ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/15 ojú ìwé 15-20
  • Fífún Ìgbọ́kànlé Wa Nínú Òdodo Ọlọ́run Lókun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífún Ìgbọ́kànlé Wa Nínú Òdodo Ọlọ́run Lókun
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Bá Nímọ̀lára Pé A Ti Jìyà Láìnídìí
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Jónà
  • Àkókò Láti fún Ìgbọ́kànlé Wa Lókun Rèé!
  • Ìdájọ́ Jèhófà Yóò Jẹ́ Òdodo
  • Jèhófà Ni Ó Yẹ Kí A gbọ́kàn Lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • A Lè Padà Ní Ìgbọ́kànlé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/15 ojú ìwé 15-20

Fífún Ìgbọ́kànlé Wa Nínú Òdodo Ọlọ́run Lókun

“Kí ìgbọ́kànlé rẹ lè wá wà nínú Jèhófà ni mo ṣe fún ọ ní ìmọ̀.”—ÒWE 22:19.

1, 2. (a) Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fi ìgbọ́kànlé hàn nínú Jèhófà? (Òwe 22:19) (b) Kí ní fi hàn pé àwọn kan ní láti fún ìgbọ́kànlé wọn nínú Jèhófà lókun?

A FI ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀ jíǹkí àwọn Kristẹni tòótọ́. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń fi ìfẹ́ pèsè “oúnjẹ” tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45) Ìmọ̀ tí wọ́n ń jèrè ń fún wọn ní ìpìlẹ̀ lílágbára tí wọ́n lè gbé ìgbọ́kànlé wọn nínú Ọlọ́run kà. Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìgbọ́kànlé àrà ọ̀tọ̀ hàn nínú Jèhófà àti òdodo rẹ̀.

2 Ṣùgbọ́n, ó dà bí pé gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí kan lè ní láti fún irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ lókun. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, Society máa ń rí àwọn lẹ́tà gbà, tí ń fi iyèméjì hàn nípa àlàyé tí ó ti ṣe nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀. Iyèméjì yìí lè jẹ́ ìhùwàpadà sí àtúnṣe lórí òye kan, tàbí kí ó jẹ́ lórí àwọn ọ̀ràn tí ó kan olùbéèrè náà gbọ̀ngbọ̀n, ní pàtàkì ní ti ìmọ̀lára.—Fi wé Jòhánù 6:60, 61.

3. Kí ní lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ pàápàá, èé sì ti ṣe?

3 Àní àwọn ìránṣẹ́ tòótọ́ ti Jèhófà pàápàá ń rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ Oníwàásù 9:11, tí ó sọ pé: “Mo padà láti rí i lábẹ́ oòrùn pé eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Báwo ni èyí ṣe lè jẹ́ òótọ́ lọ́nà gbígbòòrò, tàbí nípa tẹ̀mí? A ti lè mọ àwọn Kristẹni kan tí wọ́n tètè máa ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, tí wọ́n jẹ́ alágbára ní gbígbèjà òtítọ́, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní lílo àwọn ìlànà Bíbélì, tí wọ́n sì jẹ́ onítara ní lílépa ìmọ̀ pípéye. Síbẹ̀, nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” ìjàǹbá tàbí ọjọ́ ogbó lè mú kí àwọn kan wá rí i nísinsìnyí pé ìwọ̀nba ni ohun tí àwọn lè ṣe. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí kọminú pé bóyá ni àwọn kò ti ní kú kí ayé tuntun Ọlọ́run tó dé.

4, 5. Èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan fún àwọn Kristẹni láti pàdánù ìgbọ́kànlé wọn nínú òdodo Jèhófà?

4 Nígbà tí Kristẹni kan bá pàdánù ọkọ tàbí aya rẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn àti òfò náà máa ń ga púpọ̀. Gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, wọ́n ti lè jùmọ̀ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún tàbí ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún pàápàá. Ẹnì kejì tí ó wà láàyè mọ̀ pé ikú ti já ìdè ìgbéyàwó náà.a (1 Kọ́ríńtì 7:39) Wàyí o, kí ìgbọ́kànlé rẹ̀ má bàá di èyí tí a jìn lẹ́sẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ̀.—Fi wé Máàkù 16:8.

5 Ẹ wo bí ó ti bọ́gbọ́n mu tó láti wo ikú ọkọ tàbí aya ẹni, òbí ẹni, ọmọ ẹni, tàbí ọ̀rẹ́ ẹni tímọ́tímọ́ tí ó jẹ́ Kristẹni gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti fi ìgbọ́kànlé nínú òdodo Jèhófà hàn! Àní nígbà tí a bá pàdánù ẹnì kan, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà kì í ṣe aláìṣòdodo. A lè ní ìgbọ́kànlé pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá jèrè ìyè àìnípẹ̀kun—yálà nípasẹ̀ lílà á já tàbí àjíǹde—yóò láyọ̀. Onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn. Olódodo ni Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀. Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́. Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.”—Sáàmù 145:16-19.

Bí A Bá Nímọ̀lára Pé A Ti Jìyà Láìnídìí

6, 7. (a) Èé ṣe tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jìyà nígbà kan rí ṣe lè wá ní òye tí ó yàtọ̀ nísinsìnyí? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a ka Jèhófà sí aláìṣòdodo fún yíyọ̀ǹda kí irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ wá nígbà yẹn?

6 Ní àkókò kan sẹ́yìn, Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ti jìyà nítorí tí wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí ẹ̀rí-ọkàn wọn kò gbà láyè. Bí àpẹẹrẹ, èyí ti lè jẹ́ nípa irú iṣẹ́ àṣesìnlú tí wọ́n yàn ní àwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Nísinsìnyí, arákùnrin kan lè wá ronú pé ẹ̀rí-ọkàn òun gba òun láyè láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ láìré ìlànà àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni kọjá ní ti ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí.

7 Ṣé àìṣòdodo ni ó jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà fún jíjẹ́ kí ó jìyà nítorí kíkọ̀ láti ṣe ohun tí ì bá ti ṣe, ká ní nísinsìnyí ni, tí ohunkóhun kò sì ní tẹ̀yìn rẹ̀ yọ? Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀ kò ní ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú wọn dùn pé àwọn láǹfààní láti fi hàn ní gbangba àti lọ́nà tí ó ṣe kedere pé, àwọn pinnu láti dúró gbọn-in lórí ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ àgbáyé. (Fi wé Jóòbù 27:5.) Ìdí wo ni ẹnì kan lè ní fún kíkábàámọ̀ lẹ́yìn tí ó ti tẹ̀ lé ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ ní dídúró gbọn-in fún Jèhófà? Nípa fífi ìdúróṣinṣin gbé ìlànà Kristẹni lárugẹ bí wọn ṣe lóye rẹ̀ sí tàbí dídáhùnpadà sí ìsúnniṣe ẹ̀rí-ọkàn, wọ́n fi hàn pé àwọn yẹ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Dájúdájú, ó bọ́gbọ́n mu láti yẹra fún ipa ọ̀nà tí ó lè kó ìdààmú bá ẹ̀rí-ọkàn ẹni tàbí tí ó lè mú kí a mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. A lè ronú nípa èyí ní ti àpẹẹrẹ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 8:12, 13; 10:31-33.

8. Èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan fún àwọn Kristẹni tí í ṣe Júù, tí wọ́n dìrọ̀ mọ́ Òfin tẹ́lẹ̀, láti ṣiyèméjì nípa òdodo Jèhófà?

8 Láti lè wu Jèhófà, a béèrè pé kí àwọn Júù pa Òfin Mẹ́wàá àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àfikún òfin 600 mìíràn mọ́. Lẹ́yìn náà, lábẹ́ ìṣètò Kristẹni, ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin wọ̀nyí kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun àbéèrèfún mọ́ láti sin Jèhófà, àní a kò tilẹ̀ béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Júù nípa ti ara pàápàá. Lára àwọn òfin tí wọn kò sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́ ni àwọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìdádọ̀dọ́, pípa Sábáàtì mọ́, fífi ẹran rúbọ, àti pípa àwọn òfin kan tí ó jẹ mọ́ ti oúnjẹ mọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:19; 10:25; Kólósè 2:16, 17; Hébérù 10:1, 11-14) Àwọn Júù—títí kan àwọn àpọ́sítélì—tí wọ́n di Kristẹni ni a tú sílẹ̀ nínú ojúṣe ti pípa àwọn òfin tí a béèrè pé kí wọ́n ṣègbọràn sí mọ́ nígbà tí wọ́n ṣì wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. Wọ́n ha ṣàròyé pé ètò tí Ọlọ́run ṣe kò tọ́ nítorí tí ó mú kí wọ́n kọ́kọ́ máa ṣe àwọn ohun tí kò pọndandan? Rárá o, inú wọn dùn fún òye gbígbòòrò tí wọ́n ní nípa ète Jèhófà.—Ìṣe 16:4, 5.

9. Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí kan, ṣùgbọ́n èé ṣe tí kò fi sí ìdí kankan fún wọn láti kábàámọ̀?

9 Lóde òní, Àwọn Ẹlẹ́rìí kan wà tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí, ọwọ́ líle dan-in dan-in ni wọ́n fi mú ojú ìwòye tiwọn nípa ohun tí wọn yóò ṣe tàbí tí wọn kò ní ṣe. Nítorí èyí wọ́n jìyà ju àwọn mìíràn lọ. Lẹ́yìn náà, ìmọ̀ púpọ̀ sí i ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ojú ìwòye wọn gbòòrò sí i nípa àwọn nǹkan. Ṣùgbọ́n kò sí ìdí kankan fún wọn láti kábàámọ̀ lórí híhùwà nígbà yẹn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí-ọkàn wọn, àní nígbà tí ó tilẹ̀ ti lè ṣeé ṣe kí èyí mú ìjìyà lọ́wọ́. Ní tòótọ́, ó yẹ kí a gbóríyìn fún wọn pé wọ́n fi ìmúratán wọn hàn láti jìyà nítorí ìṣòtítọ́ sí Jèhófà, láti “ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere.” Jèhófà ń bù kún irú fífọkànsìn ín lọ́nà bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 9:23; Hébérù 6:10) Àpọ́sítélì Pétérù fi ìjìnlẹ̀ òye kọ̀wé pé: “Bí ẹ bá fara dà á nígbà tí ẹ bá ń ṣe rere, tí ẹ sì ń jìyà, èyí jẹ́ ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Pétérù 2:20.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Lára Jónà

10, 11. Báwo ni Jónà ṣe fi àìnígbọkànlé hàn nínú Jèhófà (a) nígbà tí a ní kí ó lọ sí Nínéfè? (b) nígbà tí Ọlọ́run kò pa àwọn ará Nínéfè run?

10 Nígbà tí a pàṣẹ fún Jónà láti lọ sí Nínéfè, kò mọrírì ìgbọ́kànlé tí Jèhófà ní nínú rẹ̀. Lẹ́yìn tí ojú Jónà ti rí màbo nítorí tí ó lọ́ tìkọ̀ láti ṣègbọràn, orí rẹ̀ wálé, ó rí àṣìṣe ara rẹ̀, ó gba iṣẹ́ tí a yàn fún un nílẹ̀ òkèèrè, ó sì kìlọ̀ fún àwọn ará Nínéfè nípa ìparun tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Lẹ́yìn èyí ni ohun àìròtẹ́lẹ̀ ṣẹlẹ̀: Nítorí ẹ̀mí ìrònúpìwàdà tí àwọn ará Nínéfè ní, Jèhófà pinnu láti má ṣe pa wọ́n run.—Jónà 1:1–3:10.

11 Báwo ni Jónà ṣe hùwà padà? Ó fapá jánú, ó ṣàròyé sí Ọlọ́run nínú àdúrà. Lájorí ẹ̀hónú rẹ̀ ni pé: ‘Mo mọ̀ pé bí ọ̀ràn náà yóò ṣe rí rèé. Ìdí tí n kò fi fẹ́ wá sí Nínéfè tẹ́lẹ̀ gan-an nìyẹn. Wàyí o, lẹ́yìn gbogbo ìsásókè-sásódò mi, títí kan ìpayà ẹja ńlá tí ó gbé mi mì àti ìtìjú tí ó kó bá mi, àti lẹ́yìn òpò tí mo ṣe láti kìlọ̀ fún àwọn ará Nínéfè nípa ìparun tí ó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, àbọ̀ gbogbo rẹ̀ rèé! Gbogbo iṣẹ́ àti làálàá mi já sásán! Ikú mà kúkú yá jẹ̀sín lọ o!’—Jónà 4:1-3.

12. Kí ni a rí kọ́ nínú ìrírí Jónà?

12 Jónà ha ní ìdí tí ó múná dóko láti ṣàròyé bí? Jèhófà ha jẹ́ aláìṣòdodo láti nawọ́ àánú sí àwọn oníwà àìtọ́ tí wọ́n ronú pìwà dà bí? Dájúdájú, ṣe ni ó yẹ kí inú Jónà dùn; ẹgbẹẹgbàárùn-ún ènìyàn mà ni ikú gbígbóná yóò yẹ̀ lórí wọn! (Jónà 4:11) Ṣùgbọ́n ẹ̀mí àìlọ́wọ̀ rẹ̀ àti àròyé tí ó ń ṣe fi hàn pé kò fi ìgbọ́kànlé jíjinlẹ̀ hàn nínú òdodo Jèhófà. Tara rẹ̀ nìkan ló ń rò ṣáá, kò ro tàwọn ẹlòmíràn. Ẹ jẹ́ kí a kẹ́kọ̀ọ́ lára Jónà nípa ṣíṣàì ka ara wa àti ìmọ̀lára tiwa sí pàtàkì jù. Ẹ jẹ́ kí ó dá wa lójú pé ṣíṣègbọràn sí Jèhófà, títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà tí ètò àjọ rẹ̀ fi lélẹ̀ àti títẹ́wọ́gba ìpinnu rẹ̀, ni ohun tó tọ́ láti ṣe. Ó dá wa lójú gbangba gbàǹgbà pé “yóò dára fún àwọn tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.”—Oníwàásù 8:12.

Àkókò Láti fún Ìgbọ́kànlé Wa Lókun Rèé!

13. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè fún ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà lókun?

13 Fífún ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà lókun jẹ́ ipa ọ̀nà ọgbọ́n. (Òwe 3:5-8) Àmọ́ ṣá o, kì í kàn ṣe pé kí a gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú rẹ̀. Ìmọ̀ pípéye ní ń mú kí ìgbọ́kànlé dàgbà, nítorí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kíka Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ń ṣàlàyé Bíbélì, jẹ́ apá kan ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ṣe kókó, bẹ́ẹ̀ náà sì ni mímúra sílẹ̀ dáadáa àti kíkópa nínú rẹ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Sísọ ọ́ dàṣà láti ṣàjọpín àwọn òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, fífi ọgbọ́n inú borí àwọn àtakò, tún ń mú kí ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jinlẹ̀ sí i. A ń tipa báyìí túbọ̀ di ojúlùmọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́.

14. Láìpẹ́, èé ṣe tí a óò fi pe àwọn ènìyàn Ọlọ́run láti fi ìgbọ́kànlé hàn nínú Jèhófà ju ti ìgbàkígbà rí lọ?

14 Ó kù fẹ́ẹ́rẹ́ báyìí, tí àkókò ìpọ́njú bíburú jù lọ tí ó tí ì dé bá ìran ènìyàn yóò dé lójijì. (Mátíù 24:21) Nígbà tí gudugbẹ̀ náà bá já, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò ní láti fi ìgbọ́kànlé hàn nínú òdodo Jèhófà àti nínú ìtọ́sọ́nà tí ètò àjọ rẹ̀ ń pèsè, ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, nígbà náà, wọn yóò fi ìgbọ́kànlé ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” (Aísáyà 26:20) Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n ti wọnú àyíká aláàbò ti àwọn ìjọ tí ó lé ní 85,000 ní ilẹ̀ 232. Ohun yòówù tí àṣẹ náà láti “wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún” lè ní nínú, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe é.

15. Báwo ni a ti ṣe tẹnu mọ́ ọ̀ràn ìgbọ́kànlé ní ọdún 1998, èé sì ti ṣe tí ó fi tọ́ bẹ́ẹ̀?

15 Ó ṣe pàtàkì pé kí a fún ìgbọ́kànlé wa lókun nísinsìnyí. Bí a kò bá ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn Kristẹni arákùnrin wa, nínú ètò àjọ Jèhófà àti, ju gbogbo rẹ̀ lọ, nínú Jèhófà fúnra rẹ̀, lílàájá wa kò ní ṣeé ṣe. Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti ṣe wẹ́kú tó pé ní ọdún 1998, a ti rán Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé létí ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún náà léraléra pé, “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là”! (Róòmù 10:13) Ìgbọ́kànlé yẹn ni ó yẹ kí a ní. Bí a bá fura pé iyèméjì díẹ̀ kíún wà nínú ìgbọ́kànlé yìí, ó yẹ kí a ṣaápọn láti ṣàtúnṣe rẹ̀ nísinsìnyí, àní, lónìí olónìí.

Ìdájọ́ Jèhófà Yóò Jẹ́ Òdodo

16. Kí ni ó lè ṣẹlẹ̀ sí ìgbọ́kànlé bí a kò bá mú un dàgbà, báwo sì ni a ṣe lè dènà kí èyí má ṣẹlẹ̀?

16 Nínú Hébérù 3:14, a kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Àwa di alábàápín nínú Kristi ní ti gidi kìkì bí a bá di ìgbọ́kànlé tí a ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.” Títí dé àyè kan, ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kan àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé. Ìgbọ́kànlé àkọ́kọ́ lè yìnrìn bí a kò bá mú un dàgbà. Ẹ wo bí ó ti ṣe kókó tó pé kí a máa lépa ìmọ̀ pípéye, kí a lè tipa bẹ́ẹ̀ fún ìpìlẹ̀ tí a gbé ìgbọ́kànlé wa kà lókun!

17. Èé ṣe tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé pé ní ti lílàájá, Jésù yóò ṣèdájọ́ lọ́nà tí ó tọ́?

17 Láìpẹ́, gbogbo orílẹ̀-èdè ni Kristi yóò yẹ̀ wò kí ó bàa lè “ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.” (Mátíù 25:31-33) A lè ní ìgbọ́kànlé pé Kristi yóò ṣe òdodo nínú ṣíṣèdájọ́ àwọn tí ó yẹ láti là á já. Jèhófà ti fún un ní ọgbọ́n, ìjìnlẹ̀ òye, àti àwọn ànímọ́ pípọndandan mìíràn “láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo.” (Ìṣe 17:30, 31) Ẹ jẹ́ kí ìdánilójú wa rí bíi ti Ábúráhámù, tí ó wí pé: “Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ [Jèhófà] pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí láti fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú tí ó fi jẹ́ pé ó ní láti ṣẹlẹ̀ sí olódodo bí ó ti ń rí fún ẹni burúkú! Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ. Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 18:25.

18. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a ṣàníyàn ju nípa ohun tí a lè má mọ̀ nísinsìnyí?

18 Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún nínú òdodo Jèhófà, a kò ní láti ṣàníyàn nípa rírí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bí: ‘Báwo ni a óò ṣe ṣèdájọ́ àwọn ọmọ ọwọ́ àti ọmọ kéékèèké? Ó ha lè jẹ́ pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ni ìhìn rere náà kò tí ì ní dé ọ̀dọ̀ wọn nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá dé bí? Àwọn alárùn ọpọlọ ńkọ́? Àwọn . . . ńkọ́?’ Lóòótọ́, a lè má mọ bí Jèhófà yóò ṣe yanjú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n, yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí yóò fi òdodo àti àánú hàn. A kò gbọ́dọ̀ ṣiyèméjì rárá nípa ìyẹn. Ní ti gidi, ó lè yà wá lẹ́nu, kí ó sì mú inú wa dùn láti rí i tí ó ń yanjú wọn lọ́nà tí a kò ronú kàn rí. Fi wé—Jóòbù 42:3; Sáàmù 78:11-16; 136:4-9; Mátíù 15:31; Lúùkù 2:47.

19, 20. (a) Èé ṣe tí kò fi lòdì láti béèrè ìbéèrè tí ó bọ́gbọ́n mu? (b) Nígbà wo ni Jèhófà yóò pèsè ìdáhùn?

19 Ètò àjọ Jèhófà kò ní kí a má béèrè ìbéèrè àtọkànwá, tó bá àkókò mu, gẹ́gẹ́ bí àwọn alátakò kan ti fàṣìṣe sọ. (1 Pétérù 1:10-12) Ṣùgbọ́n, Bíbélì rọ̀ wá láti yẹra fún ìbéèrè òmùgọ̀, tí a gbé karí ìméfò. (Títù 3:9) Bíbéèrè àwọn ìbéèrè tí ó mọ́gbọ́n dání àti yíyẹ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni wò láti rí ìdáhùn tí a gbé ka Ìwé Mímọ́ lè mú kí ìmọ̀ pípéye wa pọ̀ sí i, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ fún ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà lókun. Àpẹẹrẹ Jésù ni ètò àjọ náà ń tẹ̀ lé. Ó ń yẹra fún dídáhùn àwọn ìbéèrè tí àkókò àtidáhùn wọn kò tí ì tó. Ó ṣàlàyé pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòhánù 16:12) Ó tún gbà pé àwọn nǹkan kan wà tí òun alára kò mọ̀ ní àkókò yẹn.—Mátíù 24:36.

20 Jèhófà ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí yóò ṣí payá. Ẹ wo bí ó ti bọ́gbọ́n mu tó láti dúró dè é, kí a ní ìgbọ́kànlé pé yóò ṣí àwọn ète rẹ̀ payá ní àkókò yíyẹ gan-an. A lè ní ìgbọ́kànlé pé gbàrà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, a óò ní ayọ̀ níní ìjìnlẹ̀ òye sí i nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, a óò san èrè fún wa, bí a bá fi ìgbọ́kànlé pátápátá hàn nínú Jèhófà àti ètò àjọ tí ó ń lò. Òwe 14:26 mú un dá wa lójú pé: “Inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà, ibi ìsádi yóò sì wá wà fún àwọn ọmọ rẹ̀.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ile-Iṣọ Na, February 1, 1969, ojú ìwé 94; June 1, 1987, ojú ìwé 30.

Kí Lèrò Rẹ?

◻ Èé ṣe tí kò fi lọ́gbọ́n nínú láti jẹ́ kí ìmọ̀lára jin ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà lẹ́sẹ̀?

◻ Kí ni a lè rí kọ́ nínú ìrírí Jónà?

◻ Èé ṣe tí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti wíwá sí ìpàdé fi ṣe pàtàkì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àní nígbà tí a bá pàdánù ẹnì kan pàápàá, a lè ní ìgbọ́kànlé pé olódodo ni Jèhófà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ṣé ó dá ọ lójú pé Jèhófà ni ó gbọ́kàn lé?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́