Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Kí àwọn akéde sọ fún àwọn tí wọ́n ń wàásù fún pé wọ́n lè ṣe ìtìlẹyìn ọrẹ fún iṣẹ́ yíká ayé. Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. June: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, fi ìwé pẹlẹbẹ kan tó bá àkókò yẹn mu tí ìjọ ní lọ́wọ́ lọni.
◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April múra sílẹ̀ nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè forúkọ sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Lóṣooṣù, kí a máa kéde orúkọ gbogbo àwọn tá a fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ.
◼ Ìṣe Ìrántí yóò wáyé ní Thursday, March 28, 2002. Bó bá jẹ́ pé ọjọ́ Thursday ni ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé, ẹ yí ìpàdé náà sí ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn bí àyè bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe, tí ó sì forí sọ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yín, ẹ lè fi àwọn apá tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn mìíràn.
◼ Kì í ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ló ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tí kíkọ̀wé béèrè fún wọn jẹ́ lákànṣe.
◼ Kí ẹ máa béèrè àwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ tàwọn afọ́jú nípasẹ̀ ìjọ. Kí ẹ fi fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14) mìíràn ránṣẹ́ nígbà tí ẹ bá ń béèrè àwọn ìtẹ̀jáde tó jẹ́ tàwọn afọ́jú, títí kan orúkọ àti àdírẹ́sì ẹni tó fẹ́ kà á. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kọ ATTENTION: BRAILLE DESK sórí fọ́ọ̀mù náà.
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí àwùjọ tó bá ti tó ogún èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń wéwèé láti ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka kọ́kọ́ kọ̀wé sí Watch Tower Society, P.M.B. 1090, Benin City 300001, Edo State. Kí ẹ jọ̀wọ́ fi ìsọfúnni ránṣẹ́ nípa iye àwọn tó ń bọ̀, déètì tí wọ́n máa wá àti àkókò tí wọ́n máa wá ṣèbẹ̀wò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ìjọ èyíkéyìí tó ń bọ̀ wá ṣèbẹ̀wò rí i dájú pé wọ́n ṣàkọsílẹ̀ orúkọ gbogbo àwọn tó máa bá àwùjọ náà rìnrìn àjò, kí wọ́n sì jẹ́ kí orúkọ àwọn tó ti ṣèrìbọmi, àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, àtàwọn olùfìfẹ́hàn hàn ketekete nínú àkọsílẹ̀ náà. A kò ní í gba ẹlòmíràn láyè láti bá ìjọ náà rìn yí ká Bẹ́tẹ́lì àyàfi àwọn tórúkọ wọn bá wà nínú àkọsílẹ̀ nìkan. Kí ẹ rí i pé ẹ tètè gbéra kúrò nílé kẹ́ ẹ bàa lè padà lọ́jọ́ kan náà, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti parí ìbẹ̀wò yín. Ẹ rí i pé ọkọ̀ tó máa gbé e yín wá wà ní ipò tó dára. Ṣáájú kẹ́ ẹ tó ó wá, kí ẹ jọ̀wọ́ ṣàtúnyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1998, tó sọ nípa ìwọṣọ àti ìmúra lọ́nà tó bójú mu nígbà tá a bá ń ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì.
◼ Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti wà báyìí ní ìtẹ̀jáde onílẹ́tà gàdàgbà ní èdè Ẹ́fíìkì, Ìgbò àti Yorùbá.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
A Satisfying Life—How to Attain It—Gẹ̀ẹ́sì
Does Fate Rule Our Lives?—Or Does God Hold Us Responsible? (fún àwọn Mùsùlùmí) (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 71)—Gẹ̀ẹ́sì
The Greatest Name (fún àwọn Mùsùlùmí) (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 72)—Gẹ̀ẹ́sì
Who Are Jehovah’s Witnesses? (fún àwọn Mùsùlùmí) (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 73)—Gẹ̀ẹ́sì
Hellfire—Is It Part of Divine Justice? (fún àwọn Mùsùlùmí) (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 74)—Gẹ̀ẹ́sì
Watch Tower Publications Index 1986-2000—Gẹ̀ẹ́sì
Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?—Ẹ̀dó, Ùròbò
New World Translation of the Christian Greek Scriptures—Ìgbò
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí:
Awọn Akori Ọrọ Bibeli Fun Ijiroro—Haúsá