Apá Kẹfà: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Kan Bá Béèrè Ìbéèrè
1 Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti fìdí múlẹ̀, ohun tó máa ń dára jù ni pé ká máa gbé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹ̀ wò lẹ́sẹẹsẹ dípò ká kàn máa mú ẹ̀kọ́ Bíbélì lórí-nídìí. Èyí á jẹ́ kí òye òtítọ́ máa yé akẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, á sì jẹ́ kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Kól. 1:9, 10) Àmọ́ o, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń béèrè onírúurú ìbéèrè nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́. Kí ló yẹ ká ṣe nípa èyí?
2 Lo Òye: A lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó bá jẹ mọ́ ohun tí à ń kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí ìdáhùn sí ìbéèrè kan bá ṣì wà níwájú nínú ìwé tí à ń kà, a kàn lè sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ pé á rí ìdáhùn níwájú. Ṣùgbọ́n bí ìbéèrè akẹ́kọ̀ọ́ ò bá jẹ mọ́ ohun tí à ń kọ́ tàbí tó jẹ́ pé a ní láti ṣèwádìí ká tó lè dá a lóhùn dáadáa, ó máa dára pé ká gbé e yẹ̀ wò lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà mìíràn. Ńṣe làwọn akéde kan máa ń kọ ìbéèrè akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, nítorí pé èyí máa ń fi í lọ́kàn balẹ̀ pé wọn ò fojú kékeré wo ìbéèrè òun. Bákan náà, èyí kò ní jẹ́ kí wọ́n yà kúrò lórí ohun tí wọ́n ń kọ́.
3 Ìwọ̀nba àlàyé ni àwọn ìwé tá a máa ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ṣe lórí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan ò bá wá tètè gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ kan tàbí tó bá ń rin kinkin mọ́ ẹ̀kọ́ èké tó gbà gbọ́, kí ló yẹ ká ṣe? Ó máa dára pé kẹ́ ẹ jọ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé wa mìíràn tó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó náà. Bí gbogbo àlàyé yìí ò bá tíì tẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rùn, ẹ fi kókó náà sílẹ̀ títí di àkókò mìíràn, kẹ́ ẹ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. (Jòh. 16:12) Bí ìmọ̀ Bíbélì tí onítọ̀hún ní bá ṣe ń pọ̀ sí i tó sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí kò lóye nígbà yẹn lè wá máa ṣe kedere sí i.
4 Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀: Bí o kò bá mọ bó o ṣe lè dáhùn ìbéèrè kan dáadáa, má ṣe sọ èrò ti ara rẹ lórí kókó náà. (2 Tím. 2:15; 1 Pét. 4:11) Ṣàlàyé pé wàá ṣèwádìí lórí kókó náà, wàá sì padà wá dá a lóhùn. O tiẹ̀ lè lo àǹfààní yẹn láti fi kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bó ṣe lè máa ṣèwádìí fúnra rẹ̀. Máa ṣe àlàyé fún un díẹ̀díẹ̀ nípa bó ṣe lè lo àwọn ohun tá a fi ń ṣèwádìí tí ètò àjọ Jèhófà pèsè. Lọ́nà yìí, yóò lè mọ bó ṣe lè máa fúnra rẹ̀ wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó bá ní.—Ìṣe 17:11.