Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí
Ọjọ́ Sunday, April 4 la ó ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí. Kí àwọn alàgbà bójú tó àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí:
◼ Tí ẹ bá ń ṣètò àkókò tẹ́ ẹ máa fi ìpàdé yìí sí, ẹ rí i dájú pé a kò ní gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà káàkiri àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.
◼ Kí a jẹ́ kí gbogbo èèyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀, mọ àkókò pàtó tí a ó ṣe ayẹyẹ náà àti ibi tí a ó ti ṣe é.
◼ Kí a wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ, kí wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003, ojú ìwé 14 àti 15.
◼ Kí a gbé àwọn àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu wá sí gbọ̀ngàn ìpàdé náà kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.
◼ Kí a tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a ó lò ṣe, kó sì wà ní mímọ́ tónítóní ṣáájú àkókò.
◼ Kí a yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì ti fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú àkókò nípa ojúṣe wọn, bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, àti bó ti ṣe pàtàkì tó láti múra lọ́nà tó bójú mu.
◼ Kí a ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tó jẹ́ aláìlera tí kò ṣeé ṣe fún láti wá.
◼ Tí a bá ṣètò pé kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí gbogbo ibi àbáwọlé, ojú ọ̀nà àti ibi ìgbọ́kọ̀sí má bàa kún fún èrò jù.