Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 17
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 17
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 4 ìpínrọ̀ 19 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 45
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 9-12
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 10:1-12
No. 2: Kí Nìdí Tí Jésù Fi Gbé Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ka Ìwé Mímọ́? (Jòh. 7:16-18)
No. 3: Ǹjẹ́ Èṣù Wà Lóòótọ́? (td 10A)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ ní Àwọn Oṣù Tó Ń Bọ̀? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní ṣókí, jíròrò àwọn ohun tí à ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bó ṣe wà nínú ìwé A Ṣètò Wa, lójú ìwé 112 sí 113. Ní kí àwọn tó ti fi àkókò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n ní.
10 min: Oríṣiríṣi Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù Ìhìn Rere—Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-Bí-Àṣà. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 101, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 102, ìpínrọ̀ 2. Ní kí ẹnì kan sọ ìrírí kan tàbí méjì nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín nígbà tó ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà tàbí kó ṣe àṣefihàn bó ṣe ṣẹlẹ̀.
10 min: “Àwọn Òjíṣẹ́ Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Gbàdúrà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.