Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tá a tún lè lò gẹ́gẹ́ bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kí àwọn akéde ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí onílé bá gba ìwé yìí tàbí tó bá ti ní in lọ́wọ́. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tí ì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Ń Ṣe fún Wa Nísinsìnyí.”
◼ Inú wa dùn láti fi tó yín létí pé lọ́dún 2010, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Benin City ní March 20-21 àti August 21; Ọ̀tà ní April 10-11 àti July 10; Ùlì ní June 5-6 àti April 24. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe lédè Faransé ní: Bàdágìrì ní March 6-7 àti July 3. Èdè Faransé àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la máa fi ṣe àwọn àpéjọ yìí látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ àwọn èdè yìí pé kí wọ́n wá.