Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Ṣó o rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká wa jẹ́ yìí? [Jẹ kó fèsì. Kó o wá ka Ìṣípayá 11:18.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tó fi yẹ ká gbà pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 18 hàn án.
Jí! January–March
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń rò pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ àwọn nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro. Ṣó ti ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Jákọ́bù 1:13.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tó ń fa àwọn ìṣòro wa àti ìdí tá a fi lè fọkàn balẹ̀ pé àwọn ìṣòro wa máa tó dópin.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 14 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ṣó o rò pé gbogbo ẹ̀sìn ni inú Ọlọ́run dùn sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ. [Ka Mátíù 15:8, 9.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ̀ bóyá gbogbo ìsìn ni inú Ọlọ́run dùn sí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 9 hàn án.
Jí! January–March
“Lásìkò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fẹ́ láti bọlá fún Jésù. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ọnà wo lo rò pé ó dára jù lọ láti bọlá fún Jésù? [Ka Jòhánù 14:15. Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù gan-an, ó sì lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá mọ ìdí táwọn kan fi yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n ń ṣe ọjọ́ ìbí Jésù. Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 hàn án.