Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Lóde òní, ó jọ pé ńṣe ni àwọn ìdílé túbọ̀ ń kojú ìṣòro tó lékenkà. Kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé bá ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù yìí? [Ka Mátíù 20:28. Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ẹ̀kọ́ márùn-ún táwọn ìdílé lè rí kọ́ lára Jésù.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.
Jí! October–December
“Gbogbo wa là ń kojú àìbánilò-lọ́gbọọgba. Ojú wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀tanú? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Ìṣe 10:34,35.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á táwọn èèyàn bá ń ṣe ẹ̀tanú sí wa àti ohun tó lè mú ká jáwọ́ nínú ṣíṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn.”
Ilé Ìṣọ́ December 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tó fún wa nírètí nínú ohun tí Bíbélì sọ yìí. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 7.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé àti bó ṣe máa ṣe é.”
Jí! October–December
Ka 1 Jòhánù 4:8. Kó o wá sọ pé: “Àwọn kan gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa ń fi iná dá àwọn ẹni ibi lóró títí láé nínú hẹ́ẹ̀lì. Àmọ́, àwọn kan ronú pé èrò yìí kò bá ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí mu. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 26 hàn án.