ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/09 ojú ìwé 8
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 9/09 ojú ìwé 8

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé tá a máa lò ní September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ká sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá fún ẹnì kan ní ìwé yìí. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè jàǹfààní látinú ìwé náà nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án ní ṣókí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Ẹ fún ẹni tó bá fìfẹ́ hàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Bó bá ti ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kẹ́ ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé ògbólógbòó èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Báwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.

◼ Ọ̀sẹ̀ April 12, 2010 la máa sọ àkànṣe àsọyé tó wà fún sáà Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2010. A máa ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà tó bá yá. Káwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé náà lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àsọyé yìí ṣáájú ọ̀sẹ̀ April 12.

◼ Àwọn Àwo Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Tuntun Tó Wà:

A Satisfying Life—How to Attain It (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Ìwé Ìtàn Bíbélì (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú (MP3) —Gẹ̀ẹ́sì

◼ Ọ̀wọ́ àwọn Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” ti ọdún 2009, tó máa wáyé ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà la tò sísàlẹ̀ yìí: November 27-29, 2009, BENIN CITY 7 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà Nìkan); December 11-13, 2009, Ọ̀TÀ 12 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà Nìkan); January 8-10, 2010, ÙLÌ 14 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà Nìkan). Pẹ̀lú ìṣètò yìí, a ò ní túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà ní àwọn Àpéjọ Àgbègbè tá a máa ṣe ní Ọ̀TÀ 11 (December 4-6, 2009), ÙLÌ 12 (December 11-13, 2009) àti KWALI 5 (December 4-6, 2009).

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́