Àwọn Ìfilọ̀
◼ February: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye tàbí ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! gẹ́gẹ́ bí àfidípò. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bí àwọn onílé bá ti ní ìwé yìí, a lè fi ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! lọ̀ wọ́n. April àti May: Kí a fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò rẹ̀ àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ètò àjọ Ọlọ́run, kí a fún wọn ní ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. Kí a sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá bí a bá rí àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e. Ẹ ka ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ èyíkéyìí láti ẹ̀ka ọ́fíìsì nípa ọrẹ tí ìjọ fi ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé àti owó àkànlò èyíkéyìí mìíràn tí ètò àjọ ṣètò.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún èyíkéyìí lára wọn láti ní iye wákàtí tí à ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà S-201-YR, èyí tí Society máa ń kọ lọ́dọọdún.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2004 ni, “Jẹ́ Onígboyà, Kí O sì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà.” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2003.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run—Ègùn
Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 25)—Èdè Gokana
Sún Mọ́ Jèhófà—Ègùn
Hellfire—Is It Part of Divine Justice? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 74)—Èdè Lárúbáwá
Watch Tower Publications Index 2002—Gẹ̀ẹ́sì
Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Ègùn
Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 26)—Èdè Abua, Gokana, Ìgalà, Lárúbáwá, Ùròbò
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!—Èdè Khana
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí fún Àwọn Afọ́jú:
Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 25)—Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì
Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 26)—Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì
◼ Fídíò Tuntun Tó Wà Báyìí:
Elementary Bible Teachings—On Videocassette, Apá Kìíní àti Ìkejì—Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà
Respect Jehovah’s Authority—On Videocassette—Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà
◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí a óò ṣe lọ́dún 2004, a ó ṣètò àyè ìjókòó lọ́tọ̀ fún àwọn adití ní àwọn àyíká tí a to orúkọ wọn sísàlẹ̀ yìí, níbi tí a ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà:
Akabo (EE-08) February 21 àti June 5-6.
Àkúrẹ́ (WE-12) September 12 àti May 22-23.
Badagry (WE-02) March 6 àti July 17-18.
Badagry (WE-04) September 5 àti May 15-16.
Badagry (WE-23) September 4 àti May 1-2.
Calabar (EE-21) February 7 àti August 28-29.
Dálùwọ́n (WE-03) July 17 àti March 6-7.
Dálùwọ́n (WE-13) June 24 àti February 7-8.
Ẹnúgu (EE-17) March 6 àti July 10-11.
Ìbàdàn (WE-09) June 13 àti February 14-15.
Igwuruta Ali (EE-22) March 27 àti July 17-18.
Iléṣà (WE-15) February 14 àti July 3-4.
Kàdúná (NE-01b) February 15 àti May 29-30.
Ọ̀tà (WE-06) February 28-29.
Ọ̀tà (WE-07) March 24, àti July 10-11.
Ùbogò (ME-07) June 20 àti February 28-29.
Ùlì (EE-24) August 22 àti April 24-25.