Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
Ọjọ́ Thursday, March 24 la ó ṣe Ìṣe Ìrántí ti ọdún yìí. Kí àwọn alàgbà rí i pé a ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí:
◼ Tí ẹ bá ń ronú nípa àkókò tẹ́ ẹ máa fi ayẹyẹ yìí sí, ẹ rí i dájú pé ó bọ́ sí àkókó tó jẹ́ pé oòrùn á ti wọ̀ kẹ́ ẹ tó gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ káàkiri.
◼ Kí a jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ àkókò pàtó tí a ó ṣe ayẹyẹ náà àti ibi tí a ó ti ṣe é, ká sì sọ fún olùbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú.
◼ Kí a wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ, kí wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003, ojú ìwé 14 àti 15.
◼ Kí a gbé àwọn àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu wá sí gbọ̀ngàn ìpàdé tá a fẹ́ lò, kí a sì ti tò wọ́n ṣáájú àkókò.
◼ Kí a tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a ó lò ṣe ṣáájú àkókò, ká rí i pé ó mọ́ tónítóní.
◼ Kí a yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú àkókò nípa ojúṣe wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, àti bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí ìmúra wọn bójú mu.
◼ Kí a ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tó bá jẹ́ aláìlera tí kò ṣeé ṣe fún láti wá.
◼ Tí a bá ṣètò pé kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí èrò má báa pọ̀ jù ní gbogbo ibi àbáwọlé, ojú ọ̀nà àti ibi ìgbọ́kọ̀sí.