ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/10 ojú ìwé 4
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 1/10 ojú ìwé 4

Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ilé Ìṣọ́ January 1

“Ṣé o rò pé ayé máa dáa si táwọn èèyàn bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí? [Ka Róòmù 12:18. Jẹ́ kó fèsì.] Kí lo wá rò pé ó fà á tí Ọlọ́run fi sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ìgbà kan pé kí wọ́n lọ jagun? Àpilẹ̀kọ yìí sọ bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ṣe kedere.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 13 hàn án.

Ji! January–March

“Lójú tìẹ ṣé ìsìn máa ń mú kí àwọn èèyàn fìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa gbé ní àlàáfíà àbí ńṣe ló ń fa ìkórìíra àti ìwà ipá? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ ni ò fi ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ yìí sílò. [Ka Mátíù 5:44, 45.] Àkòrí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé yìí sọ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá ẹni?’” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 24 hàn án.

Ilé Ìṣọ́ February 1

“Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé táwọn bá kú, ọ̀run làwọn ń lọ. Ṣé ìwọ náà gbà gbọ́ pé ọ̀run lò ń lọ tó o bá kú? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa jẹ́ èrè ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹni rere. [Ka Sáàmù 37:29.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó máa lọ sọ́run àti ohun tí wọ́n máa ṣe níbẹ̀.”

Ji! January–March

“Mo fẹ́ mọ èrò rẹ nípa ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí. [Ka Mátíù 5:3.] Níwọ̀n bí ìsìn ti pọ̀ lóríṣiríṣi, ṣé o rò pé ohun tó bá ṣáà ti wù wá la lè ṣe ká bàa lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 26 hàn án.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́