Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Ó máa ń ṣòro gan-an láti ṣohun tó tọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ń fúngun mọ́ wa láti ṣohun tí kò dáa. Kí lo rò pé ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbà fún wọn? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Òwe 29:25.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ìdí márùn-ún tó fi yẹ ká bẹ̀rù ṣíṣe ohun tó máa mú Ọlọ́run bínú dípò tá a ó fi máa bẹ̀rù èèyàn.” Lo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12.
Jí! April–June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sẹ́dàá láyé. Kí lèrò tiẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwa fúnra wa lè pinnu ohun tá a fẹ́. [Ka Diutarónómì 30:19.] Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa kádàrá.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn-án.
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Mo fẹ́ kó o sọ èrò ẹ lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. [Ka Jòhánù 3:3.] Kí lo rò pé ó túmọ̀ sí láti di àtúnbí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bá a bá lóye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí dáadáa, ó máa nípa lórí ìgbésí ayé wa àti ohun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú. Ìwé ìròyìn yìí sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.”
Jí! April–June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń ṣàníyàn nípa owó, ní pàtàkì jù lọ lásìkò yìí tí ọrọ̀ ajé ti dẹnu kọlẹ̀. Ṣéwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀rọ̀ yìí. [Ka 1 Tímótì 6:8, 10.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣúnwó ná, tọ́kàn wa á sì balẹ̀.”