ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bhs orí 17 ojú ìwé 174-184
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
  • Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ká à ní Bíbélì Fi Kọ́ni
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ?
  • KÍ LA GBỌ́DỌ̀ ṢE KÍ ỌLỌ́RUN LÈ GBỌ́ ÀDÚRÀ WA?
  • ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN SÁBÀ MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÀDÚRÀ
  • BÍ ỌLỌ́RUN ṢE Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA
  • Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
bhs orí 17 ojú ìwé 174-184

ORÍ KẸTÀDÍNLÓGÚN

Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́

Obìnrin kan ń gbàdúrà lálẹ́ nígbà tí ìràwọ̀ yọ lójú ọ̀run

“Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé” fẹ́ gbọ́ àdúrà wa.​—Sáàmù 115:15

1, 2. Kí nìdí tó o fi rò pé ẹ̀bùn pàtàkì ni àdúrà jẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa rẹ̀?

AYÉ kéré gan-an, tá a bá fi wé ọ̀run. Tí Jèhófà bá ń wo ayé, gbogbo àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo ayé dà bí ẹ̀kán omi kan látinú korobá. (Sáàmù 115:15; Àìsáyà 40:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kéré tá a bá fi wá wé ọ̀run, síbẹ̀ Sáàmù 145:18, 19 sọ pé: “Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́. Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní ohun tí ọkàn wọn ń fẹ́, ó ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́, ó sì ń gbà wọ́n.” Àbí ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá lèyí jẹ́! Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa tó lágbára jù lọ fẹ́ ká sún mọ́ òun, ó sì ń fẹ́ tẹ́tí sí àdúrà wa. Ká sòótọ́, àǹfààní ni àdúrà jẹ́, torí ó jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì tí Jèhófà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.

2 Àmọ́, Jèhófà máa gbọ́ àdúrà wa tá a bá bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Báwo la ṣe lè ṣe é? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ JÈHÓFÀ?

3. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa gbàdúrà sí Jèhófà?

3 Jèhófà fẹ́ kó o máa gbàdúrà, ó sì fẹ́ kó o máa bá òun sọ̀rọ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Jọ̀ọ́ ka Fílípì 4:6, 7. Ronú nípa ohun tó ní ká máa ṣe. Aláṣẹ ayé àtọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an, ó sì fẹ́ kó o máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ àti àwọn ìṣòro rẹ fún òun.

4. Báwo ni àdúrà tí ò ń gbà sí Jèhófà déédéé ṣe máa mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú rẹ̀ lágbára?

4 Àdúrà ló ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Tí àwọn ọ̀rẹ́ bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ déédéé nípa èrò wọn, àwọn àníyàn wọn àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, àjọṣe wọn á máa lágbára sí i. Bí ọ̀rọ̀ àdúrà sí Jèhófà náà ṣe rí nìyẹn. Jèhófà lo Bíbélì láti sọ èrò rẹ̀ àti bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára rẹ̀ fún ẹ, ó sì ti sọ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún ẹ. O tiẹ̀ lè sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ déédéé. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà á máa lágbára sí i.​—Jémíìsì 4:8.

KÍ LA GBỌ́DỌ̀ ṢE KÍ ỌLỌ́RUN LÈ GBỌ́ ÀDÚRÀ WA?

5. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́?

5 Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń gbọ́? Rárá o. Nígbà ayé wòlíì Àìsáyà, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Bí ẹ tiẹ̀ ń gbàdúrà púpọ̀, mi ò gbọ́ àdúrà yín, ẹ̀jẹ̀ kún ọwọ́ yín.” (Àìsáyà 1:15) Torí náà, tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa ṣe àwọn ohun tó máa mú ká jìnnà sí Jèhófà, tí kò sì ní jẹ́ kó gbọ́ àdúrà wa.

6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní ìgbàgbọ́? Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́?

6 Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Máàkù 11:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa, torí ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Hébérù 11:6) Àmọ́, ká kàn sọ pé a ní ìgbàgbọ́ nìkan kò tó. A tún ní láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà lójoojúmọ́, ìyẹn ló máa fi hàn gbangba pé a ní ìgbàgbọ́.​—Ka Jémíìsì 2:26.

7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀ hàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà? (b) Báwo la ṣe lè fi òótọ́ inú hàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà?

7 Ó yẹ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀ hàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá fẹ́ bá ọba tàbí ààrẹ orílẹ̀-èdè kan sọ̀rọ̀, a máa bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, torí náà, tá a bá ń bá a sọ̀rọ̀, ṣé kò yẹ kí ọ̀wọ̀ àti ìrẹ̀lẹ̀ tá a máa fún un pọ̀ ju ti ọba lọ? (Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Sáàmù 138:6) Ó tún yẹ ká máa fi òótọ́ inú gbàdúrà sí Jèhófà láti inú ọkàn wa, kì í ṣe ká kàn máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà lásọtúnsọ.​—Mátíù 6:7, 8.

8. Tá a bá ń gbàdúrà nípa ohun kan, kí ló tún yẹ ká ṣe?

8 Paríparí ẹ̀ ni pé tá a bá ń gbàdúrà nípa ohun kan, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tá à ń gbàdúrà nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa ní ohun tá a nílò lójoojúmọ́, kò yẹ ká ya ọ̀lẹ ká wá máa retí pé kí Jèhófà fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò, nígbà tó jẹ́ pé a lè fi ọwọ́ wa ṣiṣẹ́ láti ní ohun yẹn. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára, ká sì rí i pé a ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá lè ṣe. (Mátíù 6:11; 2 Tẹsalóníkà 3:10) Tàbí tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà tí kò dáa, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ipò èyíkéyìí tó lè jẹ́ ká hu ìwà náà. (Kólósè 3:5) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà.

ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN SÁBÀ MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÀDÚRÀ

9. Ta ló yẹ ká máa gbàdúrà sí? Ní Jòhánù 14:​6, kí la rí kọ́ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà?

9 Ta ló yẹ ká máa gbàdúrà sí? Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 6:9) Ó tún sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Tori náà, Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí nípasẹ̀ Jésù. Kí ló túmọ̀ sí láti gbàdúrà nípasẹ̀ Jésù? Kí Jèhófà tó lè gbọ́ àdúrà wa, ó yẹ ká fọ̀wọ̀ hàn fún iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà gbé lé Jésù lọ́wọ́. A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù wá sáyé láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 3:16; Róòmù 5:12) Àti pé Jèhófà ti yan Jésù láti jẹ́ Àlùfáà Àgbà àti Onídàájọ́.​—Jòhánù 5:22; Hébérù 6:20.

Àwọn èèyàn ń gbàdúrà lábẹ́ ipò tó yàtọ̀ síra

O lè gbàdúrà nígbàkigbà

10. Ṣé ó yẹ ká wà ní ipò pàtó kan tá a bá fẹ́ gbàdúrà? Ṣàlàyé.

10 Ṣó yẹ ká wà ní ipò pàtó kan tá a bá fẹ́ gbàdúrà? Rárá o, Jèhófà kò sọ pé ká kúnlẹ̀, ká jókòó, tàbí ká dúró tá a bá fẹ́ gbàdúrà. Bíbélì kọ́ wa pé a lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ní ipò ọ̀wọ̀ èyíkéyìí tá a bá wà. (1 Kíróníkà 17:16; Nehemáyà 8:6; Dáníẹ́lì 6:10; Máàkù 11:25) Ipò tá a wà nígbà tí à ń gbàdúrà kọ́ ló ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà, àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lú èrò tí ó tọ́. A lè gbàdúrà sókè tàbí ká gbàdúrà sínú níbikíbi tá a bá wà àti nígbàkigbà, bóyá lọ́sàn-án tàbí lóru. Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ọkàn wa balẹ̀ pé ó máa gbọ́, tí ẹnikẹ́ni ò bá tiẹ̀ gbọ́.​—Nehemáyà 2:1-6.

11. Àwọn nǹkan wo la lè bá Jèhófà sọ?

11 Kí la lè béèrè nínú àdúrà wa? A lè béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu nínú àdúrà wa. Bíbélì sọ pé: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.” (1 Jòhánù 5:14) Ṣé a lè gbàdúrà nípa àwọn nǹkan tara tá a nílò? Bẹ́ẹ̀ ni. Ńṣe ló yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà bí ìgbà tá à ń bá ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ sọ̀rọ̀. A lè bá Jèhófà sọ ohunkóhun tó bá wà lọ́kàn wa. (Sáàmù 62:8) A lè gbàdúrà sí i pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tí ó tọ́. (Lúùkù 11:13) A tún lè bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, ká sì tún gbàdúrà pé kó fún wa lókun láti fara da àwọn ìṣòro wa. (Jémíìsì 1:5) Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Éfésù 1:3, 7) Ó tún yẹ ká gbàdúrà fún àwọn míì, títí kan ìdílé wa àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú ìjọ.​—Ìṣe 12:5; Kólósè 4:12.

12. Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àdúrà wa?

12 Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àdúrà wa? Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀ ni. Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ látọkàn wá nítorí gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa. (1 Kíróníkà 29:10-13) Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, nígbà tí Jésù wà láyé, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. (Ka Mátíù 6:9-13.) Ó sọ pé ohun tó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ gbàdúrà nípa rẹ̀ ni pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n kà á sí ohun ọ̀wọ̀ tàbí ohun mímọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ pé ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé àti pé kí gbogbo ayé máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn tí Jésù ti béèrè àwọn nǹkan pàtàkì yẹn nínú àdúrà rẹ̀ tán, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká gbàdúrà nípa àwọn nǹkan tá a nílò. Tá a bá ń fi Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ nínú àwọn àdúrà wa, ńṣe là ń fi hàn pé ohun tó ṣe pàtàkì sí wa nìyẹn.

13. Báwo ló ṣe yẹ kí àdúrà wa gùn tó?

13 Báwo ló ṣe yẹ kí àdúrà wa gùn tó? Bíbélì kò sọ. Bí ipò nǹkan bá ṣe rí ló máa pinnu bóyá àdúrà wa máa kúrú tàbí ó máa gùn. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ jẹun a lè gbàdúrà tó kúrú, àmọ́ a lè gbàdúrà tó gùn nígbà tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tàbí tá a bá ń sọ àwọn àníyàn wa fún un. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 15) Kò yẹ ká máa gbàdúrà tó gùn torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn máa yìn wá, bí àwọn èèyàn kan ṣe ṣe nígbà ayé Jésù. (Lúùkù 20:46, 47) Jèhófà kò ka irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ sí. Ohun tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ni pé ká gbàdúrà látọkàn wá.

14. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà tó? Kí ni èyí sì kọ́ wa nípa Jèhófà?

14 Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà tó? Jèhófà sọ pé ká máa bá òun sọ̀rọ̀ déédéé. Bíbélì sọ pé ká máa “gbàdúrà nígbà gbogbo,” ká sì “máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà.” (Mátíù 26:41; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17) Jèhófà ṣe tán láti gbọ́ wa nígbà gbogbo. Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoójúmọ́ nítorí ìfẹ́ àti ìwà ọ̀làwọ́ tó fi hàn sí wa. A tùn le béèrè pé kó tọ́ wa sọ́nà, kó fún wa lókun kó sì tù wá nínú. Tá a bá mọyì ànfààní tá a ní láti gbàdúrà sí Jèhófà lóòótọ́, a ó máa bá a sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo.

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe “àmín” ní ìparí àdúrà?

15 Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe “àmín” ní ìparí àdúrà? Ọ̀rọ̀ náà, “àmín” túmọ̀ sí “ó dájú” tàbí “bẹ́ẹ̀ ni kó rí.” Ó jẹ́ ọ̀nà kan láti fi hàn pé ohun tá a sọ nínú àdúrà wa ti ọkàn wa wá àti pé òótọ́ inú la fi sọ ọ́. (Sáàmù 41:13) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká ṣe “àmín” bóyá sínú tàbí síta ní ìparí àdúrà tí ẹnì kan bá gbà láwùjọ, láti fi hàn pé àwa náà fara mọ́ ohun tẹ́ni náà sọ.​—1 Kíróníkà 16:36; 1 Kọ́ríńtì 14:16.

BÍ ỌLỌ́RUN ṢE Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA

16. Ṣé Jèhófà máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa lóòótọ́? Ṣàlàyé.

16 Ṣé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì pè é ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà tí àìmọye àwọn èèyàn ń fòótọ́ inú gbà, ó sì máa ń dáhùn wọn, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà.

17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà láyé láti dáhùn àdúrà wa?

17 Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì àtàwọn ìráńṣẹ rẹ̀ tó wà láyé láti dáhùn àwọn àdúrà wa. (Hébérù 1:13, 14) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn ló wà tí wọ́n gbàdúrà kí wọ́n lè rí ìrànlọ́wọ́ láti lóye Bíbélì, tí àwọn Ẹ̀lẹ́rìí Jèhófà sì lọ sọ́dọ̀ wọn láìpẹ́ sígbà tí wọ́n gbàdúrà náà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì náà ń kéde “ìhìn rere” kárí ayé. (Ka Ìfihàn 14:6.) Bákan náà, ọ̀pọ̀ lára wa ló ti gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn ìṣòro pàtó kan tàbí nípa àwọn ohun kan tá a nílò, tá a sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ arákùnrin tàbí arábìnrin wa.​—Òwe 12:25; Jémíìsì 2:16.

Tọkọtaya Kristẹni kan ń ran ọ̀rẹ́ wọn àgbàlagbà tó jẹ́ aláìlera lọ́wọ́

Jèhófà lè dáhùn àdúrà wa nípasẹ̀ irànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni

18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti Bíbélì láti dáhùn àdúrà wa?

18 Jèhófà máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dáhùn àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro kan, ó lè lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti tọ́ wa sọ́nà àti láti fún wa lókun. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Jèhófà tún máa ń lo Bíbélì láti dáhùn àdúrà wa, ó sì máa ń fi ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Tá a bá ka Bíbélì, a máa rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó máa ràn wá lọ́wọ́. Jèhófà tún lè mú kí ẹnì kan tó dáhùn nípàdé sọ ohun tá a nílò lásìkò yẹn tàbí kó mú kí alàgbà kan sọ ohun kan nínú Bíbélì fún wa.​—Gálátíà 6:1.

19. Kí nìdí tó fi máa ń dà bíi pé Jèhófà ò dáhùn àdúrà wa?

19 Nígbà míì, a lè máa rò ó pé, ‘Kí ló dé tí Jèhófà ò tíì dáhùn àdúrà mi?’ Rántí pé, ó mọ ìgbà tó yẹ kí òun dáhùn àdúrà wa àti bó ṣe yẹ kí òun dáhùn rẹ̀. Ó mọ ohun tá a nílò. Ó lè gba pé ká máa gbàdúrà nìṣó láti fi hàn pé ohun tí à ń sọ jẹ wá lọ́kàn, ká sì lè fi hàn pé lóòótọ́ la nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Lúùkù 11:5-10) Nígbà míì, Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá ò retí. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà nípa àwọn ipò kan tó le, àmọ́ dípò kí Jèhófà mú ìṣòro yẹn kúrò, ó lè fún wa ní agbára láti fara dà á.​—Ka Fílípì 4:13.

20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé?

20 Ẹ wo àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tá a ní láti máa gbàdúrà sí Jèhófà! Ó dá wa lójú pé ó máa gbọ́ wa. (Sáàmù 145:18) Bá a bá ṣe ń gbàdúrà sí Jèhófà látọkàn wá tó, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á máa lágbára sí i.

KÓKÓ PÀTÀKÌ

ÒTÍTỌ́ 1: JÈHÓFÀ FẸ́ KÁ MÁA GBÀDÚRÀ SÍ ÒUN

“Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.”​—Sáàmù 145:18

Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa?

  • Hébérù 11:6

    A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́.

  • Sáàmù 138:6

    A gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀ hàn.

  • Jémíìsì 2:26

    Ìwà wa ní láti bá àdúrà wa mu.

  • Mátíù 6:7, 8

    A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, kí àdúrà wa sì tọkàn wá. Kò yẹ ká máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan náà lásọtúnsọ nínú àwọn àdúrà wa.

  • Àìsáyà 1:15

    Ìgbésí ayé wa gbọ́dọ̀ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

ÒTÍTỌ́ 2: ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPÀ ÀDÚRÀ

  • Tá ló yẹ ká máa gbàdúrà sí?

    Mátíù 6:9; Jòhánù 14:6

  • Ṣó yẹ ká wà ní ipò kan pàtó nígbà tá a bá fẹ́ gbàdúrà?

    1 Kíróníkà 17:16; Nehemáyà 8:5, 6; Dáníẹ́lì 6:10; Máàkù 11:25

  • Ṣé Jèhófà máa ń gbọ́ àwọn àdúrà tá a bá gbà sínú?

    Nehemáyà 2:1-6

  • Báwo ló ṣe yẹ kí àdúrà wa gùn tó?

    1 Sámúẹ́lì 1:12, 15; Lúùkù 20:46, 47

  • Báwo ló ṣe yẹ kí á máa gbàdúrà tó?

    Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17

  • Kí nìdí tá a fi ń ṣe “àmín” ní ìparí àdúrà?

    1 Kíróníkà 16:36; 1 Kọ́ríńtì 14:16

ÒTÍTỌ́ 3: OHUN TÁ A LÈ BÉÈRÈ NÍNÚ ÀDÚRÀ WA

“Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”​—1 Jòhánù 5:14

Àwọn nǹkan wo la lè béèrè nínú àdúrà wa?

  • Mátíù 6:9, 10

    Gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.

  • 1 Kíróníkà 29:10-13

    Máa dúpẹ́ nínú àdúrà rẹ.

  • Mátíù 6:11-13

    Gbàdúrà pé kó o ní àwọn nǹkan tó o nílò àtàwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn.

  • Lúùkù 11:13

    Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́.

  • Jémíìsì 1:5

    Gbàdúrà pé kó o ní ọgbọ́n láti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa.

  • Fílípì 4:13

    Gbàdúrà pé kó o ní okun láti fara da ìṣòro.

  • Éfésù 1:3, 7

    Gbàdúrà pé kó o rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.

  • Ìṣe 12:5

    Gbàdúrà fún àwọn ẹlòmíì.

ÒTÍTỌ́ 4: JÈHÓFÀ Ń DÁHÙN ÀDÚRÀ WA

“Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, ọ̀dọ̀ rẹ ni onírúurú èèyàn yóò wá.”​—Sáàmù 65:2

Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáhùn àwọn àdúrà wa?

  • Òwe 12:25; Ìfihàn 14:6

    Jèhófà lè lo àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn èèyàn láti ràn wá lọ́wọ́.

  • 2 Kọ́ríńtì 4:7

    Ó ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.

  • Fílípì 4:6, 7, 13

    Ó máa ń fún wa ní àlàáfíà àti okun tá a nílò láti fara da ìṣòro.

  • Gálátíà 6:1; 2 Tímótì 3:16, 17

    Ó máa ń fún wa ní ọgbọ́n nípasẹ̀ Bíbélì àti ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́