ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/05 ojú ìwé 3-4
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ẹ Máa Ṣọ́nà!
  • Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Láti Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • (1) Ìbéèrè, (2) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti (3) Orí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Fífi Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà Lọni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 1/05 ojú ìwé 3-4

Tọ́jú Rẹ̀

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí

Lo àwọn àbá yìí láti fi múra àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dámọ̀ràn sílẹ̀, èyí tó o lè lò láti fi ìwé tá a máa fi lọni lóṣù kọ̀ọ̀kan lọni.

Sún Mọ́ Jèhófà

“Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ ló máa fẹ́ káwọn túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ̀ pé Ọlọ́run sọ pé ká sún mọ́ òun? [Ka Jákọ́bù 4:8.] A ṣe ìwé yìí lọ́nà tí yóò fi lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tipa kíka Bíbélì wọn sún mọ́ Ọlọ́run.” Ka ìpínrọ̀ 1 lójú ìwé 16.

“Lónìí ìwà ìrẹ́jẹ ń gbilẹ̀ kárí ayé. Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ gan-an ló rí. [Ka Oníwàásù 8:9b.] Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa wa. [Ka ìlà méjì àkọ́kọ́ nínú ìpínrọ̀ 4 lójú ìwé 119.] Àkòrí yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ìrẹ́jẹ fúngbà díẹ̀.”

Ẹ Máa Ṣọ́nà!

“Àwọn ìṣòro ńlá àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó wọ́pọ̀ lónìí ń ba àwọn èèyàn lọ́kàn jẹ́. [Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ kan tí wọ́n mọ̀ ládùúgbò yín.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nǹkan wọ̀nyí wà lára àmì tó kárí ayé tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ayé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu, bí àpẹẹrẹ, Mátíù 24:3, 7, 8; Lúùkù 21:7, 10, 11; tàbí 2 Tímótì 3: 1-5.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ ìdí to fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa kíyè sí ohun tí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí túmọ̀ sí.”

“Onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tàbí àdánù ń ba ọ̀pọ̀ èèyàn nínú jẹ́ lóde òní. Àwọn kan máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ káwọn nǹkan wọ̀nyẹn máa ṣẹlẹ̀. Bíbélì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run máa tó gba aráyé lọ́wọ́ ìjìyà. [Ka Ìṣípayá 14:6, 7.] Wo ohun tí ìdájọ́ Ọlọ́run yóò yọrí sí fún aráyé. [Ka 2 Pétérù 3:10, 13.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí túbọ̀ ṣàlàyé kókó yìí síwájú sí i.”

Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun

“Ká ní wọ́n sọ pé kó o wá máa gbé inú ibi tó lẹ́wà bí irú èyí, ṣé wàá fẹ́ gbébẹ̀? [Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 4 àti 5 hàn án, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó lè jẹ́ ká gbádùn nínú ayé kan tó rí bí èyí títí láé. [Ka Jòhánù 17:3.] Ìwé yìí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ìmọ̀ tí yóò jẹ́ kó o ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Sọ fún un pé ìpínrọ̀ márùn-ún àkọ́kọ́ nínú orí 1 lẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ tó o bá padà wá.

Ṣí ìwé yìí sí àwòrán tó wà ní ojú ìwé 188 àti 189, kí o sì bi onílé ní ìbéèrè tó wà níbẹ̀, ìyẹn ni: “O ha nírètí láti gbé nínú Párádísè, nígbà tí ìmọ̀ Ọlọ́run yóò bo ilẹ̀-ayé bí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Aísáyà 11:9.] Ìwé yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa Párádísè àti bá a ṣe lè wà níbẹ̀.” Sọ fún un pé ìpínrọ̀ 11 sí 16 nínú orí 1 lẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ tó o bá padà wá.

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

“Ǹjẹ́ o rò pé ayé á dára ju bó ṣe wà yìí lọ báwọn èèyàn bá ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣèwà hù? [Ka Mátíù 7:12a. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí olùkọ́ gíga jù lọ tó tíì gbé ayé rí kọ́ni ló wà nínú ìwé yìí.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán tó wà ní orí 17 àti ọ̀rọ̀ tá a kọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àwòrán náà.

“Ọ̀pọ̀ òbí lóde òní ń gbìyànjú láti fi àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà tó dára kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ǹjẹ́ o rò pé èyí ṣe pàtàkì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 22:6.] Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí rọ àwọn òbí láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré. A ṣe ìwé yìí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán tó wà ní orí 15 tàbí 18 àti ọ̀rọ̀ tá a kọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àwòrán náà.

“Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ya àwọn òbí lẹ́nu láti gbọ́ ìbéèrè táwọn ọmọ wọn ń béèrè. Kì í rọrùn láti dáhùn àwọn kan lára ìbéèrè wọ̀nyí, àbí ó máa ń rọrùn? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Éfésù 6:4.] Ìwé yìí lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè àwọn ọmọ wọn lóde òní.” Sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn àwòrán tó wà ní orí 11 àti 12 tàbí orí 34 sí 36 àti ọ̀rọ̀ tá a kọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn àwòrán náà.

Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀

“Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ nípa [mẹ́nu kan ìròyìn kan]. Tí jàǹbá kan bá dá ẹ̀mí àwọn èèyàn légbodò, ọ̀pọ̀ máa ń ronú nípa bí àwọn ṣe lè tu àwọn mọ̀lẹ́bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú. Kí lèrò tìẹ?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ṣí ìwé yìí sí ojú ìwé 299, kí o fi àwòrán àjíǹde tó wà níbẹ̀ hàn án. Tún sọ fún un pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ẹnu yà nígbà tí wọ́n mọ̀ pé àti olóòótọ́ àti aláìṣòótọ́ ni yóò jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. [Ka Ìṣe 24:15 bó ṣe wà ní ìpínrọ̀ 9 lójú ìwé 297, kó o sì ṣàlàyé kókó tó wà ní ìpínrọ̀ 10.] Ìwé yìí tún ṣàlàyé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan dáradára míì tí Ọlọ́run máa gbéṣe lọ́jọ́ iwájú.”

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí

“Ní àsìkò yìí nínú ọdún, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú nípa Jésù. Ṣùgbọ́n látàrí gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé báyìí, ọ̀pọ̀ lè máa ṣiyèméjì pé bóyá ni Jésù tiẹ̀ bìkítà nípa wa. Kí lo rí nípa èyí?” Jẹ́ kó fèsì. Ṣí ìwé yìí sí orí 24, kí o sì sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa ìdí tí Jésù fi wá sáyé. Lẹ́yìn náà ka Jòhánù 15:13, kí o sì tẹnu mọ́ ìfẹ́ àtọkànwá tí Jésù ní sáwọn èèyàn.

“Tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá gbọ́ orúkọ Jésù Kristi, ńṣe ni wọ́n máa ń rò pé ó jẹ́ ọmọdé jòjòló tàbí pé ó jẹ́ ọkùnrin tó ti jìyà gan-an tí ẹ̀mí rẹ̀ ò ní pẹ́ bọ́. Gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Jésù ò ju ọjọ́ ìbí àti ọjọ́ ikú rẹ̀ lọ. Wọn ò mọ̀ nípa àwọn gbankọgbì ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn arabaríbí iṣẹ́ tó gbéṣe lásìkò tó lò láyé. Gbogbo ẹni tó ti gbé orí ilẹ̀ ayé yìí ni ohun tó ṣe kàn. Ìyẹn ló fi ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ gan-an nípa àwọn ohun ribiribi tó gbéṣe nítorí wa.” Ka Jòhánù 17:3. Ṣí ìwé yìí sí ojú ìwé tí ìnàsẹ̀ ọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀, kí o wá ka ìpínrọ̀ kẹrin níbẹ̀.

Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?

“Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìnira máa bá àwọn èèyàn bó ṣe ń bá wọn lóde òní bí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Mátíù 6:10.] Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ronú lórí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́?” Ṣí ìwé náà sí ẹ̀kọ́ 6, kí o sì ka àwọn ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ yẹn. Ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ lójú ẹsẹ̀ tàbí kó o sọ fún un pé ẹ ó kà á tó o bá padà wá.

“Láìka ti ìtẹ̀síwájú tó ń dé bá ayé ọ̀làjú wa sí, àìsàn àti ikú ṣì ń fojú ẹ̀dá gbolẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jésù máa ṣe fún àwọn aláìsàn, arúgbó àtàwọn òkú?” Jẹ́ kó fèsì. Tí ẹni yẹn bá fẹ́ mọ̀, ṣí ìwé náà sí ẹ̀kọ́ 5, kí o sì ka ìbéèrè ìpínrọ̀ 5 àti 6 fún un. Ẹ ka àwọn ìpínrọ̀ yẹn tàbí kó o sọ fún un pé ẹ ó kà á tó o bá padà wá.

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà

“Ibo lo rò pé a lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ ká bàa lè rójútùú sí àwọn ìṣòro ìgbésí ayé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Róòmù 15:4.] Ṣàkíyèsí pé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìtọ́ni, ìtùnú, àti ìrètí tó lè sọ wá di alágbára ká lè rójútùú sí ìṣòro. Ìwé yìí fún wa ní àwọn àbá tó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí bí a ṣe lè jàǹfààní gan-an látinú Bíbélì kíkà.” Sọ̀rọ̀ lórí kókó mẹ́rin tó wà lójú ìwé 30.

“Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti fìgbà kan rí ronú nípa ohun tí Ìjọba ọ̀hún máa ṣe fáráyé tó bá dé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Dáníẹ́lì 2:44.] Ìwé yìí ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tó máa gbéṣe. Ó tún ṣàlàyé síwájú sí i nípa bá a ṣe lè jàǹfààní lábẹ́ ìṣàkóso òdodo rẹ̀.” Fi àwòrán tó wà ní ojú ìwé 92 àti 93 hàn án.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́