Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
A parí ọdún iṣẹ́ ìsìn alárinrin kan ní oṣù August ọdún tó kọjá! Iye àwọn akéde tó ròyìn lóṣù náà jẹ́ ẹ̀rìndínlọ́gọ́jọ lé ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [312,315], èyí dín díẹ̀ sí iye àwọn tó ròyìn lóṣù August ọdún 2008. Àmọ́, ìpíndọ́gba iye àwọn akéde fi ìpín mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ọdún 2008 lọ. Iye àwọn aṣáájú ọ̀nà tó ròyìn jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti igba-dín-mẹ́fà [30,194], iye yìí sì pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. A darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó tó ọ̀kẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárin àti ọ̀tà-lé-nírinwó dín méjì [628,458], ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa bá àwọn èèyàn tó tóyẹn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà nìyẹn. Bá a ṣe ń rí ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ wa, èyí mú ká lè máa sọ ohun tó wà nínú Sáàmù 65:11 pé: “Ìwọ ti fi oore rẹ dé ọdún ládé.”