Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìtàn àròsọ lásán ni ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Ádámù àti Éfà. Àwọn míì sì gbà pé Ádámù àti Éfà gbé ayé lóòótọ́. Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ nípa wọn. [Ka Máàkù 10:6-9.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó lè mú ká gbà gbọ́ pé wọ́n gbé ayé lóòótọ́, ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbà bẹ́ẹ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 12 hàn án.
Jí! July–September
“Awuyewuye pọ̀ gan-an lórí ọ̀rọ̀ ìṣẹ́yún. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Wọ́n ti mú káwọn kan gbà pé béèyàn bá ṣẹ́yún, fọ́nrán iṣan lásán ni wọ́n wulẹ̀ fọ̀ dà nù lára ẹni náà. Àmọ́, ìyẹn ò lè rí bẹ́ẹ̀ lójú ìwòye ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka Jóòbù 3:3.] Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé, ìgbà tí wọ́n bá ti lóyún ọmọ kan ni ìwàláàyè ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.”
Ilé Ìṣọ́ October 1
“Gbogbo wa la ní ibi tí bàtà ti ń ta wá lẹ́sẹ̀. [Mẹ́nu kan díẹ̀ lára ìṣòro tó ń bá àwọn èèyàn fínra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.] Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run lè bá wa kásẹ̀ àwọn ìṣòro yìí nílẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Nínú ẹsẹ yìí, Jésù sọ ọ̀nà kan tí Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́. [Ka Lúùkù 11:13.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́, ó sì sọ bó ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.”
Jí! July–September
“Wákàtí kan náà ni gbogbo ẹ̀dá ń lò lójúmọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ṣó o mọ ohun tó fà á táwọn kan fi ń ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún yìí ju àwọn míì lọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó máa dùn mọ́ ẹ láti mọ̀ pé Bíbélì sọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà lo àkókò wa. [Ka Òwe 21:5.] Àpilẹ̀kọ yìí pèsè ìrànlọ́wọ́ gbígbéṣẹ́ tá á jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè jàǹfààní látinú fífọgbọ́n lo àkókò rẹ.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 29 hàn án.