Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Lóṣù February ọdún 2009, a fún àwọn akéde níṣìírí láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April ọdún 2009. Àròpọ̀ iye àwọn akéde tó ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìlélógún [13,622]. Iye yìí fi ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé márùndínláàádọ́rùn-ún [2,885] ju iye àwọn tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní oṣù April ọdún tó kọjá lọ.