Máa Bá A Nìṣó Nínú Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà
1 Kò sí àní-àní pé a mọyì àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà láàárín wa. Wọ́n ń ṣe gudugudu méje nínú bí wọ́n ṣe ń wá àwọn ẹni yíyẹ kàn nínú ìpínlẹ̀ ìjọ. Abájọ tí inú wa ṣe máa ń dùn nígbà táwọn aṣáájú ọ̀nà bá túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ìjọ.
2 Àmọ́ ṣá o, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn aṣáájú ọ̀nà kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Wọ́n ń pinnu láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro díẹ̀ ló yọjú. Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001, àwọn aṣáájú ọ̀nà tí iye wọ́n jẹ́ 1,176 ní Nàìjíríà ló padà di akéde. Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ló fa èyí. Ó lè jẹ́ pákáǹleke ọjọ́ ìkẹyìn tí ó nira láti bá lò yìí, àìsàn líle koko, títọ́jú òbí tàbí ẹnì kejì ẹni nínú ìgbéyàwó, ojúṣe ìdílé tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tàbí àwọn nǹkan mìíràn. (2 Tím. 3:1) Ó dùn wá gan-an pé àwọn ìṣòro wọ̀nyí ti jẹ́ kí àwọn kan fi iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà sílẹ̀. Ìrànlọ́wọ́ wo la lè ṣe fún àwọn ajíhìnrere tí ó ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyí kí púpọ̀ sí i lára wọn má bàa máa fi iṣẹ́ ìsìn wọn sílẹ̀? Kí ló yẹ kí wọ́n ṣe láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà?
3 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìrẹ̀wẹ̀sì Bò Ọ́ Mọ́lẹ̀: Òwe 24:10 sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn aṣáájú ọ̀nà ń bá yí. Bí ìrẹ̀wẹ̀sì bá tún wá lọ pẹ̀lú rẹ̀, ìṣòro wọn á túbọ̀ pọ̀ sí i, èyí á sì mú kí gbogbo nǹkan tojú sú wọn. Níwọ̀n bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti ń béèrè ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn aṣáájú ọ̀nà jẹ́ aláyọ̀ láti lè máa bá a nìṣó.—Neh. 8:10.
4 Bí àwọn ìránṣẹ́ alákòókò kíkún bá ń sapá láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sìn pa pọ̀, èyí yóò fi kún ayọ̀ wọn. Nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa jẹ́ aláyọ̀, kódà nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá ṣẹ̀ wọ́n. Èyí yóò ṣeé ṣe bí wọ́n bá ń rántí pé aláìpé bíi tiwọn làwọn arákùnrin wọn náà, àti pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣàṣìṣe. (Ják. 3:2) Bí ẹni tí a jọ jẹ́ Kristẹni bá ṣẹ aṣáájú ọ̀nà kan, irú aṣáájú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ lè gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ láti lè gbójú fo àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó onítọ̀hún dá.
5 Bó bá jẹ́ àìsàn ló ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Àwọn aṣáájú ọ̀nà kan ti ń bá a nìṣó láìka bí ìlera wọn ti ń jó rẹ̀yìn sí, nítorí wọ́n mọ̀ pé nípa fífarada àdánwò, àwọn ń fi Èṣù hàn ní òpùrọ́.—Òwe 27:11.
6 Ẹnì kan tó ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ohun tó lé ní ọdún márùnlélógójì fún àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ìṣòro ń wọ̀ lọ́rùn ní ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí. Ó sọ pé: “Ṣe ló yẹ ká máa ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tá a ní, ká sì tún máa ní in lọ́kàn pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹlòmíràn ló ń kojú ìṣòro tó ju tiwa lọ.” Ìmọ̀ràn yìí mà ń fini lọ́kàn balẹ̀ o!—1 Pét. 5:6-9.
7 Máa Fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Níṣìírí: Kò sẹ́ni tí kò nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí, nítorí ó ń mú ká tẹ̀ síwájú. Kálukú wa ló yẹ ká máa fún àwọn aṣáájú ọ̀nà níṣìírí. Wọ́n nílò ọ̀rọ̀ ìṣírí látọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tá a yàn àti látọ̀dọ̀ àwọn akéde ìjọ pẹ̀lú. Jèhófà sọ fún Mósè pé kí ó fún Jóṣúà níṣìírí, kí ó sì fún un lókun. (Diu. 3:28) Ǹjẹ́ o lè ṣèrànwọ́ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà, bóyá nípa bíbá wọn jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́jọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀, tó jẹ́ pé ìwọ̀nba làwọn ẹni tó máa ń jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn tàbí kí ẹnikẹ́ni máà sí láti bá jáde? Ǹjẹ́ yóò lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà nípa sísan lára owó tí wọ́n fi ń wọkọ̀ tàbí kó o ṣètìlẹyìn fún àwọn ìnáwó wọn mìíràn bó bá pọn dandan? Ǹjẹ́ o lè máa ké sí wọn wá sí ilé rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wá bá ọ jẹun tàbí kó o máa ṣàjọpín àwọn nǹkan jíjẹ mìíràn tó o ní pẹ̀lú wọn? Ṣé wàá máa sọ̀rọ̀ ìmọrírì tí ó lè gbé wọn ró nítorí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn?
8 Ìforítì Ṣe Pàtàkì: Ìforítì ṣe pàtàkì láti lè dójú ìlà wákàtí tá a béèrè. Ká sọ tòótọ́, ìṣòro àtijẹ-àtimu, ojúṣe tara ẹni tàbí àwọn ẹrù iṣẹ́ inú ìjọ lè ṣèdíwọ́ fún àwọn kan láti má lè dójú ìlà wákàtí tá a béèrè. Àmọ́ ṣá o, ohunkóhun yòówù tí ì báà jẹ́ tó lè máa mú kí wákàtí aṣáájú ọ̀nà déédéé kan lọ sẹ́yìn gan-an ní gbogbo ìgbà, irú aṣáájú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kò ní tóótun láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà bí ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn ìjọ bá fohùn ṣọ̀kan pé ìṣòro náà kò lè lójútùú láàárín ìwọ̀nba oṣù díẹ̀, àyàfi bí ó bá wà lára àwọn aṣáájú ọ̀nà tá a kà sí aláìlera.
9 Nítorí ìdí yìí, àwọn tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní láti máa “tiraka tokuntokun” láti fi hàn pé àwọn mọyì àǹfààní tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà gan-an. (Lúùkù 13:24) Wọ́n ní láti máa fi àwọn ohun kan du ara wọn kí wọ́n lè máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. (Héb. 13:15) Àwọn aṣáájú ọ̀nà tún ní láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè déédéé kí wọ́n bàa lè jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí. Èyí ń béèrè ọ̀pọ̀ ìsapá àti ìwéwèé gúnmọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà tó ti ṣàṣeyọrí ṣe sọ.—Éfé. 5:15, 16.
10 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ìbùkún ńláǹlà làwọn aṣáájú ọ̀nà jẹ́ fún ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa tì wọ́n lẹ́yìn, ká sì máa fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè máa bá a nìṣó.