Fífi Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà Lọni
◼ “Ǹjẹ́ o rò pé ayé á dára ju bó ṣe wà yìí lọ báwọn èèyàn bá ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣèwà hù? [Ka Mátíù 7:12a. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí olùkọ́ tó ga jù lọ tó tíì gbé ayé rí kọ́ni ló wà nínú ìwé yìí.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 17.
◼ “Ọ̀pọ̀ òbí lóde òní ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà àti àṣà tó dára kọ́ àwọn ọmọ wọn. Ǹjẹ́ o rò pé èyí ṣe pàtàkì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Òwe 22:6.] Kíyè sí i pé a rọ àwọn òbí láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló. A ṣe ìwé yìí láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀.” Sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 15, 18 tàbí 32.
◼ “Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ya àwọn òbí lẹ́nu láti gbọ́ ìbéèrè tí àwọn ọmọ wọn ń béèrè. Kì í rọrùn láti dáhùn àwọn kan lára ìbéèrè wọ̀nyí, àbí ó máa ń rọrùn? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Tímótì 3:14, 15.] Ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ láti kékeré. Ìwé yìí lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti ṣe ohun kan náà fún àwọn ọmọ wọn lónìí.” Sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn àwòrán àti àkọlé tó wà ní orí 11 àti 12 tàbí orí 34 sí 36.