ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/10 ojú ìwé 1
  • ‘A Ó Wàásù Ìhìn Rere Yìí’!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘A Ó Wàásù Ìhìn Rere Yìí’!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Fífún Ìgbọ́kànlé Wa Nínú Òdodo Ọlọ́run Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 5/10 ojú ìwé 1

‘A Ó Wàásù Ìhìn Rere Yìí’!

1. Báwo la ṣe mọ̀ pé kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù dúró?

1 Ó dájú pé kò sóhun tó lè dá Jèhófà dúró láti má ṣe mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Aísá. 14:24) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dà bíi ohun tí kò lè ṣeé ṣe fún Gídíónì Onídàájọ́ àti ọ̀ọ́dúnrún [300] ọmọ ogun rẹ̀ láti borí àwọn ọmọ ogun Mídíánì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [135,000], Jèhófà sọ fún un pé: ‘Dájúdájú, ìwọ yóò gba Ísírẹ́lì là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ Mídíánì. Èmi kò ha rán ọ bí?’ (Oníd. 6:14) Iṣẹ́ wo ni Jèhófà ń tì lẹ́yìn lónìí? Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:14) Kò sí ẹni tó lè dá iṣẹ́ yìí dúró!

2. Kí nìdí tá a fi lè retí pé kí Jèhófà máa ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?

2 Jèhófà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan: Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú káwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ṣe àṣeyọrí lápapọ̀, àmọ́ ǹjẹ́ a lè retí pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Nígbà tí nǹkan nira fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó nímọ̀lára pé Jèhófà dìídì ti òun lẹ́yìn nípasẹ̀ Jésù, Ọmọ rẹ̀. (2 Tím. 4:17) Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa bù kún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—1 Jòh. 5:14.

3. Àwọn ipò wo ni Jèhófà ti máa ràn wá lọ́wọ́?

3 Ṣé àwọn àníyàn ìgbésí ayé máa ń tán ẹ lókun débi pé o kì í lè lo àkókò tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́? “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.” (Aísá. 40:29-31) Ṣé inúnibíni tàbí àtakò ló ń dojú kọ ọ́? “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sm. 55:22) Ǹjẹ́ o máa ń rò pé o kò tóótun nígbà míì? Jèhófà sọ pé, ‘Lọ, èmi alára yóò sì wà pẹ̀lú ẹnu rẹ.’ (Ẹ́kís. 4:11, 12) Ṣé àìlera kan ń bá ọ fínra, tí kò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́? Jèhófà mọyì ìsapá tó ò ń fi tọkàntọkàn ṣe bó ti wù kó mọ, ó sì lè mú kó méso jáde.—1 Kọ́r. 3:6, 9.

4. Ipa wo ni ìgbẹ́kẹ̀lé tá a bá ní nínú Jèhófà máa ní lórí wa?

4 Ọwọ́ Jèhófà “ni èyí tí a nà, ta sì ni ó lè dá a padà?” (Aísá. 14:27) Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà pé ó máa bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti wàásù “pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.”—Ìṣe 14:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́