Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 1
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 1
Orin 138
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv orí 16 ìpínrọ̀ 9 sí 14 àti àpótí tó wà lójú ìwé 192 sí 193
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 8-10
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 8:1-12
No. 2: Bíbélì Jẹ́ Ìwé Kan fún Gbogbo Èèyàn (td 8D)
No. 3: Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Kéèyàn Mọ Bí Ikú Ṣe Jẹ́ Gan-an?
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ ọjọ́ tó kàn tí ìjọ yín máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákànṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn. Sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tàbí kó o fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí akéde míì tó nírìírí, ní kó sọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó ti lò tó sì rí i pé ó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. O lè ní kó ṣàṣefihàn bó ṣe gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀.
10 min: Lo Àwọn Ohun Tí A Lè Fojú Rí Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 247 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 248 ìpínrọ̀ 1.