ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/05 ojú ìwé 3-6
  • Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìwé Tá A Dámọ̀ràn fún Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀
  • Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Bá Ipò Akẹ́kọ̀ọ́ Mu
  • Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Kọ́ni
  • Sísàmì sí Ìdáhùn àti Kíkọ Kókó Ọ̀rọ̀ sí Etí Ìwé
  • Yíyẹ Ibi Tí Ẹ Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Wò àti Ṣíṣe Àtúnyẹ̀wò
  • Kọ́ Ọ Lọ́nà Tí Yóò Fi Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára
  • Má Ṣe Yà Bàrá
  • Lo Òye
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
  • Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ sí Gbàdúrà
  • Àwọn Nǹkan Tẹ́ Ẹ Lè Máa Gbàdúrà Lé Lórí
  • Ìpàdé Ìjọ
  • Lo Fídíò Láti Mú Káwọn Èèyàn Mọyì Ètò Ọlọ́run
  • Fún Wọn Níṣìírí Pé Kí Wọ́n Máa Wàásù
  • Kọ́ Wọn Láti Máa Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ẹ Jọ Máa Múra Sílẹ̀
  • Ẹ Jọ Máa Wàásù
  • Kọ́ Ọ Bó Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Kó Tó Lọ Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
  • Padà Lọ Sọ́dọ̀ Ẹni Tó Fìfẹ́ Hàn Láìjáfara
  • Bá A Ṣe Ń Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni
  • Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Di Olùkọ́
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Máa Múra Sílẹ̀ Dáadáa Tó O Bá Fẹ́ Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 11/05 ojú ìwé 3-6

Tọ́jú Rẹ̀

Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú

Nínú àkìbọnú yìí la kó àwọn kókó pàtàkì pàtàkì jọ sí látinú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó dá lórí bá a ṣe lè máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò máa tẹ̀ síwájú èyí tó máa ń jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. A rọ gbogbo yín pé kẹ́ ẹ tọ́jú àkìbọnú yìí kẹ́ ẹ sì máa yẹ̀ ẹ́ wò bẹ́ ẹ bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láfikún sí i, ẹ lè máa yẹ àwọn kókó tó wà nínú àkìbọnú náà wò láwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sì lè máa mú ọ̀rọ̀ jáde láti inú rẹ̀ bí wọ́n bá ń bẹ àwọn àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wò.

Apá Kìíní: Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Bó o bá ń bá ẹnì kan fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa Bíbélì déédéé, tó ò ń lo Bíbélì pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn ìwé wa tá a dámọ̀ràn, kódà bí àkókò tó ò ń lò kò bá tiẹ̀ pọ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lò ń darí yẹn. O lè ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tó o bá ti darí rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lẹ́yìn ìgbà tó o kọ́kọ́ ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún onílé, tó o sì ti wò ó pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè máa tẹ̀ síwájú.—km-YR 7/04 ojú ìwé 1.

Àwọn Ìwé Tá A Dámọ̀ràn fún Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́

◼ Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?

◼ Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun

◼ Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà

◼ Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! O lè lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti kọ́ àwọn èèyàn tí wọn ò kàwé púpọ̀ tàbí àwọn tí kò mọ ìwé kà.

Apá Kejì: Mímúrasílẹ̀ Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́

Ó yẹ ká máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi wọ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn. Èyí gba pé ká múra sílẹ̀ dáadáa, ká sì máa ronú nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tá a bá ń múra sílẹ̀.—km-YR 8/04 ojú ìwé 1.

Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀

◼ Kọ́kọ́ wo àkọlé ẹ̀kọ́ náà, àwọn ìsọ̀rí inú rẹ̀ àti àwòrán èyíkéyìí tó bá wà níbẹ̀.

◼ Rí i pé o mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tó jẹ́ kókó pàtàkì nìkan.

◼ Pinnu èyí tó o máa kà lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí bí ìkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Kọ àwọn kókó pàtàkì inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sétí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.

◼ Múra àtúnyẹ̀wò ṣókí tó dá lórí àwọn kókó inú ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀.

Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Bá Ipò Akẹ́kọ̀ọ́ Mu

◼ Gbàdúrà sí Jèhófà nípa akẹ́kọ̀ọ́ náà àtàwọn ohun tó lè mú kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

◼ Ronú àwọn kókó tó lè ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ láti lóye tàbí láti gbà gbọ́.

◼ Máa bi ara rẹ pé: Kí ló yẹ kó mọ̀ tàbí tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lé lórí kó bàa lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Báwo ni mo ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ mi wọ̀ ọ́ lọ́kàn?

◼ Múra àkàwé kan, àlàyé kan, tàbí ọ̀wọ́ àwọn ìbéèrè sílẹ̀, èyí tó lè ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ìtumọ̀ kókó kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.

Apá Kẹta: Lílo Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Múná Dóko

Ìdí tá a fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé a fẹ́ ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ Kí wọ́n sì tó lè di ọmọ ẹ̀yìn, a ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n gbà pé òtítọ́ ni, kí wọ́n sì máa fi wọ́n sílò. (Mát. 28:19, 20; 1 Tẹs. 2:13) Nítorí náà, orí Ìwé Mímọ́ ló yẹ ká gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kà.—km-YR 11/04 ojú ìwé 4.

Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Kọ́ni

◼ Fi bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì tiẹ̀ hàn án.

◼ Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti àwọn ohun tá a gbà gbọ́ lẹ́yìn kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

◼ Máa béèrè ìbéèrè. Dípò tí wàá fi máa ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì fún akẹ́kọ̀ọ́, sọ pé kó ṣàlàyé wọn fún ọ.

◼ Jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà rọrùn. Má ṣe gbìyànjú láti ṣàlàyé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan. Kìkì ohun tí yóò bá jẹ́ kí kókó tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò ṣe kedere ni kó o sọ̀rọ̀ lé lórí.

◼ Sọ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè fi ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ sílò. Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tẹ́ ẹ̀ ń kà ṣe kan òun fúnra rẹ̀.

Apá Kẹrin: Bí A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Wa Láti Máa Múra Sílẹ̀

Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń ka ibi tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, tó ń sàmì sí ìdáhùn, tó sì mọ bí òun ṣe lè dáhùn ìbéèrè látọkànwá máa ń tètè tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan bá ti fìdí múlẹ̀, kí ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà jọ múra ẹ̀kọ́ kan sílẹ̀ láti lè kọ́ ọ ní bó ṣe lè máa múra sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ohun tó máa ṣe ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ láǹfààní jù ni pé kẹ́ ẹ jọ múra àkòrí kan sílẹ̀ látòkèdélẹ̀ nínú ìwé tẹ́ ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́.—km-YR 12/04 ojú ìwé 1.

Sísàmì sí Ìdáhùn àti Kíkọ Kókó Ọ̀rọ̀ sí Etí Ìwé

◼ Ṣàlàyé bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè mọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó dáhùn ìbéèrè inú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní tààràtà.

◼ Fi ìwé tìrẹ han akẹ́kọ̀ọ́, kó lè rí bó o ṣe sàmì sí kìkì àwọn kókó ọ̀rọ̀ àtàwọn gbólóhùn tó ṣe pàtàkì.

◼ Ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ pé ó ní kókó kan tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a kò kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú wọn sínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ń tì lẹ́yìn nínú ìpínrọ̀, kó o sì fi hàn án bó ṣe lè máa kọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ sí etí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

Yíyẹ Ibi Tí Ẹ Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Wò àti Ṣíṣe Àtúnyẹ̀wò

◼ Fi han akẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe lè wo àkòrí ẹ̀kọ́ náà, àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, àtàwọn àwòrán kó tó bẹ̀rẹ̀ sí múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

◼ Gba akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì lẹ́yìn tó bá múra sílẹ̀ tán.

Apá Karùn-ún: Bí A Ó Ṣe Mọ Ìwọ̀n Tí Òye Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Gbé

Bí òye olùkọ́ àti ti akẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe pọ̀ tó àti ipò àwọn méjèèjì ni wọn ó fi mọ ohun tí wọ́n máa kọ́ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.—km-YR 1/05 ojú ìwé 1.

Kọ́ Ọ Lọ́nà Tí Yóò Fi Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára

◼ Kò yẹ kó jẹ́ pé torí àtilè ka ojú ìwé tó pọ̀ la ò ṣe ní bìkítà nípa bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

◼ Máa lo àkókò tó pọ̀ tó kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè ní òye kó sì gba ohun tó ń kọ́ gbọ́.

◼ Ló àkókò tó pọ̀ tó láti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti àwọn kókó tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà lẹ́yìn.

Má Ṣe Yà Bàrá

◼ Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí kò sí lára ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ ló ń gbé akẹ́kọ̀ọ́ náà níkùn, ẹ lè jẹ́ kó dìgbà tẹ́ ẹ bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ ẹ tó gbé e yẹ̀ wò.

◼ Má ṣe jẹ́ kí àlàyé rẹ pọ̀ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́. Má ṣe jẹ́ kí àyàbá tàbí ìrírí pọ̀ jù kó má bàa ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì.

Apá Kẹfà: Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Kan Bá Béèrè Ìbéèrè

Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti fìdí múlẹ̀, ohun tó máa ń dára jù ni pé ká máa gbé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yẹ̀ wò lẹ́sẹẹsẹ dípò ká kàn máa mú ẹ̀kọ́ Bíbélì lórí-nídìí. Èyí á jẹ́ kí òye òtítọ́ máa yé akẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, á sì jẹ́ kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—km-YR 2/05 ojú ìwé 6.

Lo Òye

◼ A lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ ohun tá à ń kọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

◼ Ẹ lè gbé ìbéèrè tí kò bá jẹ mọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ tàbí téèyàn á ṣèwádìí kó tó lè dáhùn rẹ̀, yẹ̀ wò nígbà mìíràn. Ó sì tún dára béèyàn bá kọ irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ sílẹ̀.

◼ Bí akẹ́kọ̀ọ́ ò bá tètè gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ kan, ṣe ni kẹ́ ẹ jọ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé mìíràn tó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó náà.

◼ Bí gbogbo àlàyé yìí ò bá tẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́rùn, ẹ fi kókó náà sílẹ̀ títí di àkókò mìíràn, kẹ́ ẹ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ.

Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀

◼ Bó ò bá mọ bó o ṣe lè dáhùn ìbéèrè kan, má ṣe sọ èrò tara ẹ lórí kókó náà.

◼ Máa ṣàlàyé díẹ̀díẹ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe lè ṣe ìwádìí.

Apá Keje: Ta Ló Yẹ Kó Gbàdúrà Níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́?

Kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bàa lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ṣe pàtàkì ká máa tọrọ ìbùkún Jèhófà sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nítorí náà, ó bójú mu bá a bá ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ká máa fàdúrà bẹ̀rẹ̀ ká sì tún máa fàdúrà parí rẹ̀.—km-YR 3/05 ojú ìwé 4.

Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ sí Gbàdúrà

◼ Bá a bá rí àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè gbàdúrà nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.

◼ Àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ míì wà tó jẹ́ pé àwa gan-an la ó fi òye gbé e ká tó lè mọ ìgbà táá dáa ká bẹ̀rẹ̀ sì gbàdúrà.

◼ O lè fi Sáàmù 25:4, 5 àti 1 Jòhánù 5:14 ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ láti máa gbàdúrà.

◼ O lè fi Jòhánù 15:16 ṣàlàyé fún un pé Jèhófà ló yẹ ká máa gbàdúrà sí nípasẹ̀ Jésù Kristi.

Àwọn Nǹkan Tẹ́ Ẹ Lè Máa Gbàdúrà Lé Lórí

◼ Ó dára kéèyàn máa yin Jèhófà nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìtọ́ni ti ń wá.

◼ Máa sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà tọkàntọkàn.

◼ Máa fi ìmọrírì hàn fún ètò tí Jèhófà ń lò.

◼ Máa gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún ìsapá akẹ́kọ̀ọ́ náà kó bàa lè máa fi ohun tó ń kọ́ sílò.

Apá Kẹjọ: Bá A Ṣe Lè Máa Darí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Sínú Ètò Ọlọ́run

Kì í ṣe nítorí káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè mọ ohun tá a gbà gbọ́ nìkan la ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí kò ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn pẹ̀lú lè di ara ìjọ Kristẹni. Máa fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti fi kọ́ wọn ní ohun kan nípa ètò Jèhófà.—km-YR 4/05 ojú ìwé 8.

Ìpàdé Ìjọ

◼ Ṣàlàyé fún wọn nípa ìpàdé ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ọjọ́ tó o bá kọ́kọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni kó o ti fi ìpàdé lọ̀ wọ́n.

◼ Sọ àwọn kókó pàtàkì tó o gbọ́ rí láwọn ìpàdé fún wọn.

◼ Ṣàlàyé Ìrántí Ikú Kristi, àwọn àpéjọ àti ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká lọ́nà tí wọ́n á fi nífẹ̀ẹ́ sí i.

◼ Fi àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé wa hàn wọ́n, kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn yàwòrán bí ìpàdé wa ṣe máa ń rí.

◼ Gbà wọ́n níyànjú láti ka ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?

Lo Fídíò Láti Mú Káwọn Èèyàn Mọyì Ètò Ọlọ́run

◼ Fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name

◼ Fídíò Our Whole Association of Brothers

◼ Fídíò United by Divine Teaching

◼ Fídíò To the Ends of the Earth

Apá Kẹsàn-án: Bó O Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́ bí Àṣà

Bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n ń kọ́, àwọn náà á máa fẹ́ láti sọ fáwọn ẹlòmíràn.—km-YR 5/05 ojú ìwé 1.

Fún Wọn Níṣìírí Pé Kí Wọ́n Máa Wàásù

◼ Ṣé wọ́n láwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn míì nínú ìdílé tí wọ́n lè pè wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?

◼ Ǹjẹ́ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà, lára àwọn tí wọ́n jọ wà nílé ìwé, tàbí lára àwọn ojúlùmọ̀ wọn míì?

Kọ́ Wọn Láti Máa Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbàgbọ́ Wọn

◼ Bẹ́ ẹ bá kẹ́kọ̀ọ́ dórí àwọn kókó kan, bi akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Báwo lo ṣe máa fi Bíbélì ṣàlàyé òtítọ́ yìí fáwọn ará ilé rẹ?”

◼ Ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti lóye ìdí tó fi yẹ kó máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe.

◼ Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? láti ran àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a gbà gbọ́ kí wọ́n sì tún lóye àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni wa.

Apá Kẹwàá: Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ní Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé

Bí àwọn alàgbà bá pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti yẹ lẹ́ni tó lè di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ará lọ sóde ẹ̀rí.—km-YR 6/05 ojú ìwé 1.

Ẹ Jọ Máa Múra Sílẹ̀

◼ Jẹ́ kí akéde tuntun mọ bó ṣe lè rí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá.

◼ Yan ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn tó sì bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.

◼ Gbà á nímọ̀ràn pé kó máa lo Bíbélì tó bá ń wàásù.

◼ Ẹ jọ máa ṣe ìdánrawò. Kọ́ ọ báá ṣe máa fọgbọ́n fèsì ọ̀rọ̀ táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sábà máa ń sọ.

Ẹ Jọ Máa Wàásù

◼ Ní kí akẹ́kọ̀ọ́ máa wò ó bó o ṣe ń lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tẹ́ ẹ ti jọ múra sílẹ̀.

◼ Fi ànímọ́ àti ìṣesí akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́kàn. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ohun tó máa dáa jù ni pé kó o jẹ́ kí akéde tuntun náà ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kó sì ṣàlàyé rẹ̀.

◼ Ran akéde tuntun náà lọ́wọ́ kó lè mọ bí yóò ṣe máa jáde fún iṣẹ́ ìwàásù déédéé láìpa ọ̀sẹ̀ kankan jẹ.

Apá Kọkànlá: Bá A Ṣe Lè Kọ́ Akéde Tuntun Kó Lè Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò

Ìgbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fẹ́nì kan ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò. Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó máa fi àwọn tó ń wàásù fún sọ́kàn. Máa kọ́ ọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé bó ṣe lè mú kí wọ́n máa sọ èrò inú wọn jáde, bó ṣe lè máa fetí sílẹ̀ bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ àti bó ṣe lè máa fiyè sí ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn.—km-YR 7/05 ojú ìwé 1.

Kọ́ Ọ Bó Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Kó Tó Lọ Ṣe Ìpadàbẹ̀wò

◼ Ẹ jọ jíròrò ohun tó bá ẹni náà sọ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pàdé, kó o sì ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti múra kókó ọ̀rọ̀ tó máa fa onílé mọ́ra sílẹ̀.

◼ Ẹ jọ múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí. Kí èyí dá lórí ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú ìpínrọ̀ kan nínú ìwé kan tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.

◼ Ẹ múra ìbéèrè kan tó máa fi kádìí ìjíròrò náà.

Padà Lọ Sọ́dọ̀ Ẹni Tó Fìfẹ́ Hàn Láìjáfara

◼ Gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó máa yára ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn.

◼ Ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti rí ìdí tó fi jẹ́ pé lemọ́lemọ́ ló yẹ kó máa padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ṣòro láti bá nílé.

◼ Kọ́ akéde tuntun náà bó ṣe lè máa bá àwọn tó fìfẹ́ hàn ṣàdéhùn, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa mú àdéhùn ṣẹ.

Apá Kejìlá: Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Bẹ̀rẹ̀ sí Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa fara wé ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ káwọn èèyàn bàa lè máa rí ẹ̀kọ́ tó dáa kọ́ lá ra rẹ. Bẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ṣe ń wo bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ ọ̀hún láá máa yé e pé torí àtibẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò.—km-YR 8/05 ojú ìwé 1.

Bá A Ṣe Ń Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni

◼ Ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ pé kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan pé ká ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bá a bá ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni.

◼ Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sábà máa ń dáa jù pé ká fi ìpínrọ̀ kan tàbí méjì nínú ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàpèjúwe bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

◼ Ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀kan lára àwọn àbá nípa bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kẹ́ ẹ sì tún fi dánra wò.—km-YR 8/05 ojú ìwé 1; km-YR 1/02 ojú ìwé 6.

Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Di Olùkọ́

◼ Gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níyànjú láti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.

◼ Ṣètò pé kí àwọn akéde tuntun bá ọ lọ ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì kó o sì jẹ́ káwọn náà kópa díẹ̀ nínú kíkọ́ onítọ̀hún.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́