ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 8/15 ojú ìwé 21-24
  • Gbígbé Ìtòsí Òkè Ayọnáyèéfín Kan àti Wíwàásù Níbẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbé Ìtòsí Òkè Ayọnáyèéfín Kan àti Wíwàásù Níbẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ewu Òkè Ayọnáyèéfín Náà
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Bá Iṣẹ́ Lọ
  • Báwo Ni O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀?
  • Ìkìlọ̀ Ńlá
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 8/15 ojú ìwé 21-24

Gbígbé Ìtòsí Òkè Ayọnáyèéfín Kan àti Wíwàásù Níbẹ̀

“ÓBANI lẹ́rù gidigidi. Àfi bí òpin ayé tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ gẹ́lẹ́. A gbọ́dọ̀ wà lójúfò, kí a sì mú ìdúró rere níwájú Jèhófà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.” Víctor, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn nígbà tí ó ń sọ ìrírí tí ó ní lásìkò tí ó ń gbé ìtòsí òkè ayọnáyèéfín Popocatépetl, tí a sábà máa ń pè ní Popo, ní Mexico.

Láti 1994 ni a ti ń gbọ́ ìròyìn nípa òkè ayọnáyèéfín tí ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ yìí káàkiri àgbáyé.a Àwọn aláṣẹ sọ pé gbogbo nǹkan tí ó bá wà ní 30 kìlómítà sí ẹnu òkè náà wà ní àgbègbè eléwu ńlá. Ìhà gúúsù òkè ayọnáyèéfín náà léwu gan-an nítorí apá ibẹ̀ ni òkè náà kọ ẹnu sí, àwọn àfonífojì tóóró jíjinlẹ̀, tí ẹ̀gbẹ́ wọn dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀, tí àpáta yíyòrò àti ẹrẹ̀ lè gbà jáde láti inú ihò ara òkè náà sì wà níbẹ̀.

Bí ó ṣe sábà máa ń rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ṣe kàyéfì nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Ìlú Ńlá Mexico bí òkè ayọnáyèéfín náà bá bú lọ́nà lílágbára. Ìlú ńlá náà ha wà nínú ewu bí? Gbogbo ènìyàn ìpínlẹ̀ Morelos tún wà ní ìhà gúúsù òkè ayọnáyèéfín náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè yẹn pẹ̀lú ha wà nínú ewu bí? Báwo sì ni ìgbésí ayé ṣe rí nítòsí òkè ayọnáyèéfín náà, láìmọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́kọ́jọ́?

Ewu Òkè Ayọnáyèéfín Náà

Àáríngbùngbùn Ìlú Ńlá Mexico wà ní nǹkan bí 70 kìlómítà sí àríwá ìwọ̀ oòrùn Popocatépetl, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbèríko kan kò ju nǹkan bí 40 kìlómítà lọ síbẹ̀. Lójú ìwòye ohun tí òfin là sílẹ̀, gbogbo àgbègbè ìlú náà, tí àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ 20 mílíọ̀nù, kò sí ní àgbègbè tí ó léwu. Àmọ́, tí a bá fi ojú ti ibi tí afẹ́fẹ́ darí sí wò ó, bí eérú tí ó pọ̀ bá tú jáde láti inú òkè ayọnáyèéfín náà, ó lè dé àgbègbè yìí.

Ìjàǹbá tí eérú tí ń tú jáde nínú òkè ayọnáyèéfín náà ń ṣe fún àwọn tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn rẹ̀ máa ń burú jáì. Ìlú ńlá Puebla àti àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké, tí nǹkan bí 200,000 ènìyàn, tí ń gbé àyíká ibi tí ó léwu gan-an, ń gbé, ló wà ní àgbègbè yìí. Ní Sunday, May 11, 1997, òkè ayọnáyèéfín náà tú ọ̀pọ̀ eérú dà sínú afẹ́fẹ́, ó sì fọ́n ọn ká gbogbo àgbègbè náà, ó sì dé ìpínlẹ̀ Veracruz, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn rẹ̀ tí ó ju 300 kìlómítà lọ sí i. Àwọn ìlú ńlá àti ìlú mélòó kan, tí àpapọ̀ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 40,000 tí àwọn pẹ̀lú lè wà nínú ewu ńlá, wà ní ìhà gúúsù òkè ayọnáyèéfín náà, ní ìpínlẹ̀ Morelos.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé gbogbo ibi tí a ń sọ wọ̀nyí, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àwọn tí wọ́n wà ní Ìlú Ńlá Mexico lé ní 90,000, wọ́n sì wà ní nǹkan bí 1,700 ìjọ. Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Watch Tower Society wà lẹ́yìn odi Ìlú Ńlá Mexico ní ìhà àríwá ìlà oòrùn, tí ó wà ní nǹkan bí 100 kìlómítà sí òkè ayọnáyèéfín náà. Ó lé ní 800 olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn ní ẹ̀ka náà, yàtọ̀ sí àwọn 500 olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń ṣiṣẹ́ níbi ilé ńlá kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́. Kò sí èyí tí ó wà ní àgbègbè tí ó léwu náà nínú wọn.

Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí 50 ni ó wà ní ìpínlẹ̀ Morelos, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ sì lé ní 2,000. Díẹ̀ lára àwọn ìjọ wọ̀nyí, tí wọ́n wà ní Tetela del Volcán àti Hueyapan, kò ju nǹkan bí 20 kìlómítà lọ sí ihò ara òkè náà. Ní àfikún, àwọn ìjọ tí wọ́n ní nǹkan bí 600 akéde, tí wọ́n ń gbé ibi tí ó tó 20 sí 30 kìlómítà sí òkè ayọnáyèéfín náà, wà ní ìhà ìlà oòrùn rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Puebla. Ó dájú pé ẹ̀mí àwọn wọ̀nyí lè wà nínú ewu ńlá.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ń Bá Iṣẹ́ Lọ

Lójú ewu tí kò dáwọ́ dúró náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn ní àgbègbè náà. Bákan náà, wọn kò pa àwọn ìpàdé Kristẹni tí wọ́n ti ṣètò jẹ, èyí tí ń mú kí wọ́n ní ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti ìgbọ́kànlé lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé wọ̀nyí. (Hébérù 10:24, 25) Ìròyìn tí ọ̀kan lára àwọn ìjọ ọ̀ún kọ sọ pé: “Ìyípadà pàtàkì kan ti wà nínú ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn sí ìhìn rere Ìjọba náà. Fún àpẹẹrẹ, ní abúlé kékeré kan, ènìyàn 18 ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ìjọ mìíràn, tí ó wà ní 20 kìlómítà sí òkè ayọnáyèéfín náà, ròyìn pé: “Ìbísí náà ti pọ̀ gan-an. A dá ìjọ yìí sílẹ̀ ní November 1996. Láàárín oṣù mẹ́fà tí ó tẹ̀ lé e, àwọn 10 tóótun láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Àwọn akéde kan tilẹ̀ ń gbé nǹkan bí 20 kìlómítà péré sí ibi ihò ara òkè ayọnáyèéfín náà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni, ènìyàn bí 40 sì ń wá sípàdé.”

Magdalena, tí ń gbé San Agustín Ixtahuixtla, Puebla, tí ó wà ní kìlómítà 25 péré sí òkè ayọnáyèéfín náà, ń jára mọ́ iṣẹ́ dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìbúgbàù líléwu kan.

“Wọ́n sọ fún wa pé kí a fi ilé wa sílẹ̀, a sì ṣe bẹ́ẹ̀—nígbà tí eérú ń tú jáde. Lójú bí ipò nǹkan ti jẹ́ kánjúkánjú tó, mo ronú nípa ìdílé Dorado tí mo ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi àti àwọn arákùnrin kan lọ sílé ìdílé Dorado láti kó wọn lọ sí ibi tí kò séwu. Ní ìlú ńlá Puebla tí ó wà nítòsí, ìgbìmọ̀ olùpèsè ìrànwọ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹwu. Ọ̀nà tí wọ́n gbà bá gbogbo wa lò níbẹ̀ wú ìdílé Dorado lórí gan-an. Wọ́n fi wá wọ̀ sí àwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn Kristẹni ará wa ti ṣètò sílẹ̀ fún wa. A kò lálàṣí ohunkóhun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí a wà jìnnà sí ilé wa. Ìdílé yìí ti wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Ọlọ́run nígbà bíi mélòó kan, àmọ́ ẹnu yà wọ́n nítorí ìfẹ́ tí àwọn ará tí wọn kò bá pàdé rí fi hàn sí wọn. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí a padà sí ilé wa, ìdílé yìí bẹ̀rẹ̀ sí wá sí gbogbo ìpàdé déédéé. Kò pẹ́ tí wọ́n tóótun bí akéde ìhìn rere náà. Méjì lára wọn ti ṣèrìbọmi báyìí. Wọ́n ti sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù bíi mélòó kan, wọ́n sì ń ṣètò láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé.”

Martha, ọmọdébìnrin ẹni 20 ọdún kan, tí ń gbé ibi tí ó wà ní kìlómítà 21 sí ibi ihò ara òkè náà, kò jẹ́ kí àbùkù ara dí òun lọ́wọ́ láti lo gbogbo àǹfààní tí ó ní láti wàásù. Ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nígbà tí òkè ayọnáyèéfín náà tún bẹ̀rẹ̀ sí rú. Dípò kí ó máa lo àga arọ, tí yóò ṣòro láti yí ní ilẹ̀ dídàgẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí ó ń gbé, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó ń gùn lọ wàásù. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ni ó máa ń gun lọ sí ìpàdé. Martha dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà gidigidi fún wíwà lára ẹgbẹ́ àwọn ará tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, nítorí pé àwọn arábìnrin ni wọ́n ń gbé e gun orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọ́n sì ń gbé e sọ̀ kalẹ̀. Ó máa ń lò ju wákàtí 15 lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù.

Ní àwọn àgbègbè àdádó wọ̀nyí, àwọn alámùúlégbè Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń yọ wọ́n lẹ́nu láti wá bá wọn ṣe àwọn ọdún onísìn tí wọ́n máa ń ṣe. Ní Tulcingo, abúlé kan tí ó wà ní 20 kìlómítà sí òkè ayọnáyèéfín náà, wọ́n yan ọkùnrin kan pé kí ó lọ gba owó ọdún tí wọ́n máa ń dá lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí. Àwọn ará fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí wọn kò fi lè bá wọn ṣe àwọn ọdún onísìn náà. Ọkùnrin náà tẹra mọ́ gbígbìyànjú láti gba owó náà lọ́wọ́ àwọn ará gan-an débi tí ó bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ wọn, tí ó sì wá mọ díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ó gbádùn rírí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ nínú Bíbélì Kátólíìkì rẹ̀. Òun àti ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ ti ń lọ sí ìpàdé déédéé fún ọdún kan, ó sì ti sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti di akéde ìhìn rere náà jáde.

Báwo Ni O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀?

Àwọn onímọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín ṣe ìwádìí tiwọn, wọ́n sì gbé ìròyìn àfàṣẹsí jáde nípa Popocatépetl eléwu náà, àmọ́ kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tàbí ìgbà tí yóò ṣẹlẹ̀ gan-an. Bí àwọn oníròyìn àti àwọn tí ń gbé ìtòsí rẹ̀ ti sọ, òkè ayọnáyèéfín náà lè bú nígbàkigbà. Ewu náà kì í ṣe ọ̀rọ̀ yẹ̀yẹ́. Lóòótọ́, àwọn aláṣẹ ń dààmú gan-an, wọ́n sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti gbára dì sílẹ̀ de ìṣòro tí ó lè ṣẹlẹ̀. Àmọ́, a gbọ́ ti pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nípa gbígbé ìkìlọ̀ jáde, nítorí pé wọn kò ní fẹ́ kí àwọn ènìyàn púpọ̀ rẹpẹtẹ kúrò níbẹ̀ bí ewu kò bá rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Nígbà náà, kí ló yẹ kí a ṣe?

Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Nítorí náà, ohun tí ó bọ́gbọ́n mu ni pé, nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣì ṣí sílẹ̀, kí a gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ láti rí i pé a kò kó sínú ewu, kí a máà ‘dágunlá’ bí pé ohunkóhun kò ní ṣẹlẹ̀ láé, kí a mọ̀ọ́mọ̀ máa dúró de ìgbà tí òkè náà yóò bú kí a tó gbé ìgbésẹ̀. Ojú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ní àgbègbè náà fi ń wo ọ̀ràn náà nìyí.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society bá àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tí wọ́n máa ń kàn sí àwọn ìjọ tí wọ́n wà ní àgbègbè eléwu náà ní ìpínlẹ̀ Puebla dáadáa, ṣèpàdé. Wọ́n ṣètò kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ìpèsè ìrànwọ́ náà lọ bẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìdílé tí ń gbé ibi tí ó wà ní kìlómítà 25 sí ẹnu òkè náà wò. Wọ́n ran àwọn ìdílé wọ̀nyí lọ́wọ́ láti ronú nípa kíkó kúrò ní àgbègbè eléwu náà kí ó tó bú. Wọ́n ṣètò ohun ìrìnnà àti ibùgbé kí wọ́n bàa lè kó àwọn 1,500 ènìyàn kúrò níbẹ̀ lọ sí ìlú ńlá Puebla. Àwọn ìdílé kan kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn ní àwọn ìlú ńlá mìíràn.

Ìkìlọ̀ Ńlá

Èéfín, iná, àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀ Popocatépetl yìí jẹ́ àmì tí ó ṣe kedere pé yóò bú láìpẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti là á já gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àwọn ìkìlọ̀ tí àwọn aláṣẹ ń ṣe, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ní ìtòsí òkè ayọnáyèéfín náà ń wà lójúfò nígbà gbogbo láti rí i dájú pé àwọn wà láìséwu, kí àwọn sì tún ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti rí ewu náà, kí wọ́n sì wá nǹkan ṣe sí i kí ó tó pẹ́ jù.

Lọ́nà gbígbòòrò, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún wà lójúfò sí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àṣọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ogun, ìsẹ̀lẹ̀, ìyàn, àrùn, àti ìwà ọ̀daràn jẹ́ àmì tí kò ṣeé dágunlá sí bí rírú òkè ayọnáyèéfín kan ṣe jẹ́. Wọ́n jẹ́ ara àmì alápá púpọ̀ tí Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò jẹ́ àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí òpin yóò dé pàtó, kò sí iyè méjì nípa dídé rẹ̀ àti pé ó ti sún mọ́lé gan-an.—Mátíù 24:3, 7-14, 32-39.

Ohun tí ó jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn ènìyàn lónìí ni pé kí àwọn ènìyàn níbi gbogbo fọwọ́ gidi mú ìkìlọ̀ Jésù náà pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn.” (Lúùkù 21:34) Ó ṣe kedere pé, ọ̀nà tí ó bọ́gbọ́n mu láti tọ̀ nìyí. Bí a kò ti gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn àmì ìkìlọ̀ tí a ń rí lára òkè ayọnáyèéfín náà ni a kò gbọ́dọ̀ kọtí ikún sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọmọ ènìyàn, Jésù Kristi, fi ń gbà wá níyànjú pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:44.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé ìròyìn Jí!, ti March 8, 1997, sọ nípa òkè ayọnáyèéfín eléwu yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Martha (lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́) àti àwọn mìíràn ń wàásù nítòsí Popocatépetl

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́