Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 10
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 4-8
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 6:1-13
No. 2: Ǹjẹ́ A Lè Bá Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa Tí Wọ́n Ti Kú Sọ̀rọ̀? (td 24D)
No. 3: Ìdí Tí Ìwọra Fi Jẹ́ Ìbọ̀rìṣà (Éfé. 5:5)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Ṣèrànwọ́ Tó Yẹ fún Àwọn Èèyàn Lóde Ẹ̀rí. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 188, ìpínrọ̀ 4 dé ìparí ojú ìwé 189. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó ti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí látàrí bí ẹni tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe fìfẹ́ ràn án lọ́wọ́.
10 min: Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Mọ́ Tónítóní Ń Fìyìn fún Jèhófà. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run wa ti jẹ́ mímọ́, ó yẹ kí ìmọ́tótó jẹ àwa náà lógún. (Ẹ́kís. 30:17-21; 40:30-32) Bá a bá jẹ́ kí ibi ìjọsìn wa wà ní mímọ́ tónítóní, tá a sì ń tún àwọn nǹkan tó bá bà jẹ́ níbẹ̀ ṣe, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ fìyìn fún Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin tó ń bójú tó ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní kó sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa èyí. Sọ àwọn ìrírí tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò tàbí èyí tó wà nínú ìtẹ̀jáde wa nípa bí ìrísí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dára ṣe jẹ́rìí fáwọn èèyàn. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti máa kópa nínú mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà nípò tó bójú mu.
10 min: “A Ó Wàásù Ìhìn Rere Yìí!” Ìbéèrè àti ìdáhùn.