Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ June 1
“Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan náà làwọn tó ń ṣe oríṣiríṣi ẹ̀sìn láyé ń jọ́sìn. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [Ka Jóṣúà 24:15.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fúnra wa ṣàyẹ̀wò bóyá ẹ̀sìn tá à ń ṣe lè ṣamọ̀nà wa sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn án.
Jí! July–September
“Ó ṣeé ṣe kó ti máa ta sí ẹ̀yin náà létí pé awuyewuye pọ̀ gan-an lórí oyún ṣíṣẹ́. Ṣó o rò pé Bíbélì lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti pinnu ohun tó yẹ kó ṣe? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 2 Tímótì 3:16, 17.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí.”
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní Bíbélì, àmọ́ tí ohun tó wà níbẹ̀ ò yé wọn. Ṣó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Òǹṣèwé Bíbélì fẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ká sì jàǹfààní látinú kíkà á. [Ka Sáàmù 119:130.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye Bíbélì.”
Jí! July–September
“Àwọn olórí ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé Ọlọ́run máa sọ àwọn tó bá ṣohun tó tọ́ lójú rẹ̀ di ọlọ́rọ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn èèyàn rere tí wọn kì í ṣe ọlọ́rọ̀. Ṣé o rò pé Ọlọ́run fẹ́ ká dọlọ́rọ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Hébérù 13:5.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà bù kún wa.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.