Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Báwo lo ṣe rò pé ayé yìí máa rí bí gbogbo èèyàn bá ń ṣe ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? [Ka Mátíù 7:12. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù tó jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ Kristẹni.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.
Ji! April–June
“Ṣé ìkọ̀sílẹ̀ lọ̀rọ̀ kàn bí tọkọtaya bá ti ní ìṣòro? [Jẹ́ kó fèsì.] Nínú ìwé Málákì 2:16a, Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀. Àmọ́, bí ìṣòro àárín tọkọtaya bá kọ̀ tí kò yanjú, ṣe ló yẹ kí wọ́n bójú tó o lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. Ìwé ìròyìn yìí tú iṣu ọ̀rọ̀ yìí dé ìsàlẹ̀ ìkòkò, ó ṣàlàyé àwọn ohun tí tọkọtaya lè ṣe tí ìgbéyàwó wọn ò fi ní tú ká.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 3 sí 9 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni kì í sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Ǹjẹ́ o gbà pé ẹ̀ṣẹ̀ ti di nǹkan àtijọ́, àbí ó yẹ ká ronú nípa rẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Róòmù 5:12.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀.”
Ji! April–June
“Ṣé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa wà? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọjọ́ Ìdájọ́ ń bọ̀. [Ka Iṣe 17: 31.] Ọjọ́ Ìdájọ́ ni ìgbà tí àwọn òkú máa jíǹde tí àwọn èèyàn kárí ayé sì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn òfin òdodo Ọlọ́run, èyí yàtọ̀ sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.