Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ February 1
“Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jésù sọ lórí kókó yìí. [Ka Mátíù 6:7.] Àpilẹ̀kọ tó fani mọ́ra yìí sọ ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè mẹ́rin táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà. Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.
Jí! January–March
“Ta ni ìwọ́ kà sí ẹni táyé yẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ní kedere, ohun téèyàn gbọ́dọ̀ rí lára ẹni táyé yẹ lóòótọ́. [Ka Sáàmù 1:3.] Gbígbé ìgbé ayé tó dára jù lọ ló ń mú káyé yẹni, ọwọ́ èèyàn lè tẹ èyí nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, èyí sì ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún àwa èèyàn. Wo bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé ẹ lọ́nà táyé á fi yẹ ẹ́, nípa kíka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 3 sí 9 nínú ìwé ìròyìn yìí.”
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sẹ́dàá ni Ọlọ́run ti kádàrá ẹ̀ tẹ́lẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀. [Ka Oníwàásù 9:11.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti kádàrá ẹ̀ pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa, síbẹ̀ ó fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láyè láti yan bá a ṣe máa lo ìgbésí ayé wa.”
Jí! January–March
“Láìsí àníàní, o mọ̀ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí Jésù sí. Àmọ́, ṣó o mọ ọjọ́ tí wọ́n bí i? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé Bíbélì kò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù gan-an. Gbọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìbí Jésù. [Ka Lúùkù 2:4-8.] Pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ yìí, kò jọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn lè wà níta gbangba pẹ̀lú àwọn àgùntàn lálẹ́ ọjọ́ kan lóṣù December tí òtútù máa ń mú gan-an. Bó ti wù kó rí, ìwé ìròyìn yìí ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìdí táwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni fi yan December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù.” Wo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16.