Títan Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Kálẹ̀
1 Jèhófà ni “Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ní ìmọ̀.” (Sm. 94:10) Ó ń lò wá láti tan ìmọ̀ tí ń gba ẹ̀mí là nípa ara rẹ̀ kálẹ̀ fún àwọn tí kò mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣiṣẹ́ sìn ín lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà. Ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, jẹ́ ìwé àtàtà tí a fi lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ èyí tí àwọn aláìlábòsí ọkàn ti lè jèrè òye pípé pérépéré nípa Ọlọ́run láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, Bíbélì. (1 Tim. 2:3, 4) Bí ìwé Ìmọ̀ ṣe ṣàlàyé òtítọ́ lọ́nà ṣíṣe kedere, tí ó sì bọ́gbọ́n mu, yóò ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Jèhófà ń gbìyànjú láti fi kọ́ wọn. Ní oṣù yìí, a fẹ́ láti mú àwọn ènìyàn wọnú ìjíròrò tí yóò mú kí wọ́n fẹ́ láti ka ìwé náà. Àwọn àbá díẹ̀ nìyí. Dípò gbígbìdánwò láti há wọn sórí, gbìyànjú láti sọ kókó inú rẹ̀ ní àwọn ọ̀rọ̀ tìrẹ àti lọ́nà tí o ń gbà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́.
2 Níwọ̀n bí púpọ̀ ènìyàn ti pàdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú, o lè mú ìrètí àjíǹde wọnú ìjíròrò rẹ nípa kíkọ́kọ́ sọ ohun kan bí èyí:
◼ “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ti pàdánù olólùfẹ́ kan nínú ikú. O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bóyá ìwọ yóò tún rí ẹni náà lẹ́ẹ̀kan sí i bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ikú kì í ṣe ara ète Ọlọ́run fún ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Jésù fẹ̀rí hàn pé a lè gba àwọn olólùfẹ́ wa là kúrò lọ́wọ́ ikú. [Ka Jòhánù 11:11, 25, 44.] Bí èyí tilẹ̀ wáyé ní àwọn ọ̀rúndún sẹ́yìn, ó ṣàṣefihàn ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí láti ṣe fún wa. [Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 85, kí o sì ka àkọlé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 86 hàn án, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀.] Bí ìwọ́ yóò bá fẹ́ láti kà sí i nípa ìrètí àjíǹde tí ń tuni nínú yìí, inú mi yóò dún láti fi ìwé yìí sílẹ̀ fún ọ fún ọrẹ ₦80.”
3 Lẹ́yìn ìjíròrò àkọ́kọ́ nípa ìrètí àjíǹde, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó tẹ̀ lé e pẹ̀lú ẹnì kan náà lọ́nà yìí:
◼ “O lè rántí pé mo sọ pé ikú kì í ṣe ara ète Ọlọ́run fún ènìyàn ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Bí ìyẹ́n bá jẹ́ òtítọ́, èé ṣe tí a fi ń darúgbó, tí a sì ń kú? Àwọn ìjàpá kan wà láàyè fún èyí tí ó ju 100 ọdún lọ, àwọn igi kan sì wà tí wọ́n ti wà láàyè fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Èé ṣe tí ènìyàn fi ń wà láàyè fún 70 ọdún tàbí 80 ọdún péré? [Jẹ́ kí ó fèsì.] A ń kú nítorí pé tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.” Ka Róòmù 5:12. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 53, kí o sì ka àkòrí orí náà. Gbé ìpínrọ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́ yẹ̀ wò, tọ́ka sí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀. Ṣàdéhùn láti padà wa lẹ́yìn náà láti jíròrò ìyókù orí náà. Fún ẹni náà níṣìírí láti parí kíkà á kí o tó padà wá.
4 Bí o bá bá ẹnì kan tí o dà bíi pé ó jẹ́ onísìn sọ̀rọ̀, o lè sọ pé:
◼ “Ní ti gidi, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó wà lónìí. Wọ́n ń kọ́ni ní onírúurú àwọn ìgbàgbọ́ tí ń forí gbárí. Àwọn ènìyàn kan sọ pé gbogbo ìsìn ni ó dára, ohun tí a sì gbà gbọ́ kò mú ìyàtọ̀ kankan wá. Kí ni èrò ọkàn rẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jésù fi ìsìn tòótọ́ kọ́ni, ó sì fi hàn pé Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba irú ìjọsìn míràn. [Ka Mátíù 7:21-23.] Bí a bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ jọ́sìn rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ̀.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 5, ka àkòrí rẹ̀, kí o sì tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀. Ṣàlàyé pé ìsọfúnni yìí yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kọ́ bí a ṣe lè mú inú Ọlọ́run dùn. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún iye tí a ń fi í síta.
5 Àwọn ènìyàn tí nǹkan tojú sú nítorí ìsìn tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ lè mọrírì ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, nígbà ìpadàbẹ̀wò rẹ:
◼ “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jaburata ìsìn yíyàtọ̀síra tí ó wà lónìí, báwo ni a ṣe lè pinnu èyí tí ó tọ̀nà? Kí ni ìwọ yóò fojú sọ́nà fún láti rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jésù sọ fún wa bí a ṣe lè dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ yàtọ̀.” Ka Jòhánù 13:35. Ṣàyẹ̀wò ìpínrọ̀ 18 àti 19 ní orí 5 ìwé Ìmọ̀. Ṣàlàyé pé nípa lílo àwọn ìlànà ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí àti ìlànà yíyọ èyí tí kò tọ̀nà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ẹnì kan lè mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀. Ròyìn bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé fún ojúlówó ìfẹ́ àti ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù gíga wọn. Ṣàlàyé bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní lílo ìwé Ìmọ̀, yóò ti fi irú ìjọsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí hàn kedere.
6 Bí o bá ṣalábàápàdé òbí kan, ìyọsíni yìí lè gbéṣẹ́:
◼ “Lójoojúmọ́, a ń gbọ́ ìròyìn nípa ìwà láìfí àwọn èwe, tí ó dà bíi pé wọ́n kò ní ìlànà ìwà rere kankan. Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ láti di ẹ̀bi náà ru ètò ilé ẹ̀kọ́ fún ṣíṣàìkọ́ àwọn ọmọ ní ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Ta ni o rò pé ó yẹ kí ó pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Fetí sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè yìí. [Ka Éfésù 6:4.] Èyí fi yé wa pé gbígbin ìtóye ìwà rere sínú ọkàn àwọn ọmọ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 145, ka ìpínrọ̀ 16, kí o sì ṣàlàyé àwọn àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 147. Ṣàlàyé pé a pète ìwé náà fún gbogbo ìdílé láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ní lílo ìpínrọ̀ 17 àti 18 ní ojú ìwé 146, yọ̀ǹda láti ṣàṣefihàn bí a ṣe ń darí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdílé.
7 Bí o bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú òbí kan tí ń ṣàníyàn nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, o lè máa bá a nìṣó nígbà ìpadàbẹ̀wò rẹ ní sísọ pé:
◼ “Ayé òde òní gbé ọ̀pọ̀ ìdẹwò ka iwájú àwọn èwe wa. Èyí mú kí ó ṣòro gan-an fún wọn láti di olùbẹ̀rù Ọlọ́run bí wọ́n ti ń dàgbà. Bóyá o lè rántí pé nínú ìjíròrò wa tí ó kẹ́yìn, a tọ́ka sí ìlànà méjì. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run, a ní láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa, a sì ní láti máa fi ìfẹ́ wa hàn sí wọn déédéé. Ohun mìíràn wà tí Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ nílò láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn.” Ka Òwe 1:8. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 148, kí o sì máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó, ní kíkárí ìpínrọ̀ 19 sí 23. Dábàá pé ìwọ yóò tún padà wá láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ìdílé náà lápapọ̀, ní bíbẹ̀rẹ̀ láti orí 1.