(1) Ìbéèrè, (2) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti (3) Orí
Ọ̀nà tó rọrùn láti lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ni pé kéèyàn (1) béèrè ìbéèrè téèyàn á fi mọ ohun tó wà lọ́kàn onílé, (2) kéèyàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó bá a mu, kó sì (3) fi orí tó jíròrò kókó tọ́rọ̀ dá lé nínú ìwé náà han ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa kíka àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ àkòrí náà. Bí onílé bá fẹ́ mọ̀ sí i, o lè fi bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án nípa lílo ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú orí náà. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tàbí nígbà ìpadàbẹ̀wò.
◼ “Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe fáwa èèyàn lásánlàsàn láti mọ Ẹlẹ́dàá wa alágbára ńlá gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe wí?” Ka Ìṣe 17:26, 27, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 1 hàn án.
◼ “Pẹ̀lú ìṣòro tó ń dojú kọ wá lónìí, ṣó o rò pé á ṣeé ṣe láti rí ìtùnú àti ìrètí tí ibi yìí ń sọ?” Ka Róòmù 15:4, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 2 hàn án.
◼ “Bó o bá lágbára àtiṣe é, ṣé wàá lè ṣe àwọn àtúnṣe wọ̀nyí?” Ka Ìṣípayá 21:4, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 3 hàn án.
◼ “Ṣó o rò pé àwọn ọmọ wa á lè rí irú ìgbádùn tí orin àtijọ́ yìí ń sọ?” Ka Sáàmù 37:10, 11, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 3 hàn án.
◼ “Ṣó o rò pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí ọ̀rọ̀ yìí á nímùúṣẹ?” Ka Aísáyà 33:24, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 3 hàn án.
◼ “Ǹjẹ́ o ti ronú rí pé bóyá àwọn òkú mọ ohun táwa alààyè ń ṣe?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 9:5, kó o sì fi orí 6 hàn án.
◼ “Ṣó o rò pé á ṣeé ṣe lọ́jọ́ kan pé ká rí àwọn èèyàn wa tó ti kú bí Jésù ṣe sọ nínú àwọn ẹsẹ yìí?” Ka Jòhánù 5:28, 29, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà fi orí 7 hàn án.
◼ “Lérò tìẹ, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run tí àdúrà tá a mọ̀ bí ẹni mowó yìí ń sọ á ṣe di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run?” Ka Mátíù 6:9, 10, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 8 hàn án.
◼ “Ṣó o gbà pé àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ là ń gbé yìí?” Ka 2 Tímótì 3:1-4, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 9 hàn án.
◼ “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tó fi dà bíi pé ṣe ni ìṣòro ẹ̀dá ń pọ̀ sí i. Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ronú pé bóyá àwọn nǹkan tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lè máa fà á?” Ka Ìṣípayá 12:9, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 10 hàn án.
◼ “Ǹjẹ́ o ti ń ronú àtirí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí èyí?” Ka Jóòbù 21:7, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 11 hàn án.
◼ “Ǹjẹ́ o rò pé fífi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò á ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gbádùn ìdílé aláyọ̀?” Ka Éfésù 5:33, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fi orí 14 hàn án.
O lè ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kan gẹ́gẹ́ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn tó o bá ti fi han onítọ̀hún bá a ṣe ń ṣe é, tó o ti darí rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì, tó o sì ti rí ẹ̀rí pé á máa tẹ̀ síwájú.