ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/06 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 3/06 ojú ìwé 7

Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi

Ọjọ́ Wednesday, April 12 la ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí. Kí àwọn alàgbà rí i pé wọ́n ṣe àwọn ètò tó wà nísàlẹ̀ yìí.

◼ Kẹ́ ẹ tó mú àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa wáyé, ẹ rí i dájú pé àkókò tẹ́ ẹ bá mú á bọ́ sí àkókò tí oòrùn á ti wọ̀ kẹ́ ẹ tó gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ káàkiri.

◼ Gbogbo èèyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀, ló gbọ́dọ̀ mọ àkókò pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò wáyé ká sì sọ ibi tá a ti máa ṣe é fún wọn.

◼ Irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ la gbọ́dọ̀ wá, ká sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003, ojú ìwé 14 àti 15.

◼ Àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu la gbọ́dọ̀ lò, a sì ti gbọ́dọ̀ tò wọ́n sílẹ̀ ṣáájú àkókò.

◼ A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a ó lò wà ní mímọ́ tónítóní ṣáájú àkókò.

◼ A gbọ́dọ̀ yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ṣáájú ọjọ́ náà, ká sì ti fún wọn nítọ̀ọ́ni nípa ojúṣe wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ àti ìmúra wọn gbọ́dọ̀ bójú mu fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.

◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò bá ṣeé ṣe fún láti wá nítorí àìlera.

◼ Bó bá jẹ́ pé ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ la ṣètò pé kó lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, àwọn ìjọ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí èrò má bàa pọ̀ jù ní gbogbo ibi àbáwọlé, ojú ọ̀nà àti ibi ìgbọ́kọ̀sí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́