ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/05 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 14
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 21
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 28
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 5
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 11/05 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 14

Orin 220

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 15 àti Jí! December 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! December 8.) Ẹ lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá wúlò. Jẹ́ kí àṣefihàn kọ̀ọ̀kan fi hàn bí àwọn ará ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, bí, “Èmi ò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 9.

15 min: Àwọn Ọrẹ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí. Alàgbà kan ni kó sọ àsọyé yìí, kó sì mú un látinú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2005, ojú ìwé 26 sí 30.

20 min: “Ẹ Polongo Ògo Jèhófà.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní káwọn ará sọ ìrírí ṣókí tó fi hàn bí ìwà rere ṣe lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti jẹ́rìí.

Orin 24 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 21

Orin 40

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Bó O Ṣe Lè Fi Jèhófà Ṣe Ọlọ́run Rẹ. Alàgbà kan ni kó sọ àsọyé yìí, kó sì mú un látinú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2005 ojú ìwé 25 sí 28. Jẹ́ káwọn ará rí bí ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára Ábúráhámù Dáfídì àti Èlíjà ṣe wúlò tó.

15 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Kíkíyèsí Ohun Tó Wà Láyìíká Wọn.”b Fi àṣefihàn kan kún un nínú èyí tí akéde kan ti kíyè sí ohun tó ń jẹ ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ lógún tó sì wá mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ohun tó kíyè sí yẹn mu.

Orin 67 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 28

Orin 7

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó, kó o sì tún ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tá à ń ṣe. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù November sílẹ̀. Lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! December 8. (Lo àbá kẹrin fún Jí! December 8.) Ẹ lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá wúlò. Láfikún, mẹ́nu kan ìṣètò tó wà fún fífi ọrẹ ṣètìlẹyìn.

15 min: “Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?” Àsọyé. Mẹ́nu ba àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti dìde ìrànwọ́ nítorí àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn lákòókò tí nǹkan le koko. (Wo Jí! August 8, 2003, ojú ìwé 22 sí 27; December 8, 2002, ojú ìwé 19 sí 24; àti August 8, 2001 àpótí tó wà lójú ìwé 22 àti 23. Tàbí nínú àwọn ìwé wa mìíràn.) Lẹ́yìn náà, jíròrò àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 7 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Tẹnu mọ́ ọn fáwọn ará pé bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún ètò ìrànwọ́, á dáa jù kí irú ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé.

18 min: Bá A Ó Ṣe Máa Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀ Lóṣù December. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún, ṣàlàyé ṣókí lórí àwọn kókó tó tẹ̀lé e yìí látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 lábẹ́ àkòrí náà, “Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Lo Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tí A Dámọ̀ràn,” tó wà lójú ìwé 8: (1) Tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ ara wa ṣàlàyé rẹ̀, yóò túbọ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. (2) Ká jẹ́ olóye ká sì mọ ohun táwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa fẹ́. (3) Ó yẹ ká tún máa ronú nípa ipò àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa àti nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (4) Ká máa fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ tàbí àkòrí tá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé tá a fẹ́ fi lọni ká sì wá àwọn kókó tó lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. (5) Kì í ṣe àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn nìkan la gbọ́dọ̀ lò. Lẹ́yìn náà, jíròrò bá a ṣe lè lo àwọn kókó yẹn nígbà tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lóṣù December. A sì tún lè lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá sínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì nípa bá a ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀.

Orin 123 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 5

Orin 38

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú.”c Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a mú látinú apá kìíní àti apá kejì nínú àkìbọnú. Ẹ tún lè wo ojú ìwé 1 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 2004. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa múra sílẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n ti gbà fi àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa náà sílò. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣàlàyé lórí àpótí aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú tó wà lókè, lápá òsì lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú àkìbọnú.

20 min: “Ohun Tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Ṣe.”d Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, fi àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2004, ojú ìwé 32.

Orin 26 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́