Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 22
Orin 177
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 6 ìpínrọ̀ 10 sí 15, àti àpótí tó wà lójú ìwé 67
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 10-13
No. 1: Léfítíkù 11:29-45
No. 2: Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Ṣàìsàn (lr orí 23)
No. 3: Ìbùkún Táwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Tó Ti Ṣèrìbọmi Ń Gbádùn
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 7
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ran Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Máa Lo Ìfòyemọ̀. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 57, ìpínrọ̀ 3, sí ojú ìwé 58, ìpínrọ̀ 3.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! July–September. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní kí àwùjọ sọ àwọn àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi fẹ́ lò ó. Ìbéèrè wo ni wọ́n fẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ kà? Ṣàṣefihàn ọ̀nà tá a lè gbà fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Bó O Ṣe Lè Dáhùnpadà sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Ó Lè Bẹ́gidínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 10, lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ náà, ‘Mo Ní Ìsìn Tèmi.’ Ṣàṣefihàn kan tàbí méjì.
Orin 27