Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi
Ọjọ́ Monday, April 2 la ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí. Káwọn alàgbà rí i pé wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nísàlẹ̀ yìí.
◼ Kẹ́ ẹ tó mú àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí á wáyé, ẹ rí i dájú pé àkókò tẹ́ ẹ bá mú á bọ́ sí àkókò tí oòrùn á ti wọ̀ kẹ́ ẹ tó gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ káàkiri.
◼ Gbogbo èèyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀, ló gbọ́dọ̀ mọ àkókò pàtó tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò wáyé, kẹ́ ẹ sì sọ ibi tá a ti máa ṣe é fún wọn.
◼ Irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ lẹ gbọ́dọ̀ wá, kẹ́ ẹ sì rí i pé wọ́n wà ní sẹpẹ́.—Wo Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003, ojú ìwé 14 àti 15.
◼ Àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu ni kẹ́ ẹ lò, ẹ sì ti gbọ́dọ̀ tò wọ́n sílẹ̀ kó tóó tó àkókò.
◼ Ẹ rí i pé, inú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tẹ́ ẹ máa lò wà ní mímọ́ tónítóní kó tóó tó àkókò.
◼ Kó tóó di ọjọ́ náà ni kẹ́ ẹ ti yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kẹ́ ẹ sì ti fún wọn nítọ̀ọ́ni nípa ojúṣe wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é. Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé aṣọ tí wọ́n máa wọ̀ àti ìmúra wọn gbọ́dọ̀ bójú mu fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.
◼ Ẹ rí i pé ẹ ṣètò láti gbé ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí àìlera ò bá jẹ́ kó lè wá.
◼ Bó bá jẹ́ pé ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ ló máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, àwọn ìjọ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí èrò má bàa pọ̀ jù níbi àbáwọlé, lójú ọ̀nà àti níbi ìgbọ́kọ̀sí.