀ Ámósì—Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa Lóde Òní”)
5. (a) Àwọn ewu wo ló wà nínú mímu ọtí líle lámujù, kódà bí ẹnì kan ò bá tiẹ̀ mu àmupara pàápàá? (b) Báwo la ṣe lè borí ìṣòro mímu ọtí ní àmujù? (Máàkù 9:43; Éfé. 5:18; “Yẹra fún Ìdẹkùn Ọtí Àmujù”)
6. Báwo lo ṣe ń jàǹfààní nínú ìwé tuntun náà, Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà? (“‘Ilẹ̀ Dáradára’ Náà—Àpẹẹrẹ Bí Párádísè Yóò Ṣe Rí”)
7. Ọ̀nà mẹ́ta wo la lè gbà máa “ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bíi dígí”? (2 Kọ́r. 3:18; “À Ń ‘Ṣe Àgbéyọ Ògo Jèhófà Bíi Dígí’”)
8. Ta lẹni tó ń mú kí wọ́n kórìíra wa láìnídìí, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń kórìíra wa? (Sm. 109:1-3; “Wọ́n Ń Kórìíra Wa Láìnídìí”)
9. Kí ni èrò Kristi nípa ipò ọlá, báwo ni ẹnì kan sì ṣe lè mọ̀ bóyá ó yẹ kóun túbọ̀ ní irú èrò yìí? (Mát. 20:20-26; “Bí A Ṣe Lè Ní Èrò Kristi Nípa Ipò Ọlá”)
10. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró sán-ún nípa tẹ̀mí láìka àárẹ̀ ara sí? (“Ó Ń Rẹ̀ Wá Àmọ́ A Kì Í Ṣàárẹ̀”)
11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń lò láti gbé irọ́ lárugẹ, àwọn ìgbésẹ̀ tó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ló sì yẹ ká gbé láti gbéjà ko àwọn ohun tó lè dojú ìgbàgbọ́ wa dé? (Jòh. 10:5; “Ẹ Ṣọ́ra fún ‘Ohùn Àwọn Àjèjì’”)
12. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó wà nínú àkọsílẹ̀ Máàkù 10:14, 16? (b) Kí lo fẹ́ràn nípa ìwé tuntun náà, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà? (“Àwọn Ọmọ Wa—Ogún Iyebíye Ni Wọ́n”)
13. Báwo làwọn èwe ṣe ń yin Jèhófà? (1 Tím. 4:12; “Bí Àwọn Èwe Ṣe Ń Yin Jèhófà”)
14. Àwọn ohun wo lo rántí dáadáa nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Fífi Ìgboyà Jẹ́rìí Láìfàtakò Pè”?
15. Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ (a) Pétérù àti Jòhánù? (Ìṣe 4:10) (b) Sítéfánù? (Ìṣe 7:2, 52, 53) (d) ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní? (Ìṣe 9:31; àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti àwíyé náà, “Ẹ Máa Polongo Ìhìn Rere Náà ‘Láìdabọ̀’”)
16. (a) Àwọn ọ̀nà wo la pinnu láti gbà máa fi ògo fún Ọlọ́run? (b) Kí ló dájú pé a óò ní bá a bá ń fi ohun tá a kọ́ ní Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” sílò? (Jòh. 15:9, 10, 16; “‘Ẹ Máa So Èso Púpọ̀’ fún Ògo Jèhófà”)
Bá a bá ń ṣàṣàrò lórí ìtọ́ni tẹ̀mí tó dára gan-an tí a gbádùn ní àpéjọ àgbègbè yìí, yóò sún wa láti fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò. (Fílí. 4:8, 9) Nípa bẹ́ẹ̀, ìpinnu wa láti “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run” yóò túbọ̀ lágbára sí i.—1 Kọ́r. 10:31.