Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 28, 2005. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ January 3 sí February 28, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ wa túbọ̀ yéni sí i? [be-YR ojú ìwé 226 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 1]
2. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ló lè nílò àlàyé síwájú sí i? [be-YR ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 1]
3. Báwo la ṣe lè ṣe iṣẹ́ tá a yàn fún wa lọ́nà táwọn tó ń tẹ́tí sí wa á fi rí ẹ̀kọ́ kọ́? [be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
4. Tá a bá fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí àwọn tó ń tẹ́tí gbọ́ wa ti mọ̀ dunjú, báwo la ṣe lè mú kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
5. Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀ tá a bá rọ àwọn olùgbọ́ wa pé kí wọ́n kíyè sí kúlẹ̀kúlẹ̀ inú ẹsẹ Bíbélì kan tí wọ́n mọ̀ dunjú? [be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn láti “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí [wọ́n] sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,” àwọn ohun wo ló yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀? (Oníw. 12:13) [be-YR ojú ìwé 272 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
7. Báwo la ṣe lè mú kí àwọn èèyàn máa ronú nípa Jèhófà fúnra rẹ̀, kí wọ́n má kàn fọkàn sí orúkọ rẹ̀ nìkan? (Jóẹ́lì 2:32) [be-YR ojú ìwé 274 ìpínrọ̀ 3 sí 5]
8. Báwo ni níní ìmọ̀ nípa Jésù àti jíjẹ́rìí rẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó? (Jòh. 17:3) [be-YR àkọlé tó wà ní ojú ìwé 275 ìpínrọ̀ 4]
9. Kí nìdí téèyàn fi gbọ́dọ̀ lóye ipa tí Jésù kó kí ó tó lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run kó sì lóye Bíbélì? [be-YR ojú ìwé 276 ìpínrọ̀ 1]
10. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la gbà pé Jésù Kristi jẹ́ Ọba? [be-YR ojú ìwé 277 ìpínrọ̀ 4]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ṣé abọ̀rìṣà ni Térà bàbá Ábúráhámù? (Jóṣ. 24:2)
12. Nígbà tí Jèhófà rán Gídíónì níṣẹ́, ṣé ẹ̀rù ń ba Gídíónì láti ṣe iṣẹ́ náà ni? Kí nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀? (Oníd. 6:25-27)
13. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Gídíónì gbà bá ẹ̀yà Éfúráímù sọ̀rọ̀? (Oníd. 8:1-3)
14. Kí ni ìwà àìláájò àlejò táwọn èèyàn Gíbíà hù fi hàn nípa irú ẹni tí wọ́n jẹ́? (Oníd. 19:14, 15)
15. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘ohun tó tọ̀nà ní ojú kálukú tó sì ti mọ́ kálukú lára láti máa ṣe ló ń ṣe,’ ǹjẹ́ èyí dá wàhálà kankan sílẹ̀? (Oníd. 21:25)