Ṣọ́ra fún “Àwọn Èké Arákùnrin”
1. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa “àwọn èké arákùnrin”?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé bí òun ṣe ń sáré ìje òun gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí òun dojú kọ ni ewu “àwọn èké arákùnrin” tí wọ́n yọ́ wọnú ìjọ. Ó sọ pé wọ́n á ‘pá kọ́lọ́ wọlé wá,’ báwọn ará ò bá sì ṣọ́ra, wọ́n á pa wọ́n lára. (2 Kọ́r. 11:26; Gál. 2:4) Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀ ti kó ìdààmú àti àìbalẹ̀ ọkàn bá Pọ́ọ̀lù.
2. Kí la ti kíyè sí pé ó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí?
2 Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, a ti ráwọn kan tí wọ́n ṣe bíi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn, tí wọ́n sì ṣèpalára fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan. Irú àwọn èké arákùnrin bẹ́ẹ̀ lè ṣe bí ẹni tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí tó wá nílò ìrànlọ́wọ́, tàbí kí wọ́n ṣe bí ẹni pé ara wọn ò yá, wọ́n wá ń wá ẹni tó máa gbé wọn lọ sílé ìwòsàn. Àwọn míì tiẹ̀ lè fi okòwò tó máa mówó gọbọi wọlé lọ̀ wá. Nígbà míì, àwọn tó ń purọ́ pé Ẹlẹ́rìí làwọn lè sọ pé ẹnì kan wà nínú ìṣòro, ó sì nílò owó, wọ́n á sì (lo lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu láti) sọ nọ́ńbà àkáǹtì tí wọ́n fẹ́ kéèyàn lọ sanwó náà sí ní báńkì.
3. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá à ń gbé yìí, ǹjẹ́ ó yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sáwọn Kristẹni bíi tiwa dín kù? Ṣàlàyé.
3 Bá a ti ń rìn jìnnà wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí, ńṣe ló yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sí àwọn Kristẹni bíi tiwa “máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú.” (Fílí. 1:9) Bákan náà, àwọn ènìyàn burúkú àtàwọn afàwọ̀rajà á máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù. (2 Tím. 3:13) Torí náà, báwo la ṣe lè máa kíyè sára síbẹ̀ ká má pa ojúṣe Kristẹni wa tì láti máa ṣàánú àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ pé òótọ́ ni nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn?—Mát. 10:16, 17; Ják. 2:15, 16.
4. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ra? (b) Báwo la ṣe lè fi ìlànà inú Jóòbù 34:3 sílò?
4 Ó Yẹ Ká Kíyè Sára: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ ká máa fura lọ́nà òdì, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ká máa ṣọ́ra, kó má di pé a ó máa “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀,” tá a ó sì wá kó sọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn. (Òwe 14:15) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dábàá pé ká máa dán ohun táwọn èèyàn ń sọ wò, dípò ká máa tẹ́wọ́ gba gbogbo ohun tí etí wá bá ṣáà ti gbọ́. Ó sọ pé: “Etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò, gan-an gẹ́gẹ́ bí òkè ẹnu ti máa ń tọ́ nǹkan wò nígbà jíjẹun.” (Jóòbù 34:3) Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣebí a máa ń tọ́ oúnjẹ wò ká tó gbé e mì, ǹjẹ́ kò wá yẹ ká máa dán ọ̀rọ̀ àti ìṣesí àwọn èèyàn wò ká tó gbà wọ́n gbọ́?
5. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká bàa lè mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni ẹnì kan jẹ́ ojúlówó Ẹlẹ́rìí?
5 Bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ẹnì kan jẹ́ ojúlówó Kristẹni, kò ní bínú tá a bá bi í láwọn ìbéèrè kan ká bàa lè mọ irú ẹni tó jẹ́ tàbí ká lè mọ̀ bóyá ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbára lé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú.” (1 Tẹs. 5:21) Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò fún “wádìí” yìí fún yíyẹ irin wò bóyá ó jẹ́ ojúlówó. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká wádìí ẹnì kan wò bóyá lóòótọ́ ló jẹ́ Kristẹni, kí ẹlẹ̀tàn èèyàn kan má bàa tú wa jẹ.
6. (a) Báwo la ṣe lè wà déédéé bá a ṣe ń fi inú rere hàn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ran àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́?
6 Bá a bá ń ran àwọn ojúlówó Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́, ìyẹn á máa fi hàn pé lóòótọ́ la jẹ́ ‘ọ̀rẹ́ kan tó fà mọ́ wọn tímọ́tímọ́ ju arákùnrin lọ.’ (Òwe 18:24) Àwọn náà ò sì ní sá fún wa nígbà tá a bá nílò ìrànlọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí Lúùkù 6:38 ṣe sọ, ‘òṣùwọ̀n tá a bá fi díwọ̀n fún wọn, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún wa.’ Bá a ṣe ń fi inú rere tó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa hàn, ká má ṣe gbàgbé láti máa wà lójúfò nígbà gbogbo.—Ják. 1:27.