Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ July 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kí ọkàn èèyàn balẹ̀ nínú ayé oníwàhálà tá à ń gbé yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí Bíbélì sọ nínú Fílípì 4:6, 7. [Kà á.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè ní àlàáfíà tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Jí! July–September
“Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa la máa ń mọyì ohun táwọn òbí wa fi kọ́ wa. Àmọ́, ṣó o rò pé ìwà ọ̀yájú ló jẹ́ bá a bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn tá a bá lọ́wọ́ àwọn òbí wa fi kọ́ wa? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 1 Jòhánù 4:1.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ bóyá ó tọ́ ká yí ẹ̀sìn wa pa dà tàbí kò dáa bẹ́ẹ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ August 1
“Àwọn kan máa ń sọ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo là ń sìn, ẹ̀sìn ló yàtọ̀ síra wọn. Ṣéwọ náà rò pé a lè fi ẹ̀sìn wé onírúurú ọ̀nà tèèyàn lè gbà dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Mátíù 7:13, 14.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan mẹ́ta tí Bíbélì sọ pé ẹ̀sìn tó bá dáa gbọ́dọ̀ máa fi kọ́ni.”
Jí! July–September
“Kò sẹ́ni téèyàn rẹ̀ ò ṣaláìsí rí. Ṣó wá yẹ ká máa bẹ̀rù pé àwọn kan lára àwọn èèyàn wa tó ti kú lè bínú sí wa, kí wọ́n sì fẹ́ láti pa wá lára? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 9:5, 6.] Àpilẹ̀kọ yìí máa tù ẹ́ nínú gan-an.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 hàn án.