Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 9
Orin 225
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn kan nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 15 lọni. Bákan náà, fi hàn bá a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bíi “Mo ní ìsìn tèmi.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 10.
10 min: “Jàǹfààní Látinú Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.” Àsọyé tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sọ, èyí tí yóò gbé ka àpilẹ̀kọ yìí. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, sọ̀rọ̀ nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ka ìpínrọ̀ 23 lójú ìwé 25 nínú ìwé náà, kó o sì ṣàlàyé rẹ̀.
25 min: “Máa Bá A Nìṣó Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Jèhófà.”a (Ìpínrọ̀ 1 sí 10) Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Sọ ọ̀rọ̀ tí yóò ta àwọn ará jí láti túbọ̀ kópa nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà Ìṣe Ìrántí.
Orin 90 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 16
Orin 41
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù February sílẹ̀.
40 min: “Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé Ta Wá Jí Láti Fi Ògo fún Ọlọ́run! Alàgbà ni kó bójú tó o. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìṣẹ́jú kan tàbí kó má tó ìṣẹ́jú kan, kí o lo àwọn ìbéèrè inú àpilẹ̀kọ náà láti fi bá àwùjọ jíròrò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè. Pín àkókò rẹ dáadáa kí ó fi lè ṣeé ṣe fún yín láti gbé gbogbo ìbéèrè ibẹ̀ yẹ̀ wò, bóyá kó o kàn gba ìdáhùn kan ṣoṣo láwọn ìbéèrè kan. Kì í ṣe gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lẹ máa lè kà láàárín àkókò tí a yàn fún iṣẹ́ náà; ńṣe la fi wọ́n síbẹ̀ kí ó fi lè rọrùn láti rí àwọn ìdáhùn ibẹ̀. Kí ìdáhùn àwọn ará dá lórí àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn ohun tá a kọ́ sílò.
Orin 112 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 23
Orin 118
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! March 8 lọni. Lo àbá kẹta tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! March 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn tí a bá ti parí ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, béèrè ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ kan lọ́wọ́ onílé, èyí tó o lè wá fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè dáhùn nígbà tó o bá tún padà wá.
15 min: “Máa Bá A Nìṣó Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Jèhófà.”b (Ìpínrọ̀ 11 sí 17) Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ṣètò pé kí a ṣe àṣefihàn ṣókí kan nípa bí akéde kan ṣe ń ké sí ìpadàbẹ̀wò rẹ̀ wá sí Ìṣe Ìrántí.
20 min: Máa Yin Jèhófà “ní Àárín Ìjọ.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ September 1, 2003, ojú ìwé 19 sí 22. (1) Báwo ni Sáàmù 22:22, 25 ṣe fi ìdí tí a fi ń dáhùn ní ìpàdé hàn kedere? (2) Kí nìdí tí àdúrà fi ṣèrànwọ́? (3) Kí nìdí tó fi yẹ ká múra sílẹ̀? (4) Kí ló yẹ kí gbogbo wa ní lọ́kàn pé a fẹ́ rí i pé a ṣe ní ìpàdé? (5) Kí nìdí tí jíjókòó sápá iwájú fi ṣèrànwọ́? (6) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti fetí sílẹ̀ sí ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń sọ? (7) Báwo la ṣe lè dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara wa láìsí pé à ń ka ìdáhùn jáde ní tààràtà látinú ìwé? (8) Báwo la ṣe lè lo ìdáhùn wa láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí? (9) Kí ni ojúṣe ẹni tó ń darí ìpàdé?
Orin 81 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 1
Orin 156
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù February sílẹ̀. Sọ ìwé tí a ó fi lọni lóṣù March, kó o sì gbé ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002 yẹ̀ wò ní ṣókí.
15 min: Sọ̀rọ̀ lórí “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso” tá a fi ránṣẹ́ pa pọ̀ mọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.
20 min: “A Lè Ṣe Ohun Tí Jèhófà Ní Ká Ṣe.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí.
Orin 98 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o sì bójú tó ìjíròrò náà nípa lílo ìbéèrè àti ìdáhùn.