Ìfẹ́ Ló Ń Mú Ká Wàásù
1 Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa pé a máa ń fi ìtara wàásù ìhìn Ìjọba náà. (Mát. 24:14) Ó ju àwa mílíọ̀nù mẹ́fà tó ń ṣiṣẹ́ yìí kárakára jákèjádò ayé; àwọn ẹni tuntun sì tún máa ń di ara wa nígbà tí wọ́n bá dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Iye àwọn tó bá ń kópa nínú iṣẹ́ yìí la máa ń gbé jáde.
2 Kí ló ń mú ká yọ̀ǹda ara wa fún irú iṣẹ́ tó ń peni níjà yìí? Kò sẹ́ni tó fagbára mú wa, kò sí pé èrè owó kan ló wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí pé ipò ọlá àkànṣe kan ni wọ́n fi lọ̀ wá. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀pọ̀ nínú wa ló bẹ̀rù nítorí pé a ronú pé a ò tóótun, àti pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ tiwa. (Mát. 24:9) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wò wá ni kò mọ ohun tó ń mú ká ṣe iṣẹ́ ọ̀hún. Ìdí pàtàkì kan gbọ́dọ̀ wà táa fi tẹra mọ́ ọn.
3 Agbára Tí Ìfẹ́ Ní: Jésù sọ èyí tó tóbi jù lọ nínú gbogbo òfin nígbà tó sọ pé ‘kí a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa àti pẹ̀lú gbogbo okun wa.’ (Máàkù 12:30) Ohun tó mú ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé a ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún un ní ti irú ẹni tó jẹ́ àti ohun tó jẹ́, pé òun ni Alákòóso tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, tó “yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára.” (Ìṣí. 4:11) Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu kò láfiwé.—Ẹ́kís. 34:6, 7.
4 Mímọ Jèhófà àti nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń mú ká jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn níwájú àwọn èèyàn. (Mát. 5:16) Ìmọ́lẹ̀ wa ń tàn nígbà tí a bá ń yìn ín ní gbangba, tí a bá ń sọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀, tí a sì ń sọ nípa ìhìn Ìjọba rẹ̀ níbi gbogbo. Bíi ti áńgẹ́lì tó ń fò lágbedeméjì ọ̀run, a ní “ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bíi làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ . . . fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Ìfẹ́ táa ní ló fà á táa fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò ayé.
5 Ayé ń wò ó pé iṣẹ́ ìwàásù táa ń ṣe jẹ́ “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” tí kò yẹ kí wọ́n fetí sí. (1 Kọ́r. 1:18) Wọ́n ti sapá níbi púpọ̀ láti tẹ iṣẹ́ wa rì. Àmọ́, ìfẹ́ adúróṣinṣin táa ní ti fún wa lágbára láti polongo, bí àwọn àpọ́sítélì ti ṣe pé: “Àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́. . . . Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 4:20; 5:29) Iṣẹ́ ìwàásù wa ń bá a nìṣó láti máa gbilẹ̀ ní apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé láìka àtakò sí.
6 Ńṣe ni ìfẹ́ táa ní sí Jèhófà dà bí iná tí ń jó tó ń mú ká máa polongo àwọn ìtayọlọ́lá rẹ̀ káàkiri. (Jer. 20:9; 1 Pét. 2:9) A óò máa bá a nìṣó láti “sọ àwọn ìbánilò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn . . . nítorí pé ó ti ṣe ohun tí ó ta yọ ré kọjá”!—Aísá. 12:4, 5.