Àwọn Òjíṣẹ́ Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Gbàdúrà
1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
1 Láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ò lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Jèhófà ló ń fún wa lágbára láti fi ṣe iṣẹ́ náà. (Fílí. 4:13) Ó máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti darí wa sọ́dọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn. (Ìṣí. 14:6, 7) Àwa là ń gbin irúgbìn òtítọ́, tá a sì ń bomi rin ín, àmọ́ Jèhófà ló ń mú kó dàgbà. (1 Kọ́r. 3:6, 9) Nítorí náà, ó pọn dandan pé kí àwa òjíṣẹ́ Kristẹni gbára lé Jèhófà Baba wa ọ̀run nínú àdúrà!
2. Àwọn nǹkan wo la lè gbàdúrà fún?
2 Fún Ara Wa: Ó yẹ ká máa gbàdúrà ní gbogbo ìgbà tá a bá ń wàásù. (Éfé. 6:18) Àwọn nǹkan wo la lè gbàdúrà fún? A lè gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ ká lẹ́mìí tó dáa nípa ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, kó sì tún fún wa nígboyà. (Ìṣe 4:29) A lè bẹ Jèhófà pé kó darí wa sọ́dọ̀ àwọn tó lọ́kàn títọ́ tá a lè kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ẹni tá à ń wàásù fún bá bi wá ní ìbéèrè, a lè gbàdúrà ṣókí lọ́kàn wa, ká bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè fèsì lọ́nà tó dáa. (Neh. 2:4) A tún lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ọgbọ́n ká lè ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí pàtàkì ju àwọn nǹkan míì lọ. (Ják. 1:5) Láfikún sí i, inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Kól. 3:15.
3. Báwo ni gbígbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì ṣe lè mú kí iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú?
3 Fún Àwọn Ẹlòmíì: Ó tún yẹ ká máa ‘gbàdúrà fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,’ ká tiẹ̀ máa dárúkọ àwọn òjíṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀. (Ják. 5:16; Ìṣe 12:5) Ṣé o ní àìlera tí kò jẹ́ kó o lè ṣe púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, máa gbàdúrà fún àwọn òjíṣẹ́ tí wọ́n ní ìlera tó jí pépé. Má ṣe fojú kéré ipa tí àdúrà rẹ lè ní lórí wọn láé! Bákan náà, ó dáa tá a ń bá gbàdúrà pé kí àwọn aláṣẹ fojú rere wo iṣẹ́ ìwàásù wa, kí àwọn ará wa “lè máa bá a lọ ní gbígbé ìgbésí ayé píparọ́rọ́ àti dídákẹ́jẹ́ẹ́.”—1 Tím. 2:1, 2.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìforítì nínú àdúrà?
4 Wíwàásù ìhìn rere ní gbogbo ilẹ̀ ayé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Tá a bá “ní ìforítì nínú àdúrà,” Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe iṣẹ́ náà parí.—Róòmù 12:12.