Máa Múra Sílẹ̀ Dáadáa Tó O Bá Fẹ́ Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
1. Kí nìdí tó fi yẹ́ ká sapá láti ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọyì òtítọ́?
1 Nígbà tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa tá a bá fẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà pinnu láti sin Jèhófà. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ ọ látinú Bíbélì. Èyí á mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́ láti sin Jèhófà. (Diu. 6:5; Òwe 4:23; 1 Kọ́r. 9:26) Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe é?
2. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀?
2 Múra Sílẹ̀ Tàdúràtàdúrà: Jèhófà ló máa ń mú kí èso òtítọ́ dàgbà lọ́kàn ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, tá a bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ó yẹ ká máa dìídì gbàdúrà nípa ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti ohun tó nílò láti tẹ̀ síwájú. (1 Kọ́r. 3:6; Ják. 1:5) Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè túbọ̀ jẹ́ kó “kún fún ìmọ̀ pípéye” nípa ìfẹ́ Jèhófà.—Kól. 1:9, 10.
3. Báwo la ṣe lè ronú nípa ẹni tá a fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tá a bá ń múra sílẹ̀?
3 Mọ Ibi Tí Agbára Akẹ́kọ̀ọ́ Mọ: Jésù mọ̀ pé ká tó lè kọ́ni lọ́nà tó máa wọni lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ronú nípa àwọn tá a fẹ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Ó kéré tán, ìgbà méjì ni wọ́n bi Jésù ní ìbéèrè kan náà: Wọ́n bi í pé: “Nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Ọ̀nà tó yàtọ̀ síra ló gbà dáhùn ìbéèrè yìí nígbà méjèèjì. (Lúùkù 10:25-28; 18:18-20) Ó yẹ ká ronú lórí ohun tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa mọ̀ nígbà tá a bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀. Èwo nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ la máa kà pẹ̀lú rẹ̀? Báwo ni ibi tá a máa kà ṣe yẹ kó pọ̀ tó? Àwọn kókó wo nínú ẹ̀kọ́ yẹn ló lè ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti lóye tàbí tí ò ní fẹ́ fara mọ́? Bá a bá lè ronú ṣáájú lórí àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kó béèrè, á jẹ́ ká lè mú ìdáhùn tó máa ràn án lọ́wọ́ jáde.
4. Ká tó lè sọ pé á múra sílẹ̀ dáadáa, àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣe?
4 Múra Àpilẹ̀kọ Náà Ṣáájú: Ì báà jẹ́ pé a ti ka ìwé tá a fẹ́ fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ náà láìmọye ìgbà, síbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tá a máa fi kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́. Bá a bá fẹ́ kọ́rọ̀ wa wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń ṣe ohun tá a máa ń rọ ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ṣe. Múra ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, tó bá sì ṣeé ṣe o lè fàlà sídìí àwọn kókó tó ṣe pàtàkì.—Róòmù 2:21, 22.
5. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà?
5 Ó wu Jèhófà gan-an pé kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa tẹ̀síwájú. (2 Pét. 3:9) Bá a bá ń wáyè láti múra sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe là ń fi hàn pé ó wu àwa náà pé kí wọ́n máa tẹ̀síwájú.