“Ìgbàgbọ́ Ń Tẹ̀lé Ohun Tí A Gbọ́”
1 Nígbà tí a bá rí ẹnì kan tí ó “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” ó ṣe pàtàkì láti fún ìgbàgbọ́ ẹni yẹn lókun nínú ohun tí ó ti gbọ́. (Ìṣe 13:48; Romu 10:17) Láti ṣàṣeparí ìyẹn, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ lórí gbogbo àsansílẹ̀-owó Ilé-Ìṣọ́nà àti ìwé ìròyìn tí a fi sóde, nípa pípadà lọ láti fi ìtẹ̀jáde tí ó dé kẹ́yìn lọni, kí a sì jíròrò sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ní góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun lọ́kàn. Àwọn àbá díẹ̀ nìyí tí ó lè ṣèrànwọ́:
2 Nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò níbi tí o ti jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ẹ Yin Ọba Ayérayé!,” o lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà yìí pé:
◼ “Nígbà tí a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, a ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ẹ̀rí jaburata tí ń fi hàn pé Ọlọrun alágbára ńlá gbogbo kan wà. Bí ó ti wù kí ó rí, wíwulẹ̀ mọ̀ pé ó wà kò tó. A ní láti mọ orúkọ rẹ̀. Orúkọ wo ni ìwọ́ ń pe Ọlọrun? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn wulẹ̀ ń pè é ní ‘Oluwa’ tàbí ‘Ọlọrun,’ tí ó jẹ́ orúkọ oyè tí kì í ṣe ti ara ẹni. Ní àfikún, ó fẹ́ kí á mọ òun pẹ̀lú orúkọ òun. [Ka Orin Dafidi 83:18.] Bibeli sọ púpọ̀ sí i fún wa nípa Jehofa Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ìwé yìí ti ṣàlàyé.” Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 29 nínú ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì ka ọ̀rọ̀ tí ó wà ní abẹ́ àwòrán. Lẹ́yìn tí o bá ti jíròrò ìpínrọ̀ mẹ́ta àkọ́kọ́ ní orí 3, o ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan nìyẹn!
3 Fún àwọn tí o bá ṣàyẹ̀wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ìdí Tí Ìsìn Ayé Yóò Fi Dópin,” o lè fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ tí a fi hàn nípa sísọ pé:
◼ “Lẹ́yìn kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ó ṣeé ṣe kí òkodoro òtítọ́ náà pé a kò lè fi ojú kan náà wo gbogbo ìsìn ti wú ọ lórí. Ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké ni ó wà. Èyí gbé ìbéèrè bíbọ́gbọ́n mu dìde pé, Ìjọsìn ta ni Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà? Jesu pèsè ìdáhùn náà, ìwé yìí sì tẹnu mọ́ ọn.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 5, kí o sì ka ìpínrọ̀ 4, àti Johannu 4:23, 24. Nígbà náà, béèrè pé, “Ìwọ yóò ha fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ bí?” Bí ó bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ṣí i sí orí 1, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
4 Bí a bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú “Jí!,” April 22, nígbà tí o bá padà lọ, o lè gbìyànjú ìyọsíni yìí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé “Ìmọ̀”:
◼ “O lè rántí pé a jíròrò nípa ìfojúsọ́nà tí a ní fún rírí ayé kan láìsí ogun nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó ṣòro láti wòye bí ìyẹn yóò ti rí gan-an. Àwòrán alápèjúwe rẹ̀ kan nìyí. [Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 188 àti 189 nínú ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Kì yóò ha jẹ́ ìdùnnú láti lè gbádùn àyíká wọ̀nyí? [Ṣí i sí ojú ìwé 4 àti 5, fi àwòrán náà hàn án, kí o sì ka àpótí náà.] Àkòrí ìwé yìí jọ àwọn ọ̀rọ̀ Jesu tí a rí nínú Johannu 17:3. [Kà á.] Bí o bá fẹ́, inú mi yóò dùn láti fi bí o ṣe lè lo ìwé yìí pẹ̀lú Bibeli rẹ láti rí ìmọ̀ tí ń gba ẹ̀mí là yẹn, hàn.” Bí onílé bá fẹ́, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní orí àkọ́kọ́.
5 Bí o bá kàn sí ẹnì kan tí ọwọ́ rẹ̀ dí nígbà tí o kọ́kọ́ bẹ̀ ẹ́ wò, o lè sọ èyí nígbà tí o bá padà lọ:
◼ “Mo bẹ̀ ọ́ wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo sì fún ọ ní ẹ̀da ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ń gbé ọ̀wọ̀ ró fún Bibeli àti ìtọ́sọ́nà ìwà híhù rẹ̀. Torí ti mo ronú pé ó pọn dandan fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ni mo ṣe padà wá láti fi ohun kan hàn ọ́ tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án, kí o sì tọ́ka sí àwọn àkòrí tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 3. Béèrè orí tí ó fà á mọ́ra jù lọ, ṣí i sí orí náà, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
6 Ayọ̀ wa yóò kún bí a bá lè “ṣí ilẹ̀kùn ìgbàgbọ́” tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun ‘fún awọn ẹlòmíràn.’—Ìṣe 14:27; Joh. 17:3.