Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Àwọn ìwé kan sọ pé Jésù kò kú gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, wọ́n ní ó gbéyàwó àti pé ó tiẹ̀ bímọ pàápàá. Ṣé ìwọ náà ti gbọ́ bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ òótọ́ nípa èyí. [Ka Jòhánù 17:3.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká gba ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù gbọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 26 hàn án.
Ji! April–June
“Ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn láyé òde òní ló gbà pé ìkọ̀sílẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kàn tí tọkọtaya bá ní ìṣòro. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé Mátíù 19:9 jẹ́ ká mọ ìdí kan ṣoṣo tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀. Síbẹ̀, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí ìkọ̀sílẹ̀ bá wáyé, kí tọkọtaya sì tún mọ àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe tí ìgbéyàwó wọn ò fi ní tú ká.” Fi àpótí tó wà lójú ìwé 8 hàn-án.
Ilé Ìṣọ́ May 1
“Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti rò ó rí pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí bí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ṣe béèrè ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti béèrè. [Ka Sáàmù 10:1.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, ó sì tún sọ ohun tí Ọlọ́run ń ṣe láti fòpin sí i.”
Ji! April–June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìwé pàtàkì ni Bíbélì, àmọ́ wọ́n ronú pé apá tó pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ ni kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò lóde òní. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Róòmù 15:4.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tí gbogbo ìwé inú Bíbélì, títí kan Májẹ̀mú Láéláé, ṣì fi wúlò lóde òní.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.